Mínísítà féré ìdárayá, Sunday Dare sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìdójútini tó wáyé ni Tokyo 2020 Olympics

wọn gbe oludije ọmọ Naijiria kan soke lẹyin to pegede.

Oríṣun àwòrán, olympics.com

Minisita fere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ lorilẹede Naijiria, Sunday Dare ti tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ Naijiria.

O ni oun bebe fun idojuti to de ba orukọ orilẹede Naijiria ninu eyi ti awọn elere idaraya kan to n ṣoju Naijiria nibi ti wọn ti n fọwọ fọ aṣọ imuṣẹrẹ idaraya, iyẹn Jẹsi wọn.

Sunday Dare ti ọpọ ọmọ Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu fun ohun iwọsi to waye ni ibi idije Tokyo 2020 Olympics to ṣẹṣẹ pari.

Ami ẹyẹ meji ni Naijiria gba nibi idije naa, bi o til.ẹ jẹ pe ohun ni eyi to dara julọ fun Naijiria laarin ọdun mẹtala, sibẹ ọpọ onwoye ere idaraya ni Naijiria ni o yẹ ki orilẹede Naijiria ṣe daradara ju eyi lọ.

Oniruuru kudiẹkudiẹ ati aikun oju iwọn awọn alakoso ere idaraya ni Naijiria lo waye.

Akọkọ ni bi ajọ ere idaraya lagbaya ṣe yọ ọwọ kilanko awọn elere idaraya mẹwaa lati Naijiria lawo idije naa lẹyin ti awọn alakoso ere idaraya ni

Naijiria kuna lati ṣe awọn ohun kan to yẹ ki wọn ṣe lori awọn oludije naa.

Sunday Dare ni oun tiraka pẹlu igbesẹ gbogbo to yẹ nigba ti iroyin iṣẹlẹ naa de ọdọ oun ṣugbọn aṣọ ko ba ọmọyẹ mọ nigba naa.

Àkọlé fídíò, Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú

Minisita fere idaraya ṣalaye ninu atẹjade rẹ kan pe awọn eeyan kan wa ti wọn pete ati gbin wahala ati idarudapọ.

Sugbọn awọn oludije to ṣoju fun Naijiria ko lẹtọ si itiju ti oju wọn ri nitori pe gbogbo igbaradi to yẹ ni wọn ṣe lati yege ninu idije Tokyo 2020 Olympics naa.

wọn gbe oludije ọmọ Naijiria kan soke lẹyin to pegede.

Oríṣun àwòrán, olympics.com

O ni Naijiria yoo gbe ajọ kan kalẹ ti yoo maa ṣe ayẹwo gbogbo to ba yẹ fun awọn oludije ati elere idaraya gbogbo ni Naijiria.

O ni eyi yoo je ki wọn lee maa la ilana gbogbo ti ajọ ayẹwo agbaye WADA kọja.

Bakan naa ni Minisita Sunday Dare tun kọminu lori iṣẹẹ aito awọn aṣọ ere idaraya fawọn oludije.

Eleyii to ṣokunfa bi ọkan lara awọn oludije naa ṣe ni lati maa fọwọ fọ aṣọ wọn.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́

O ni gbogbo awọn ajọ ere idaraya gbogbo to n kopa ni idije Olympics naa ni wọn ti fun ni ohun gbogbo to yẹ fun ipese awọn ohun eelo fawọn oludije wọn ninu eyi ti aṣọ ere idaraya wọn gbogbo wa.

O fi kun un pe wọn ti paṣẹ fun ajọ ere idaraya oludije ti ọrọ naa kan lati pese alaye to yẹ lori ọrs aṣọ ereidaraya naa.