You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seye Malaolu: Mo ta gbogbo dúkìá mi kí ń tó rí N7m owó ìtọ́jú èmi àti ọmọ mi
Ọjọ buruku, eṣu gbomi mu lọjọ Satide, ọjọ keji, oṣu kọkanla, ọdun 2019 jẹ nigbe aye Ṣẹyẹ Malaolu, ẹni to yan iṣẹ ajorinmọrin laayo nilu Abeokuta.
Idi ni pe ọjọ naa ni ijamba nla kan sẹlẹ si, eyi to mu ki oju rẹ fọ, ti eti rẹ di, ti apa rẹ naa si tun ge.
Yatọ si eyi, isẹlẹ to waye lọjọ manigbagbe yii naa tun kan ọmọ rẹ, Fisayọ, ẹni to padanu ẹsẹ ati ọwọ rẹ sinu ijamba naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ó ti ṣe díẹ̀ tí mo ti ń gbé pẹ̀lú ìbànújẹ́, ayé ti sú mi - Ibrahim Chatta
- Ìgbá àkọ́kọ́ nìyìí ti oò bá mi ṣe ayẹyẹ ọdún pọ̀ olólùfẹ́ mi - Bimbo Oshin
- Shina Peters dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn abiyamọ ayé lórí ọ̀rọ̀ ọmọ tí Funmi Martins bí kó tó papòdà
- Odíndi mọ̀lẹ́bí kan jẹ́ oníbalòpọ̀ abo sí abo, wo irú ìpólówó ọjà wọn tó dá wàhálà sílẹ̀
- Ẹ̀yin ọkùnrin Nàìjíríà alágbèrè, ẹ wo iṣẹ́ tí Mike Bamiloye rán sí yín
- Báwo ni #stingymenassociation ṣe gba ojú òpó twitter kan?
- Ìdí mẹ́fà rèé tí Instagram, Facebook le fi wọ́gilé ojú òpó ìkànsíraẹni rẹ
Lọjọ naa, Ṣẹyẹ ati awọn ọmọ rẹ, Fisayo to fi mọ iyawo rẹ ṣẹṣẹ de ṣọọbu ni, ni ọkunrin kan gbe taya tirela wa fun lati tun se.
Bawo ni isẹlẹ naa se waye?
Gẹgẹ bo ti salaye fun BBC Yoruba, Seye ni ọkunrin kan to n tun taya se lo gbe taya tirela kan wa fun oun lati ba oun tun se.
Ṣẹyẹ, ẹni ti ko bawọn tun taya tirela se ri lati bi ọdun marundinlogoji to ti yan iṣẹ naa laayo ni owo ti ko fi bẹẹ si lọwọ oun, lo jẹ ki oun gba isẹ naa lai mọ pe ọrọ naa yoo bẹyin yọ.
Ko si ina mọnamọna lọjọ ti a n sọ yii, ṣe ni Ṣẹyẹ si lọ tan ẹrọ amunawa ko le bawọn ṣiṣẹ naa.
Ibi to ti n gbiyanju lati gbe irinṣẹ le taya naa, ni taya ọhun ti ta pau lojiji, ti Ṣẹyẹ ati ọmọ rẹ, Fisayọ si fọn danu.
Baba ati ọmọ rẹ yii lo daku lọ rangbọndan amọ Ẹlẹdaa tun da wọn pada saye.
Lẹyin wakati mẹta ni Fisayọ laju saye, nigba ti baba rẹ, Ṣẹyẹ laju saye lẹyin ọjọ kẹẹdogun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Seye salaye pe awọn oṣiṣẹ ileesẹ amunawa to wa lẹgbẹ ṣọọbu oun lo sare gbe oun pẹlu ọmọ oun lọ sile iwosan lati doola ẹmi awọn, ti gbogbo agbegbe ọhun si pa lọọlọ lọjọ naa.
Dokita ni Fisayo ti ku amọ lọna ile igbokusi lo ti pariwo de oju aye:
Gẹgẹ bi Seye ti wi, awọn dọkita ti sọ pe Fisayọ ti di oku, ti wọn si ti fẹẹ gbe e wọ ile igbokusi, iyẹn mọṣuari, ko to pariwo jade lojiji wi pe oun ko ku.
Eyi lo jẹ ki wọn tun gbe e wọ yara itọju iṣẹlẹ pajawiri fun itọju.
Wọn ge apa Seye ati ọmọ rẹ, Baba fọ loju, to si tun di leti:
Amọ iyalẹnu nla lo jẹ fun Ṣẹyẹ nigba to laju lori bẹẹdi l'ọsibitu, to si ri awọn mọlẹbi rẹ to yii ka.
Awọn eeyan yii lo wa ba a kẹdun, nibẹ si lo ti n beere ohun to ṣẹlẹ, ko to di pe wọn ṣalaye fun un.
Amọ o se ni laanu pe wọn ge apa Ṣẹyẹ ati ti ọmọ rẹ, Fisayọ, ti wọn si tun paarọ oju rẹ si ti ayederu {artificial eye}.
Owo ti ko din ni miliọnu meje naira ni Seye ni awọn ti na sori itọju oun ati ọmọ oun, gbogbo dukia ni wọn si ta tan pata fun itọju wọn.
Mo fẹ fa wahala lori isẹlẹ naa amọ...
Ṣẹyẹ, nigba to n ba BBC YORUBA sọrọ sọ pe gbogbo ero ọkan oun nigba toun wa lori bẹẹdi l'ọsibitu ni lati lọ ba ẹni to gbe iṣẹ foun ja.
ṣugbọn oun tun da ọrọ naa ro wi pe iranlọwọ loun n wa, ki i ṣe wahala.
"Kinni yẹn lo fọ ori mi bayii, iṣẹ abẹ ni wọn fi ran ori mi yii, ohun naa lo tun yọ oju mi ọtun yii, oju ti osi yii, bi ida mẹẹdogun ninu ọgọrun ni mo fi n riran.
bi eeyan ko ba sunmọ mi daadaa, mi o le ri onitọhun. Nigba ti mo lo ọjọ mẹẹdogun lori bẹẹdi lọsibitu ni wọn n jẹ ki n mọ pe ọwọ ọmọ mi ati ẹsẹ ẹ naa ge."
Ọrọ naa gan ka iyawo mi laya, koda o ni oun ko se mọ laarin kan:
Seye tẹsiwaju pe "Mi o le fa wahala, iranlọwọ ni mo nilo bi mo ṣe wa yii, nitori pe awọn eniyan ko ni ran ẹni to ba fa wahala lọwọ.
Owo ti kinni yii ti gba lọwọ mi ti pọ, gbogbo iṣẹ geeti ti mo ṣe si ṣọọbu ni mo ti ta tan, gbogbo ọja purofiṣan ti iyawo mi n ta ni mo ti ta tan patapata, igba ti run, lati fi tọju ẹsẹ ọmọ mi."
"O to aarin kan, iyawo mi sọ pe oun ko ṣe mọ, nitori pe o ti su oun. Oun lo maa gbe ọmọ lọ si ọsibitu, to baa dana, to tun maa wa owo ounjẹ.
O maa ṣe ounjẹ temi pẹlu ọmọ, ẹẹmẹta l'ọsẹ la n lọ si ọsibitu laarin ọsẹ. Mo mọ pe pẹlu bi Ọlọrun ti n bẹ ti ẹmi rẹ n bẹ, ohun gbogbo yoo di ṣiṣe."