You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NDA Attack: Ìkọlú sí NDA ti fihàn pé Buhari ń gbìyànjú l\ati sọ Nàìjíríà di Afghanistan ni- SOKAPU
Agbarijọpọ awọn ọmọ bibi apa guusu ipinlẹ Kaduna,SOKAPU ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu awọn agbebọn si ibudọ ikọnilẹkọ awọn ọmọ ogun Naijria NDA.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita, ẹgbẹ naa ni ikọlu yi fi han pe aarẹ n gbiyanju lati sọ orileede Naijiria di bi Afghanistan ti se ri ni.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa. Luka Binniyat sọ fun ileesẹ iwe iroyin Naijiria abẹlẹ kan , The Punch.
O ni pe ọna aibikita ti awọn ọdaran yi fi doju ija kọ ibudo awọn ọmọ ogun ti eeyan kankan ko si farapa ninu wọn n tọka si eewu nla gidi to n koju oselu awarawa ni Naijiria.
- Kò sí ọmọ Zambia kan tó má sùn pẹ̀lú ebi mọ́ lásìkò tèmi gẹ́gẹ́ bíi Aàrẹ- Hichilema ṣèlérí
- "Ó yẹ kí àwọn ẹ́ṣọ́ aláàbò lè mọ̀ pé àwọn jàndùkú fẹ́ kọlu ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà, NDA kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé"
- Ilé ẹjọ́ wọ́gilé ẹ̀bẹ̀ DSS láti dáwọn ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho mẹ́rin tó gb'òmìnira padà s'atìmọ́lé
- Ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé yóò wáyé ní Eko, Oyo, Ogun, Ondo àti ìpínlẹ̀ 30 míì láàrín ọjọ́ mẹ́ta- NiMet
- Wo ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn márùn ún tí àwọn èèyàn ilú Eko fi kan àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA
- Wo ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ fún àgbà nọ́ọ̀sì tó ta ọmọ ọdún mẹ́fà ní N200,000
Ẹgbẹ naa sọ pe ti wọn koba ṣe nkankan si ikọlu yi, o ṣeeṣe ki ''ijọba Buhari maa palẹmọ ohun ti yoo ṣẹlẹ mi to n bọ ni''
O ni ''Ipaniyan awọn ọmọ ogun meji yi ati ijinigbe ọgagun kan ko ya awa ọmọ ẹgbẹ SOKAPU lẹnu rara.
Idi ni pe iru ikọlu bẹ ti waye lẹẹmeelo kan ni bareke awọn ọmọogun to wa ni ile ẹkọ Command and Staff College, Jaji to wa laarin Zaria ati Kaduna.
Ninu ikọlu yi wọn ji maalu ati nkan ini miran lọ''
Binniyat wa kilọ pe ti wọn ko ba gbe igbesẹ ni kiakia ki wọn si mu awọn ọdaran yi,o ṣeeṣe ki iru nkan to waye ni Afghanistan ṣẹlẹ ni Naijiria.
"Ọrọ ẹnu aarẹ latẹyinwa ati iṣeṣi rẹ fi han pe ko bikita lati gbe agbara fawọn alakatakiti''
''Boya iṣẹlẹ aburu yi yoo ta gbogbo eeyan ji yatọ si aarẹ Buhari ati awọn agbodegba rẹ nitori ero wọn si ọmọ Naijiria ko sunwọn rara''
O wa kesi gbogbo ọmọ Naijiria alti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yi.
- Wo ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ fún àgbà nọ́ọ̀sì tó ta ọmọ ọdún mẹ́fà ní N200,000
- Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé ẹjọ́ sọ pé kí Lizzy Anjorin san 9.5m fún ẹni tó pé lẹ́jọ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀?
- Ogúnlọ́gọ̀ àwọn dókítà bẹr̀ẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ l'Abuja lọ́nà àti sálọ sí Saudi Arabia
- Ẹ ṣọ́ra fún "Crate challenge" nítorí ó lè sọ yín di èrò ilé ìwòsàn- àwọn dókítà kìlọ̀
- Ìkọlù tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ ológun ní Kaduna le jẹ́ ète láti fi ìjọba Buhari ṣe ẹlẹ́yà - Garba Shehu
- Nǹkan tí a mọ̀ nípa ìkọlù tó wáyé ni Kabul
O ni ki wọn si pe Gomina Kaduna Nasir El Rufai ati aarẹ Buhari si akiyesi lati gbaju mọ ojuṣe wọn ki Naijiria to tẹri sinu ọọfin ti awọn ko lero rara.
Bi a ko ba gbagbe lowurọ kutu ọjọ Iṣẹgun lawọn agbebọn yawọ NDA ti wọn si pa ọmọ ogun meji ki wọn to ji ọgagun kan gbe salọ.
Titi di ba ṣe n ṣakojọ iroyin yi, a ko ti mọ pato ibi ti wọn gbe lọ ṣungbọn ijọba gba ẹnu ileeṣẹ ologun sọrọ pe awọn yoo sawari awọn ọdaran yi.
Ìkọlù sí NDA yìí ní yóò múṣẹ́ yá lórí fífi òpin sí ìwà ọ̀daràn ní Nàìjírà-Ààrẹ Buhari
Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ pe ìkọlu tó wáyé ni ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ́ NDA láti ọwọ awọn agbébọn ni yóò mu ki iṣẹ́ yá lórí fifi òpin sí ìwà ọ̀daran ni Nàìjíríà.
Ààrẹ Buhari, lásìkò tó n sọ̀rọ̀ lóri ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáye lọ́jọ́ Isegun ni Afaka ipinlẹ Kaduna nibi ti wọn pa awọn ọmọogun meji, ti wọn si pa ọkan.
Gẹ̀gẹ́ bi àtẹjáde tí olubádámọ̀ràn fún ààrẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tó n lọ Fẹmi Adesina fọ́wọ́ sí ló ti fi ìdí rẹ́ múlẹ̀ pé ìkọlù tó wáyé ni NDA ni yoo palẹ ìwa ọ̀daran mọ́ ni Nàìjíríà.
" Ìkọlu tó wáyé ni ọgbà NDA yóò túbọ̀ kún àwọn ọmọogun lágbára ni kaka ti yóò fi da omítuntun si wọn lọ́kan gẹ́gẹ́ bi nǹka ti wọ́n ń fẹ́." Gẹ́gk bi ààrẹ ṣe sọ.
"Ó tọ́ka sí pé ìkọlù náà tó yọri si pipadanu ẹmi àwọn ènìyàn wáyé ni àsìkò tí àwọn ọmọogun ti mu àwọn ọ̀daran wá sínú ìbẹ̀rù bojo, à[rẹ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni yóò mu kí ìjọba tu ìwà ọ̀daràn ti gbòngbòti gbòngbò.
Ààrẹ kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ẹbí tí wọ́n pàdánù ènìyàn wọn , ti o sì gbàdúra kí ọlọrun tù wọ́n nínú.
Ààrẹ Buhari búra fún àwọn ẹbi àwọn olóògbé pé wọ́n ko ni kú lásán àti pe oun ṣetán láti yanjú gbogbo ìṣòrò yìí.
"Bákan náà ni ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà àti àwọn ọmọogun Nàìjíríà, ti ó sì rọ àwọn tó n fi òṣèlú ṣe gbogbo nǹkan lori ọ̀rs ètò abo láti sọra .
Ọ̀gá àgbà awọn ọmọogun ni gbogbo pálapàla yìí gbọdọ̀ dáwọ́ dúró
Ẹ̀wẹ̀, oga àgbà ilé iṣk ọmọogun Lucky Irabor ti fi ẹdun ọkàn rẹ̀ hàn lóri ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ni ọgbà NDA .
Ó sàpejúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bi "ìwà orí dídàrú" o ní èyí kìí ṣe ìwà àwọn jànduku ti gbogbo ènìyàn mọ̀.
- Wo ìgbà mẹ́ta tí Olusegun Obasanjo ti fi ìdọ̀bálẹ̀ nàá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ níwájú àwọn oríadé
- Famodun, Alága APC Osun., lọ jáwọ́ nínú ẹjọ́ APC tó wà nílé ẹjọ́- Gomina Oyetola
- Èèyàn márùn ún kú, ọ̀pọ̀ míì farapa lásìkò rògbòdìyàn àwọn ọmọ onílẹ̀ l'EKo
- Ìjà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni o, àwọn dókítà NARD tó ń yanṣẹ́lódì fárígá pẹ̀lú ìjọba
- Obìnrin di gómìnà ìpínlẹ̀ New York fún ìgba àkọ́kọ́ l'Amẹrika
Ọ̀gá àgbà náà sọ èyí lásìkò tó n bá àwọn ońíròyìn ni Yola ni olúùlú Adamawa lọ́jọ́ Isegun.
Irabor ni: Ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ni Kaduna jẹ ti ìwà àwọn jànduku, sùgbọ́n ó jọ mọ bi ẹni pé, àwọn ọdàran wa jale nínu ilé ni.
Bi wọ́n ṣe wọ inú ibl kìí ṣe ọ̀nà ti àwọn jàndùkú tí gbogbo ènìyàn mọ̀ ṣe máa n ṣe ni èyí, sùgbọ́n gbogbo nǹka ti a n wò ni èyín ti a si n ṣe ìwádìí.
Nínú àtẹ̀jadé ti adarí ètò ọ̀rọ̀ tó n lọ ọmọogun Benjamin Sawyer fọwọ́sí lo ti ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọogun n lepa àwọn ọdaran náà lójú méjèèjì.
- Wọ́n búra fún Aarẹ tuntun ní Zambia, inú ará ìlú dùn fún ìlérí tó ṣe fún wọn
- Tètè wá gbé òkú eèyàn rẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ a ó sìn wọ́n papọ̀ mọ́ tí 200 lópin ọ̀sẹ̀- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Òní ni àyájọ́ ọdún Udiroko nílùú Ado Ekiti níbi tí Ọba yóò ti jẹ iṣu tuntun
- "Ó yẹ kí àwọn ẹ́ṣọ́ aláàbò lè mọ̀ pé àwọn jàndùkú fẹ́ kọlu ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà, NDA kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé"