You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fani-Kayode Visits Sunday Igboho: Mínísítà tẹ́lẹ̀ ní òun kò ní fi Igboho sílẹ̀
Yoruba ni ara la mọ, a ko mọ inu, bẹẹ si ni inu jinna, o ju ọrun lọ.
Sunday Igboho lo jẹ gbajumọ ajijagbara fun iran Yoruba, ti ọpọ eeyan n wari fun nilẹ Kaarọ Oojiire.
Tọmọde tagba si lo n wọ tẹle lẹyin nitori iwa akin to hu lati gbeja ẹya rẹ lọwọ awọn afurasi darandaran to n da ẹmi wọn legbodo laibikita.
- Ó pé mi kí n kú jù kí n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC - Fani-Kayode
- Ọjọ́ tò burú jùlọ nínú ìrìnàjò oṣèlú mi ni ọjọ ti FFK darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Ojudu
- 'Buhari, máa múra sílẹ̀ láti fẹ̀yìntì'
- Awolọwọ ní tí àsìkò bá tó, ọ̀dọ́ á jà fúnra wọn- Sunday Igboho
- Femi Fani-Kayode sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Tinubu tori kò dìde kí Ooni
- Ẹ má gbọ́ ẹjọ́ ẹnìkan dá lórí ọ̀rọ̀ ìyàwó mi - Femi Fani-Kayode
- Ọmọ ìjọ Èṣù ni Linda Fairstein -Femi Fani Kayode
- Ẹ́ yé parọ́ mọ́ mi kiri, n kò múra ìgbéyàwó, ọ̀rẹ́ lásán ni Halima - Femi Fani-Kayode fọnmú
Amọ lasiko kan ni iroyin tan kalẹ pe awọn eeyan kan loru mọju ọjọ ọjọ Isẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn osu Kinni ọdun 2020.
Bi o tilẹ jẹ pe ile atijọ ti Sunday igboho n gbe ni ile naa, ti ko si si ninu rẹ lasiko ti isẹlẹ naa waye, sibẹ ọpọ dukia to wa ninu ile naa lo bajẹ.
Idi ree ti ọpọ eeyan se n wọ wa ki Igboho nile pe Ọlọrun yoo fi ofo ra ẹmi, lara wọn la si ti ri akọrin Fuji nni, Saheed Osupa, Asofin Sina Peller, tii se ọmọ ile asoju-sofin nilu Abuja.
Bakan naa ni Oloye Femi Fani-Kayode, FFK tii se minisita tẹlẹ fun eto irinna naa wa se ẹ pẹlẹ si Sunday Igboho nile rẹ nigba ti isẹlẹ ile jijo naa waye.
Ọlọrun ko ni si Sunday Igboho silẹ, emi naa ko ni fi silẹ - Femi Fani-Kayode
Nigba ti Fani-Kayode ati Sunday Igboho joko papọ lori aga kan naa lasiko abẹwo ọhun, ni FFK ti kan saara si Igboho fun isẹ ijijagbara to n se.
Bakan naa lo fi ọwọ sọya pe ko si ọrọ anboju wẹyin mọ lori awọn igbesẹ ijijagbara ti Igboho n gbe, paapaa lori bi wsn se jo ile rẹ naa.
FFK tun wa fi ọwọ sọya fun akọni ọmọ Yoruba naa pe gba gba gba ni oun wa lẹyin rẹ, mi mi kankan ko si le mi rara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bí egungun bá há ọ lọ́fun, wo ohun méje tó ṣe láti yọ́
- Wọ́n fipá bá mi lòpọ̀ tán, díẹ̀ ló kù - Nkechi Blessing
- $4.1bn ta fẹ́ yá, àkànṣe iṣẹ́ ta fẹ́ fí ṣe yíká Naijiria rèé - Ìjọba àpapọ̀
- "Taliban kò gbà kí obìnrin wọlé padà sílé ẹ̀kọ́, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ọjọ́ ọ̀la mi"
- "Buhari, to bá fún Fani-Kayode ní ipò, àwa ọ̀dọ́ yóò fí ẹ̀họ́nú hàn"
- Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ ò! Ajá mẹwàá yà ọmọ ọdún méjì jẹ ní Anambra
- Ọjọ́ tò burú jùlọ nínú ìrìnàjò oṣèlú mi ni ọjọ ti FFK darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Ojudu
- Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ mọ́ APC- Sheikh Gumi
- Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ ò! Ajá mẹwàá yà ọmọ ọdún méjì jẹ ní Anambra
- Ẹ̀yin ọkùnrin Nàìjíríà alágbèrè, ẹ wo iṣẹ́ tí Mike Bamiloye rán sí yín
Yatọ si eyi, lẹyin abẹwo naa tun ni FFK tun sọrọ lawọn oju opo ibanidọrẹ rẹ lori ayelujara rẹ nigba naa, lati ki Sunday Igboho laya lori iwa aksni to n hu.
Ọrọ kan ti FFK kọ lo tun ni "Oloye Sunday Igboho Oosha lo n soju ọpọ ọkan, ara ati ẹmi Oduduwa lonii.
Orukọ rẹ lo fara pẹ igboya, okun, ikoraẹninijanu ati agbara, bẹẹ ni kii bẹru tabi tẹriba labẹ ẹnikẹni.
O jẹ koriya, itọni, amuyangan ati ayọ fun ọpọ miliọnu eeyan, bẹ ba si fi pa pẹrẹ, yoo da rogbodiyan ati wahala nla silẹ."
Iru Femi Fani-Kayode la nilo, asiwaju rere ni - Sunday Igboho
Nigba to n fesi lori ohun ti FFK sọ, Sunday Igboho ni oun fi Ọlọrun bura, iru FFK lawọn nilo nitori pe asiwaju rere ni.
"Ẹ sọ ọrọ kan pe a ko ni boju wẹyin mọ, iru ohun ti emi fẹ mọ gbọ lati ẹnu awọn baba wa niyẹn."
Sunday Igboho ni awọn tawọn n ba fa, wọn ro pe awọn n se fiimu ni, lo ba bu sẹkun, ti FFK si n bẹ pe ko dakẹ ẹkun nitori ko si nnkan kan.
FFK ni " Ko si nkankan, ko si nkankan rara, Alọrun to wa pẹlu rẹ, ti ko fi ẹ silẹ, ko dẹ si ẹni to maa fi ẹ silẹ, awa naa ko ni fi ẹ silẹ."
Sunday Igboho wa tẹ siwaju pe awọn kan n se ipade pe awọn kan fẹ oun, ti FFK si n fi ọwọ idaniloju sọya pe ko le seese fun wọn.
Sunday Igboho tẹsiwaju pe "Yoruba gbọdọ lọ ni nitori pe iya n jẹ wa gan ni."
Amọ awọn ọrọ ti FFK sọ nile Igboho yii lo ti bọ si apo ibinu awọn ọmọ Naijiria, ti wọ̀n si ri agba oloselu naa bii ọdalẹ.
Wọn ni ko yẹ ko jẹ iru eeyan bayii ni yoo da Sunday Igboho nipa lilọ dara pọ ijọba aarẹ Buhari.
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni Femi Fani-Kayode naa kede pe oun ti dara pọ mọ ẹgbẹ oselu APC, tii se ẹgbẹ oselu aarẹ Buhari, to ti sọrọ aidaa si tẹlẹ.