You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
ENDSARS Lekki Shooting: Ọdún kàn lẹyìn ikọlu tó wáyé ní Lekki, kò ṣì sí àrídájú òhun tó ṣẹlẹ̀
Ogunjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2020 jẹ ọjọ manigbagbe ninu itan orileede Naijiria.
Ọjọ yi ni ikọlu waye laarin awọn ọmọ ogun Naijiria ati awọn oluwọde ENDSARS ni agbegbe Lekki Toll Gate ni ilu Eko.
Iwọde tawọn oluwọde yi n ṣe ti n lọ lojoojumọ bẹrẹ lati ọjọ Keje oṣu Kẹwaa ti wọn ti ni o to gẹ pẹlu ijiya tawọn ọlọpaa SARS fi n jẹ araalu paapa awọn ọdọ.
- Wọ́n ní ìpànìyàn wáyé ní Lekki, àmọ́ a kò rí ẹ̀jẹ̀ tàbí òkú èèyàn kankan títí d'òní- Lai Mohammed
- Ìpínlẹ̀ Eko fi oṣù mẹ́ta kún ìjọ̀kó àwọn tó ń gbẹ́sùn ìṣekúpani lásìkò ìwóde EndSARS
- Kíní ìtumọ̀ ''Sọ̀rọ̀ Sókè'' tí àwọn afẹ̀họ́núhàn EndSars ń lò káàkiri
- Ẹ wo ọ̀rọ̀ àwọn Wòlíì tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ saájú nípa làásìgbò EndSARS
- Sanwo-Olu buwọ́lu ìgbésẹ̀ ìjọba láti tún Eko ṣe lẹ́yìn rògbòdìyàn EndSARS
- Wo ohun tí Baba Ijesha sọ fún BBC níbi ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ tó wáyé lónìí
Ninu apilẹkọ yi, BBC Yoruba boju wẹyin lati wo iṣẹlẹ to waye lọjọ yi eyi to pada kangun si ikọlu ati iyinbọn si awọn oluwọde.
Ni ṣiṣẹ n tẹle awọn ohun ta ri ko jọ ree nipa iṣẹlẹ iyinbọnpaniyan to waye ni Lekki Toll Gate.
Ki a tibi ohun to waye lọjọ Kọkandinlogun bẹrẹ
Iṣẹlẹ kan to lamilaka waye ni ọjọ Kọkandinlogun oṣu Kẹwaa.
Kii ṣe ni Eko lo ti waye ṣugbọn awọn ti Eko naa mọ riri rẹ lara ohun naa si ni ṣe pẹlu ọrọ ENDSARS.
Ijọba ipinlẹ Edo kede konileogbele oniwakati mẹrinlelogun nitori ikọlu tawọn janduku ṣe si ọgba Ẹwọn Benin ati Oko.
Ninu ikọlu yi, ni ṣe ni awọn janduku to sa sabẹ iwọde ENDSARS N dunkoko mọ ara ilu ti wọn si n jale kaakiri ilu.
Pẹlu bi nkan ti ṣe ri yi, ọpọ lo ti n ro pe o ṣeeṣe ki iru rẹ naa waye ni Eko.Ọrọ pada ri bẹẹ.
Logunjọ,awọn Janduku sọ ina si agọ ọlọpaa ni Iganmu
Bawọn oluwọde ti ṣe ji lowurọ ọjọ Iṣẹgun tii ṣe ogunjọ oṣu Kẹwaa lati tẹsiwaju pẹlu ifẹhonuhan wọn, pupọ ni ko lero pe ewu nla n bẹ lọjọ naa.
Awọn to gbe igba orin ti bẹrẹ si ni lu ilu tawọn to n ba awọn oluwọde sọrọ naa si ti bẹrẹ ọrọ iwuri pe ki wọn maa ṣe jẹ ki ihalẹ ijọba mu wọn lọkan.
Lagbegbe Orile ti ko jina pupọ si Lekki Toll Gate wahala naa de oju ẹ nigba tawọn janduku kan ṣe ikọlu si agọ ọlọpaa nibẹ ti wọn si sọ ina si.
Kaakiri loju opo ayelujara lawọneeyan ti ri fọnran fidio yi.
Awọn ọlọpaa fi atjade sita pe awọn yoo koju awọn to ba fẹ da omi alaafia ilu ru.
Gbangba ti pada wa dẹkun ti kedere si ṣetan lati bẹẹ wo.
Sanwoolu kede pe konile o gbele yoo bẹrẹ ni ago mẹrin ọsan Ogunjọ
Logunjọ oṣu Kẹwaa lẹyin to ni oun wo bi awọn janduku ṣe n da igboro ru lori iwọde ENDSARS, Gomina Babajide Sanwoolu kede konile o gbele.
Ikede yi yi de oju opo rẹ ni Twitter ni nkan bi ago mejila ọsan ku diẹ.
Ọrọ naa ti wa de oju rẹ bayi ti ọpọ ara ilu Eko to n ṣiṣẹ lagbegbe Lagos Island si bẹrẹ si ni palẹmọ ki gbendeke yi to pe.
Ẹwẹ, bi ijọba Eko ti ṣe kede konileogbele ni ipinlẹ naa ni Gomina Kayode Fayemi ti Ekiti naa s pe konileogbele yoo bẹr ni ago mẹwaa alẹ.
Iwọde ṣi n lọ ni Lekki, awọn oluwde ni ko si giri
Lati ago mọkanla kọja ti ijọba fi ikede yi sita, awọn oluwọde to wa ni Lekki ni ko si giri pe ile lapoti awọn yoo joko de idi awn ti ijba ba ran wa.
Ninu awọn fnran fidio ati ohun ti oniroyin wa jabọ, niṣe ni wn tsiwaju pẹlu orin kikọ ti wn si s pe ki gbogbo awọn to ba fẹ duro ri pe wọn o fa wahala kankan.
Ago mẹrin lu awọn oluwọde ko kuro ni Lekki bẹẹ si ni awọn agbofinro ko ti de.Ohun to waye lyin igba naa ree:
- Nigba ti yoo fi diago marun abọ irọlẹ awọn eeyan kan wa yọ kamẹra CCTV to wa lara patako ipolowo ọja to wa lẹgbẹ Toll Gate naa
- Ni nkan bi ago mẹfa ni wọn pa gbogbo ina to wa lagbegbe Toll Gate ti okunkun birimu si bo gbogbo ibẹ
- Ni nkan bi ago mẹfa abọ irọle ku diẹ lawọn ikọ ọmọ ogun gbera kuro ni ibudo ologun to wa ni Bonny Camp lati lọ si Lekki Toll Gate.
- 6:43pm si 6:45pm akọroyin wa towa nikalẹ sọ pe wọn bẹrẹ si sunmọ ibi ti awọn oluwọde wa ti wọn si bẹrẹ si ni yin ibọn.
- Nkan bi wakati kan abọ si meji ni wọn fi n yinbọn yi.
Ibi ibọn yinyin yi ni ariyanjiyan ti waye.
Awọn ọmọogun sọ pe awọn ko yin ọta ibọn gidi ṣugbọn awọn oluwọde ni ọrọ ko ri bẹ.
Ninu iwadii kan ti BBC ṣe lyin iṣẹlẹ yi, awon oṣojumi koro ti ko f fojuhan ni awọn eeyan ba iṣẹlẹ naa lọ.
Lọjọ Keji iṣlẹ yi, Gomina Sanwoolu tọrọ aforijin lọwọ awọn araalu to si s pe eeyan kan ku ti awọn meji mii sifarapa.
Lẹyin igba yi, wn ṣe agbekalẹ igbimọ iwadii ti yoo t pinpin ohun to ṣẹlẹ ati iye awn eeyan to ku ninu ikọlu yi.
Igbimọ pari iṣẹ ti wọn si kede owo gba ma binu to le ni miliọnu irinwo Naira fawọn to mẹjọ wa siwaju rẹ
Igbimọ naa pari iwadii rẹ bawọn ọdọ Naijiria kan ṣe n gbaradi ayajọ iranti ọdun kan iwọde ENDSARS .
O ti pe ọdun kan bayi to si jẹ pe pupọ idahun si ibeere ohun to ṣẹlẹ ni ko ti ni idahun.