Guinea coup: ECOWAS f'òfin de àwọn ológun tó dìtẹ̀ gbàjọba ní Guinea

Awọn adari ajọ ECOWAS ti fofin de awọn ologun to ditẹ gbajọba ni orilẹede Guinea ati ẹbi wọn lati maa le rinrin ajo kuro lorilẹede naa lọ si ibikan.

Ọpọ lo ti n reti ikede igbesẹ yii lẹyin ti awọn ologun doju ijọba alagbada bolẹ tan nibẹ.

Ajọ ECOWAS ti wa fun ijọba ologun ni oṣu mẹfa lati da ijọba pada fun alagbada.

Awọn ologun doju ijọba Aarẹ Alpha Condé bolẹ lori ẹsun iwa ibajẹ lẹyin to wọle idibo aarẹ fun saa kẹta.

Ajọ ECOWAS tun fofin de Guinea ninu igbimọ alaṣẹ ajọ naa titi digba tawọn ologun yoo fi da ijọba pada fawọn alagbada.

Ilu Accra ti ṣe olu ilu Ghana lawọn olori orilẹede ajọ ECOWAS ti ṣe ti ṣe ijiroro nibi ti wọn ti gbe awọn igbesẹ yii.