NDA Kaduna attack: Ẹ̀yin akọ̀ròyìn, ẹ má sọ ọ̀rọ̀ wa láì dá a mọ́ - Iléèṣẹ́ ológun

Ẹka to n mojuto eto iroyin nileeṣẹ ologun Naijiria, ti bẹ awọn akọroyin pe ki wọn o ma sọ ọrọ ileeṣẹ ologun lọna ti ko dara.

Eyi waye lẹyin ọjọ kẹta ti awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko mọ, kọlu ile ẹkọ awọn ologun, Nigerian Defence Academy (NDA), nilu Kaduna, ti wọn si pa

Lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye ni awọn ọmọ Naijiria ti n beere oriṣiriṣi ibeere lọwọ ileeṣẹ ologun.

Ti oriṣiriṣi iroyin si n jade nipa iṣẹlẹ naa.

Oludari ẹka iroyin nileeṣẹ ologun, Ọgagun Benjamin Olufemi Sawyerr fi ọrọ ẹbẹ naa sita ni ori redio Voice of Nigeria, ati Federal Radio Corporation of Nigeria, FRCN, lọjọru, ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ.

Ọgagun Sawyerr sọ pe ki awọn ileeṣẹ iroyin fọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ologun, ki wọn o si ma a gbe iroyin to ba dara jade nipa ileeṣẹ ologun, fun idagbasoke ati alaafia orilẹ-ede Naijiria.

Ṣugbọn ṣa, Agbẹnusọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu, sọ pe igbiyanju lati fi iṣejọba Aarẹ Buhari ṣe ẹlẹya, ni nkan to ṣẹlẹ ni ileeṣẹ ologun.

Garba Shehu sọ pe iṣẹlẹ naa bani lọkan jẹ.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ni ile ẹkọ ologun naa fi atẹjade sita pe awọn agbebọn kọlu ile ẹkọ naa, to wa ni Afaka, Kaduna.

Awọn agbebọn naa wọ ibugbe awọn ọmọ ogun, ti wọn si pa eeyan meji. Wọn tun ji ẹnikan gbe lọ.

Ọjọ keji iṣẹlẹ naa si ni iroyin jade pe oju orun ni awọn ọmọ ogun to n mojuto ẹrọ ayaworan CCTV to wa ninu ọgba naa wa nigba ti ikọlu ọhun waye.

Ṣugbọn, ileeṣẹ ologun sọ pe irọ ni iroyin naa.