Ondo bullion van attack: Adigunjalè kọlu ''bullion van'' tó gbówó l'Ondo fún ìgbà kẹ́rin lóṣù méjì, èèyàn méjì tún kú

Eeeyan meji lo tun gbẹmi mi lẹyin tawọn adigunjale tun kọlu ọkọ to n gbe owo lọ niluu Ofosu lọna mọrosẹ Ore si Shagamu ni ijọba ibilẹ Idanre nipinlẹ Ondo.

Ohun ti a gbọ ni pe ọkọ igbowo naa n lọ si Ore ni kawọn adigunle naa to da ibọn bo ọkọ naa.

Ẹnikan sọ pe ọlọpaa meji ati eeyan kan mii lawọn adigun jale ọhun yinbọn pa.

Awọn miran tun sọ pe eeyan marun un lo ku ninu iṣẹlẹ naa, awọn ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ banki to tẹ le ọkọ naa.

A tun gbọ pe obiti biti owo ti ẹnikan ko mọ iye rẹ ni awọn adigunjale ọhun gbe lọ.

Ẹnikan sọ pe awọn adigunjale ọhun ti lọ sa pa mọ fawọn to n gbe ọkọ igbowo naa lọ eyi to jẹ ti gbajugbaja banki kan.

Ilu Benin Benin nipinlẹ Edo ni wọn ti n gbe ọkọ owo naa bọ ki wọn to ko sọwọ awọn adigunle niluu Ofosu.

Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa, Funmilayo Odunlami to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe eeyan meji lo ku ninu iṣẹlẹ naa.

Odunlami sọ pe ọlọpaa kan ati awakọ igbowo naa lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Alukoro ọlọpaa ni ilu Araromi Obu ni ọkọ igbowo naa n lọ ki wọn to dawọn lọna.

O ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ati pe awọn ọlọpaa ti le awọn adigunjale ọhun lọ.

Eyi ṣẹlẹ lẹyin ọsẹ meji tawọn janduku agbebọn kọlu ọkọ igbowo kan ni Emure Ile ni ijọba ibilẹ Owo.

O ti di igba mẹrin ti iṣẹlẹ ikọlu ọkọ igbowo ti ṣẹlẹ bayii nipinlẹ Ondo laarin oṣu meji.