You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
T. B Joshua: Chris Okotie ní wòlíì èké, onídán àti onítànjẹ tó ń fi ara rẹ̀ wé Jesu ní Joshua
Pasitọ agba fun ijọ Household of God, Chris Okotie ti sapejuwe wolii TB Joshua gẹgẹ bi opurọ, wolii eke ati onidan to n fi bibeeli lu awọn eeyan ni gbajuẹ.
Oloogbe TB Joshua, ẹni to fẹsun yii kan ni oludasilẹ ijọ Synagogue Church of All Nations (SCOAN), to jade laye lọjọ Kẹfa osu Kẹfa ọdun 2021.
Ninu fọnran fidio kan to fi sita loju opo Youtube lọjọ Aiku, ni Chris Okotie ti sọ ọrọ yi nigba to n se atupalẹ iru onigbagbọ ti TB Joshua jẹ nigba aye rẹ.
- Pásítọ̀ kan ń ké Halleluya pé TB Joshua kú, ó ní àjẹ́ ńlá ní Afíríkà lọ
- Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti
- Mo rí Áńgẹ́lì mẹ́fà tó wá gbé Wòlíì TB Joshua lọ sọ́run - Àlúfáà kan kéde
- Wo àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun jàǹkàn ní Naijiria tí kò yọjú síbi ayẹyẹ ètò ìsìnkú TB Joshua
- Àlùfáà kan níbi tí wón bí Jesu sí tan àbẹ̀là nítorí ikú T.B. Joshua
- Ọ̀rọ̀ tí ọkọ́ mi sọ gbẹ̀yìn nílé ìjọsin lọ́jọ́ tó kú, kún fún ẹ̀rù àti ìpayà - Aya TB Joshua
- Wo ohun tí Dele Momodu sọ nípa TB Joshua lẹ́yìn ikú rẹ̀
Bẹẹ naa lo fẹsun kan Joshua pe wolii eke to n fi ara rẹ we Jesu ni.
"Ki ni ododo nipa TB Joshua? Ta nii se? Njẹ ẹlẹsin Kristẹni ni tabi ọmọ lẹyin ẹsin shamanism? Njẹ ọmọlẹyin Jesu Kristi Oluwa wa ni? Tabi gbarọgudu alarinka?"
"Se wolii tootọ ni abi awọn eeyan si ọrọ rẹ gbọ?Tabi ka si ni sekusẹyẹ to sa sabẹ ẹsin nii se?"
Diẹ ree ninu awọn ibeere ti Pasitọ Chris Okotie fi sita ninu fidio naa.
O tẹsiwaju pe ''Joshua ko pe ara rẹ ni Aposteli tabi Olukọni. Ko tiẹ pe ara rẹ ni Pasitọ nitori to ba pe ara rẹ lorukọ mi to yatọ si wolii, ko kunju osunwọn awọn orukọ wọn yi''
O ni idi ree ti ko fi le yi orukọ pada.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí Sunday Igboho fi ń ṣe ẹjọ́ ní Benin - Femi Falana
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
- Agbo PDP ń gbóná janjan, ìpàdé àwọn gómìnà lórí Secondus forí ṣánpọ́n
- Ọmọ ìyá méjì tó ń lọ ṣe ìdánwò NECO wà lára èèyàn márùn ún tí tírélà agbépo tẹ̀ pa n'Ibadan
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n ó fi Chidinma Ojukwu tí wọ́n lo pa Ataga sí ẹ̀wọ̀n
- Ajínigbé yìnbọn pa ọkọ, jí ìyàwó àti ọmọbìnrin rẹ̀ gbé lọ l'Ekiti
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìbálòpọ̀ lásìkò nǹkan oṣù lè ṣekúpa ọkùnrin?
- Babaláwo fi ọ̀dọ́ tó fẹ́ ṣe òògùn owó, ṣe ètùtù owó fún ara rẹ̀
Okotie sọ pe ''O gbọdọ duro ti ipo to gbe fun ara rẹ yii ni. Onpidan to pe ara rẹ ni wolii nii se ati pe wolii eke ni.
Ninu fọnran yii bakan naa Okotie sọ pe Joshua n polongo igbagbọ to gbe ọla ati ipo bi Ọlọrun fun ara rẹ.
Bẹẹ ni o tun sọ pe Wolii Joshua a maa tan awọn eeyan jẹ nipa sise isẹ aanu, ki o ba le dabi pe iwa ati ise rẹ wa ni ibamu pẹlu ohun ti bibeeli sọ.
Ohun to fa ki Okotie maa sọ iru ọrọ bayi nipa Joshua paapa lẹyin iku rẹ ko ye wa si.
Amọ lati igba ti wolii Joshua ti papoda ni Okotie ati awọn pasitọ mii ti n bẹnu atẹ lu.
Wolii TB Joshua nigba aye rẹ jẹ oniwaasu, ti ko fi taratara ba awọn akẹgbẹ rẹ mii ni Naijiria se.
Lọpọ igba lawọn nkan mii to maa n sọ ninu iwaasu rẹ maa n da awuyewuye silẹ.
Titi di igba ta fi n se akojọ iroyin yii, a ko gbọ esi kankan lati ile ijọsin TB Joshua tabi mọlẹbi rẹ lai tako ohun ti Okotie n sọ.
Saaju ki o to di ẹni to n polongo ẹsin, olorin takasufe ni Chris Okotie jẹ.
O tun fi igba kan sọ pe oun gbọ ipe lati di aarẹ orileede Naijiria.
Igbiyanju rẹ lati dije dupo aarẹ ja si pabo ninu idibo eyi to kopa lẹẹmẹta ọtọọtọ ni ọdun 2003,2007 ati 2011 labẹ asia ẹgbẹ oselu Fresh Party.