Charles Soludo ti jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra

Ni alẹ ọjọ Iṣẹgun ni ajọ INEC kede apapọ esi idibo gomina to waye nipinlẹ Anambra.

Ọjọ Satide ni idibo naa waye, ṣugbọn wọn ko pari rẹ nitori awọn idiwọ kan.

Eyi si lo mu ki idibo naa tẹsiwaju ni ijọba ibilẹ Ihiala lọjọ Iṣẹgun.

Lara awọn esi ibo ti wọn kede ni ọjọ Aiku lo fihan pe Charles Soludo to ti fi igba kan jẹ Gomina banki agba Naijiria, CBN, lo n lewaju.

Oun ni oludije fun ẹgbẹ All Progressives Grand Alliance, APGA.

Bi Soludo ṣe jawe olubori

Oludije ẹgbẹ oṣelu All Progressive Grand Alliance, Charles Chukwuma Soludo lo gba ọpọlọpọ ida ibo ti wọn n pe ni 2/3 gẹgẹ bi alakalẹ ajọ INEC eyi to mu ko bori ni ibamu pẹlu ofin Naijiria.

APC: 43,285

APGA: 112,229

PDP: 53,807

YPP: 21,261

Wo ohun díẹ̀ tó yẹ kóò mọ̀ nípa Charles Soludo

Isẹ oojọ: Onimọ nipa ọrọ

Ọjọ ori: Ọdun mọkalelọgọta

Charles Chukwuma Soludo ti jẹ gomina gomina banki apapọ ilẹ wa ri laarin ọdun 2004 si 2009.

Igba akọkọ ree ti yoo gbiyanju lati dije fun ipo gomina nipinlẹ Anambra. Ldun 2010, o fidi rẹmi lasiko to wa labẹ ẹgbẹ oselu PDP, ti Peter Obi si jawe olubori. O tun gbiyanju lati dije dupo gomina lọdun 2013 labẹ ẹgbẹ oselu APGA amọ igbimọ to n sayẹwo oludije ninu ẹgbẹ oselu naa ja kulẹ.

Ilu Isuofia nijọba ibilẹ Aguata lo ti wa.