Payment Microchip: Wo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí o lé fi sínú ara rẹ̀ láti má a san owó ọ̀jà láì lo káàdì ATM

Ni gbogbo igba to ba n san owo fun ọja to ra nile itaja, tabi ibikibi, ni awọn eeyan ma n wo Ọgbẹni Patrick Paumen.

Idi ni pe ẹni ọdun mẹtadinlogoji naa ko nilo kaadi banki tabi foonu rẹ lati fi sanwo ọja. Dipo bẹẹ, ọwọ osi rẹ ni yoo gbe si itosi ẹrọ to n ṣe ayẹwo kaadi, owo to fẹ san yoo si wọle.

Ọgbẹni Paumen le ṣe eyi, nitori pe o fi ẹrọ kan, 'microchip', to le san owo sinu agọ ara rẹ ni ọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Abẹ awọ to wa ni ọwọ osi rẹ ni wọn fi ẹrọ naa pamọ si, eyi to ma n tan ina nigba to ba sunmọ ẹrọ to n gba owo, bii POS.

Oludasilẹ ileeṣẹ kan ni Britain, Walletmor, to n se iru awọn ẹrọ yii, Wojtek Paprota, sọ pe ko si ilu ti eeyan ko ti le lo imọ ẹrọ naa fun owo sisan.

Bawo ni ẹrọ payment microchip ṣe n ṣiṣẹ?

Ọgbẹni Paprota sọ pe ẹrọ 'chip' ti ileeṣẹ Walletmor ṣe, kere pupọ, debi pe iwọn rẹ ko to giraamu kan.

  • O ni "diẹ lo fi tobi ju kóró irẹsi kan - ti a ṣe pẹlu eroja microchip kekere, ati antenna ti a ko jọ sinu ike fẹlẹfẹlẹ biopolymer."
  • O ṣalaye pe ẹrọ naa ko ni ewu rara.
  • Lọgan ti wọn ba fi si inu ara, lo ma n bẹrẹ iṣẹ.
  • Ojúkan ti wọn ba fi si lo ma n duro si titi lai.
  • Ko nilo batiri tabi ina mọnamọna lati ṣiṣẹ.
  • Imọ ẹrọ to fi n ṣiṣẹ ko yatọ si eyi ti awọn eniyan n lo lojoojumọ lati fi ṣi ilẹkun, kaadi ile ATM, ati bẹẹbẹẹ lọ.
  • Kaadi microchip yii gbọdọ sunmọ ẹrọ to ni 'electromagnetic' ko to o le ṣiṣẹ. Imọ ẹrọ naa ni yoo rin kaakiri gbogbo ara eniyan lati ṣawari RFID chip implant yii.

Ileeṣẹ naa sọ pe o ti le ni ẹẹdẹgbẹta irinṣẹ naa ti oun ti tà.

Ṣe ewu wa ninu fifi kaadi fun owo sisan sinu ara?

Onimọ kan nipa imọ ẹrọ fun gbigba ati fifi owo ranṣẹ nilana igbalode, Theodora Lau sọ pe awọn kaadi yii ko yatọ si ẹrọ ayélujára, ti aye n lo lati fi nkan ranṣẹ si ara wọn.

O ni iru imọ ẹrọ yii yoo mu ki o rọrun lati sanwo ọja lai si ìdádúró.

"Ṣugbọn ewu to wa n bẹ ni pe gbogbo akọsilẹ nipa eeyan ni yoo wa lori kaadi naa.

"Lootọ ni a n wa irọrun, amọ melo ninu aṣiri wa, ati eto aabo wa la fẹ fi aṣiri rẹ sita, paapaa lọjọ iwaju?"

Ẹwẹ, olukọ imọ ẹrọ ati isẹ adani ni Fasiti ilu Winchester, Steven Northam, sọ pe awọn ẹrọ bayii ko ni ewu rara.

O ni lati ọpọ ọdun ni wọn ti n fi wọn sinu ara ẹranko fun amojuto.

Ọgbẹni Northam naa ni ileeṣẹ kan to n ṣe ẹrọ ti wọn n fi sinu agọ ara awọn to ni ipenija ara, lati fi ma a ṣi ilẹkun lai fi ọwọ kan an.