Rebiulding Lagos: Sanwo-Olu buwọ́lu ìgbésẹ̀ ìjọba láti tún Eko ṣe lẹ́yìn rògbòdìyàn EndSARS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti buwọlu igbesẹ ijọba lati tun gbogbo ohun to bajẹ lasiko ifẹhonuhan EndSARS ṣe nipinlẹ Eko.

Sanwo-Olu gbe igbimọ ẹlẹni mẹjọ kalẹ ti yoo ṣe amujuto atunṣe ohun gbogbo tawọn janduku bajẹ.

O tun sọ fun igbimọ naa lati ṣiṣẹ lori ọjọ iwaju ipinlẹ Eko ki wọn si tun ṣiṣẹ lori ọna lati wẹ oju egbo ti iwọde EndSARS da san.

Awọn ọmọ igbimọ naa wa lati ileeṣẹ ijọba, alaadani atawọn ajọ agbaye ti wọn ti yọnda ara wọn fun iṣẹ atunṣe ipinlẹ Eko lẹyin iṣẹlẹ EndSARS.

Ọgbẹni Yemi Cardoso ni alaga igbimọ ọhun nigba ti Ọjọgbọn Kanyisola Ajayi, Ọgbẹni Gbenga Agboola, Arabinrin Bola Adesola, Ọgbẹni Sam Egube, Ọgbẹni Jimi Hotonu, Ọgbẹni Abubakar Suleiman ati ọmọ ẹgbẹ ajọ agbgaye alaanu kan jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ ọhun.

Sanwo-Olu tun ṣe ifilọlẹ igbimọ mẹfa miiran ti yoo ri si bi ipinlẹ Eko yoo ṣe pada bọ sipo ni kiakia.

Gomina Sanwo-Olu ni asiko ti to lati gbagbe ohun to ṣẹlẹ ki gbogbo ara ipinlẹ Eko fọwọ sọwọpọ lati tun Eko ṣe pada.

Gomina ipinlẹ Eko ni ọgọọrọ eeyan lo yọnda lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati ṣatunṣe ipinlẹ naa lẹyin rogbodiyan to ṣẹlẹ.

O ni ijọba yoo gbe abadofin lori ati tun ipinlẹ Eko ṣe lọ si iwaju ile igbimọ aṣofin lai pẹ.