Pastor rapes member in Ogun: Pásítọ̀ tó fi tipá bá omidan lòpọ̀ tórí ìtúsílẹ̀ ọkọ ọrun ní ẹ̀mí ló bà lé òun

Ẹsin kii jẹ koriko abẹ rẹ ni Yoruba n wi abi, to si tun ni agbado inu igo ti di awomọju fun adiẹ.

Sugbọn eyi ko ri bẹẹ fun pasitọ oloju ko mu, ko lọ kan, to di ẹni ta ni ko fẹ ni loju, to wa n fi ata sẹnu, ẹni ta fẹyin ti, to wa ja ni lyin kulẹ.

Ọwọ palaba pasitọ yii, tii se olori ijọ kan lo ma segi ni ipinlẹ Ogun lẹyin tilẹ mọ ba oloro rẹ nibi to ti n fi tipatipa ba ọmọ ijọ rẹ kan ni aṣepọ.

Pasitọ Mathew Ọladapọ to jẹ oluṣọaguntan ijọ Life and Power Bible Church ni awọn ọlọpaa fi panpẹ ofin mu lẹyin ti omidan ẹni ọdun mọkandinlogun kan fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa Ogijo pe o fi tipatipa ṣi oun laṣọ wo lasiko ti oun lọ si ij rẹ ni ọjọ Aiku to kọja, iyẹn ogunjọ oṣu keji ọdun 2022.

Lati Itusilẹ si ifipabasun

Gẹgẹbi atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi sita, arabinrin naa ṣalaye pe Pasitọ Ọladapọ ṣalaye fun oun pe, iran nla kan jade nipa arabinrin naa pe o ni ọkọ ọrun.

Pasitọ naa ni omidan yii nilo ko ṣe isin adura itusilẹ to lagbara.

O ṣalaye siwaju sii pe pasitọ Mathew Ọladapọ sọ fun oun pe iṣọ oru pẹlu awẹ ati adura ọjọ mẹta ni oun yoo se ninu ile ijọsin naa, lati gba a silẹ lọwọ ọkọ ọrun.

Bakan naa lo ni wọn tun ni ki oun mu owo odindi ẹgbẹrun kan naira wa pẹlu ororo adura.

Amọṣa, ni alẹ akọkọ ti wọn bẹrẹ adura naa, ni obinrin yii ni wọn ti gbe oun lọ si inu yara kan nibi ti o jẹ pe oun ati pasitọ yii nikan lo wa nibẹ.

Pasitọ fi ororo adura to ra wa pa a lara, titi to fi ki ika rẹ bọ oju ara mi:

Omidan naa ṣalaye pe ninu yara yii ni pasitọ naa ti ni ki oun o bọ aṣọ oun ati pata ki oun si sun sori aṣọ kan ti wọn tẹ silẹ, ti oun si ṣe bẹẹ.

Lasiko to sun silẹ ni pasitọ rẹ si ni fi ororo adura to ra wa pa a lara, titi to fi ki ika rẹ bọ oju ara obinrin naa.

Nigba ti omidan naa fẹ sọrọ, atẹjade naa ni pasitọ fi tipa mu u mọlẹ, o fi ọwọ bo o ni ẹnu ko ma ba a pariwo.

O si mu obinrin naa titi to fi fipa baa ni ajọṣepọ tan; to si sọ fun un pe ọna kan ti awọn le e gba lati tu ohun to so omidan naa ati ọkọ ọrun rẹ pọ niyẹn.

Nigba ti omidan yii fi ẹjọ sun, tawọn ọlọpaa lati agọ ọlọpaa lagbegbe Ogijo si lọ mu pasitọ naa, o jẹwọ lagọ ọlọpaa pe lootọ loun fipa ba ọmọbinrin naa lo pọ.

Amọ Pasitọ ni ẹmi biburu naa lo ru bo oun, ti oun fi ṣe iwa ibi naa.

Ki ni ọlọpaa n ṣe lọwọ lori iṣẹlẹ naa?

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣalaye pe kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti jẹko di mimọ pe awọn ọlọpaa to wa nidi ẹsun naa ko gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu u.

O ni Kọmiṣọna ọlọpaa Bankọle tun paṣẹ pe pe ki wọn gbe afurasi naa l si ẹka awọn ọlọpaa to n mojuto ẹsun ifiniṣowokotọ labẹ ẹka ọtẹlẹmuyẹ ileeṣẹ ọlọpaa nilu Abẹokuta.