You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ghana No Calls Day Protest: Àwọn oníbàráà ẹ̀rọ ìbánisọrọ fi ẹ̀hónú hàn, wọ́n kò lo fóònu wọn láti pè
Jakejado orilẹede Ghana, awọn onibara ko lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ laarọ lonii ni tibu-tooro ilẹ naa.
Ikọ kan to n gbeja awọn onibara onileesẹ ibaraẹnisọrọ lorilẹede Ghana lo ti kede saaju pe ọjọ Isẹgun oni yoo jẹ ọjọ ti wọn ko ni lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ lọwọ aarọ lati fi pe rara.
Igbesẹ yii ni wọn fi n fi ẹhonu han si asẹ ijọba to ni ki gbogbo awọn eeyan to n lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ ni orilẹede naa wa fi orukọ wọn ati nọmba ipe wọn silẹ fun igba keji.
- ‘Jí foonu ọkọ rẹ̀ wò, kóo fi ẹ̀wọ̀n jura’
- Wo awọn ‘Apps’ to le e ṣe akoba fun ẹni to ba ni si ori foonu rẹ
- Mọ̀ nípa iPhone 12, fóònù ológo 5G tí kìí lo "Charger” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde
- Wọn ti gbe aworan Samsung Galaxy S9 jade
- Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ ìforúkọsílẹ káàdi ìbánisọ̀rọ̀ síwájú síi
- Gbogbo ẹ̀yin tí 'SIM Card' yín tí sọ̀nú, ẹ wo ọ̀nà tí ẹ lè fi gbà á padà!
- Wo àwọn 'App' tó ń ba fóònù jẹ́ ní Nàìjíríà
- Wo nkan tó gbọdọ̀ mọ̀ nípa Flubot Malware tó le kó owó rẹ lọ ní bánkì láti orí fóònù rẹ
Ki ni awọn onibara ẹrọ ibaraẹnisọrọ, ti wọn fi n fi ẹhonu han:
Awọn onibara naa lo duro lori awijare pe asẹ ti ijọba pa ọhun ko ba ofin mu rara.
Ikọ olugbeja naa lo ri gba orukọ ati siginaṣọ awọn onibara ẹrọ ibaraẹnisọrọ to le ni ẹgbẹrun meje silẹ gẹgẹ bi ara ọna fun ipolongo lati tako amulo foonu fun ipe.
Ẹhonu yii si ni wọn fi n rọ awọn eeyan orilẹede Ghana lati mase pe lori aago tabi gba ipe kankan laarin aago mẹfa owurọ si mejila ọsan.
Wọn wa n beere pe ki ijọba se atunse ofin to wa nilẹ naa, ko si tun se agbekalẹilana atinuda miran ti onibara fi lee fi orukọ silẹ.
Awijare wọn lori eyi ni pe igbesẹ tuntun naa yoo dena awọn igbenija ti wọn maa n koju lawọn ibudo iforukọsilẹ fun amulo ẹrọ ibaraẹnisọrọ.
- Ìjọba le gbé ọ̀gá ọlọ́pàá Abba Kyari lọ Amẹ́ríkà láti lọ jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn jìbìtì pẹ̀lú Hushpuppi - Malami
- Ìjọba àpapọ̀ yọwọ́ kúrò nínú ẹjọ́ tó ń bá Rahmon Adedoyin àtàwọn afurasí míì ṣe lórí ikú Adegoke
- Báméjì lọ̀rọ̀ Sunday Igboho lè já sí bí ó bá yanjú ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú Benin republic - Abubakar Malami
- Bí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ṣe ń wáyé lọ́wọ́ ní Abuja, Femi Falana ń bèèrè pé kí ọ̀gá ọlọ́pàá dá ẹjọ́ padà sí Osun
- Àwọn alákòsóo APC l‘Abuja ti gbàbọ̀dè, APC l‘Oyo sì le kùnà ìbò gómìnà - Adeseun
- Wo ọ̀nà mẹ́ta tí obìnrin le gbà dènà òórùn ní tọjú ojú ara - Dayo Amusa
Ki ni pataki eto iforukọsilẹ awọn onibara ẹrọ ibaraẹnisọrọ lẹẹkeji naa wa fun:
Osu Kẹwa ọdun 2021 ni igbesẹ iforukọsilẹ lẹẹkeji ti bẹrẹ fawọn onibara ẹrọ ibaraẹnisọrọ, to si n so akọsilẹ wọn pọ mọ kaadi idanimọ gẹgẹ bi ọmọ orilẹede naa.
Awọn akọsilẹ tawọn onibara yii ba fi silẹ nipa ara wọn fun kaadi idanimọ, ni wọn yoo lo lati fi nọmba ipe wọn SIM Card silẹ.
Akọsilẹ awọn onibara yii si ni ijọba ni oun yoo lo lati gbogun ti iwa ọdaran lorilẹede naa.
Bawo ni eto iforukọsilẹ naa se kẹsẹ jari si?
Eto iforukọsilẹ awọn onibara to n lo ẹrọ ibaraẹnisọrọ naa , eyi yoo pari ninu osu Kẹta ọdun 2022 ni ọpọ ijakulẹ ti de baa.
Lara awọn ijakulẹ to koju eto iforukọsilẹ naa ni segesege isọwọ sisẹ awọn ẹrọ iforukọsilẹ ati rogbodiyan lati ọdọ awọn araalu.
Bakan naa ni awọn onibara n to lọ gbọọrọ lori ila lawọn ibudo iforukọsilẹ naa.
Ijọba lo ti dunkooko saaju fun awọn onibara ẹrọ ibaraẹnisọrọ naa pe ti wọn ba kuna lati fi akọsilẹ ati iroyin to yọ nipa ara wọn ati kaadi ipe wọn silẹ, wọn ko ni le gba ipe tabi pe jade lori foonu wọn.
Bakan naa ni wọn tun ni yoo nira fun iru onibara ti ko ba fi akọsilẹ ara rẹ silẹ lati fi atẹjisẹ ransẹ lati ori ẹrọ ibaraẹnisọrọ rẹ.