You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osun Masqurade attack: Kayode Esuleke, olórí egúngún to bá àwọn musulumi jà ní Osogbo wà láhámọ́ ọlọ́pàá
Rogbodiyan to waye laarin awọn ẹlẹsin musulumi ti ijọ Kamorudeen Society Central Mosque ati eleegun nilu Osogbo ni ọjọ Àìkú ti gba ọna miran yọ.
Idi ni pe ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun ti mu olori awọn eleegun naa, oloye Kayode Eṣuleke si ahamọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho ní digbí lòun wà lẹ́yìn Nnamdi Kanu àti ìdásílẹ̀ Biafra
- TAMPAN bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn igun tó ń bínú, ọ̀rọ̀ yóò yanjú láìpẹ́ - Femi Adebayo
- Ta ló fẹ́ jí Auxilliary gbé ní Ibadan?
- Àwọn àgbà Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìbẹ̀rù pé wọ́n le gbé Sunday Igboho lẹ́yìn tọ́wọ́ tẹ Nnamdi Kanu
- Eré wa ni kẹ wò, ẹ má wo aṣemáṣe àwa onítíátà - Olaiya Igwe
- Èèmọ́ wọ̀lú, ta ló yìnbon pá Babalawo àti ẹlòmíì, tí ọ̀pọ̀ sì fara pa ní Ajaawa?
- Bíṣọ́ọ̀bù Enugu ní obìnrin ni wọ́n fi mú Nnamdi Kanu
- Ẹni tó bá tàbùkù àgbà níta, ti ń bú òbí rẹ̀ nílé tẹ́lẹ̀ - Yomi Fabiyi
Gẹgẹ bi iroyin abẹle kan ṣe sọ, ikọ ọtẹlẹmuyẹ fun ọga agba ọlọpaa, IG Intelligence response Unit, lo ranṣẹ pe oloye Esuleke si ileeṣẹ wọn nilu Osogbo fun ifọrọwanilẹnuwo nibẹ, ti wọn si ti fi si ahamọ.
"Àwọn Mùsùlùmí fẹ́ ṣí ẹ̀kú Eégún mọ́ wa lórí, wọ́n gún ọmọ kan lọ́bẹ́, ìfun rẹ̀ tú jáde"
Lẹyin rogbodiyan to waye laarin awọn eleegun atawọn ẹlẹsin Musulumi niluu Osogbo, awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ti baba BBC Yoruba sọrọ lori ohun ti oju wọn ri.
Lasiko ti BBC Yoruba ṣabẹwo si agbegbe naa, ọkan lara awọn Musulumi ọhun, Salahudeen Yusuf sọ pe adura ki Naijiria le dara ni awọn n gba lọwọ, ki awọn eleegun naa to kọlu awọn.
O ni "Bi a ṣe kirun Aila tan ni awọn eleegun naa n lulu kọja, lẹyin naa ni wọn duro lagbegbe mọṣalaṣi wa."
"Ka to wi ka to fọ, wọn ti bẹrẹ si n sọko si wa, ti wọn si bẹrẹ si n yinbọn si wa."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
- Oríire dé! Aláànú kan fún Kemisola ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ dé fásitì
- Omo Borty sọ̀rọ̀ sókè lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àti Dino Melaye
- Òǹyẹ̀ kò lè yẹ ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, mò ń bọ̀ níbẹ̀ - Sunday Igboho
- Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
- Òwọ́n gógó epo bẹntiró ń kànlẹ̀kùn bí IPMAN ṣe ń múra láti daṣẹ́ sílẹ̀
- Á ba ọrọ̀ ajé Nàíjíríà jẹ́ nípa fífọ́ ọ̀pá epo rọ̀bí - Niger Delta Avengers
- Ẹ̀mí kan bọ́, ọ̀pọ̀ farapa ní Mọ́ṣáláṣí l‘Osogbo lásìkò àdúrà ètò ààbò táwọn Egúngún ṣe
- Dino Melaye sọ̀rọ̀ sókè lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọn ló ní pẹ̀lú àwọn òṣèrẹ tíátà
"Ibọn ba baba agbalaga kan lara wa, awọn miran ti ibọn ba ṣi wa nile iwosan LAUTECH bayii nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ."
Ki ni awọn elegun sọ?
Obinrin kan lara awọn Musulumi naa tun ṣalaye fun BBC pe, awọn ọlọpaa wa lara awọn elegun naa, ṣugbọn gbogbo akitiyan awọn lati rọ awọn ọlọpaa ọhun lati pana rogbodiyan naa, lo ja si pabo.
O ni awọn ko mura ija, bẹẹ ni awọn ko ba awọn eeyan naa ja nitori adura lawọn n gba, ṣugbọn awọn eleegun naa lo kọlu awọn, ninu eyii ti ẹmi kan ninu wọn ti sọnu.
Alaye awọn Eleegun ree:
Ẹwẹ, BBC kan si aṣoju idile awọn eleegun naa, Fasola Esuleke, to si sọ pe eegun idile wọn kii ṣe eegun oni jagidijagan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn elegun naa n kọja lọ lagbegbe ti Mọṣalaṣi ọhun wa ni, ki awọn Musulumi ọhun to tọ ija awọn.
Fasola ni awọn kan n kọja lọ ni, kii ṣe awọn ya lọ ba awọn Musulumi naa.
O ni "Igba ti a n bọ ni gbogbo wọn kọlu wa to fi mọ awọn ọmọde to wa lara awọn."
"Wọn ko ada, igo ati okuta to fi mọ ibọn, koda wọn dana silẹ ti wọn si pe awọn yoo sun ẹku eegun."
"Nibi ti a ti n du ki wọn ma farakan egungun, ni ọkan lara wọn gbiyanju lati ṣi ẹku egun kuro loju rẹ ṣugbọn egun ọhun salọ."
Fasola tẹsiwaju pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn Musulumi naa ati olori wọn yoo kọlu awọn.
O fi kun pe pupọ ninu awọn ni wọn ṣe leṣe, koda o ni wọn gun ọmọ kan lara wọn lọbẹ ti ifun rẹ fi tu jade.
Aṣoju eleegun naa pari ọrọ rẹ pe awọn ko gbọ pe ẹnikẹni jade laye lasiko rogbodiyan naa.
Ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ṣalaye fun BBC pe wọn ti fi ọrọ naa to awọn leto, lootọ si ni ikọlu waye ṣugbọn awọn ko tii le sọ ẹni to kọkọ kọlu ara ninu igun ẹgbẹ.
Opalola ṣalaye pe lootọ ni ẹnikan ba iṣẹlẹ naa lọ ṣugbọn awọn ko tii mọ irufẹ ẹni ti ẹni naa jẹ, nitori awọn mọlẹbi rẹ ko tii wa sọdọ awọn.
O fi kun pe awọn ti fi ṣikun ofin mu awọn eeyan kan, ṣugbọn o ni oun ko tii le sọ ni pato iye eeyan ti awọn ti mu.
Opalola pari ọrọ rẹ pe kii ṣe awọn Fulani lo wa nidi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ẹ̀mí kan bọ́, ọ̀pọ̀ farapa ní Mọ́ṣáláṣí l'Osogbo lásìkò àdúrà ètò ààbò táwọn Egúngún ṣe
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe rogbodiyan kan bẹ silẹ nilu Osogbo lọjọ Aiku ana eyi ta gbọ pe o mu ẹmi eeyan kan lọ nigba ti ọpọ eeyan miran sese pupọ.
Bi o tilẹ jẹ pe a ko tii lee fidi ohun to fa wahala yii mulẹ amọ gẹgẹ bi iwe iroyin Osun Defender ti wi, awọn egungun kan to dihamọra pẹlu ohun ija oloro lo fa sababi isẹlẹ naa.
A gbọ pe awọn egungun yii lo ti kọkọ n dun mahuru-mahuru tẹlẹ pẹlu awọn janmọ Mọsalasi kan ti ijọ wọn n jẹ Kamorudeen Islamic Society.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Látìgbà tí mo ti dé láti àhámọ́ ọlọ́pàá, ni mo ti ń rí ẹ̀jẹ̀ nínú ìgbọ̀nsẹ̀ mi - Baba Ijesha
- Ẹ yéé yá ìjọba Nàìjíríà lówó mọ́- Akintoye Ukiwe àti àwọn 125 mííràn kọ̀wé sí World Bank
- Dino Melaye sọ̀rọ̀ sókè lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ tí wọn ló ní pẹ̀lú àwọn òṣèrẹ tíátà
- Olórin bíi Tiwa Salvage ni mo fẹ́ jẹ́ lọ́jọ́ ìwájú, ẹ má jẹ́ kí ń kú - Chidima afurasí apààyàn
- Àwọn àjẹ́ fọhún síta lórí ìgbésẹ́ àti pín Nàìjíríà sí wẹ́wẹ́
- Ẹgbẹ́ òṣèré tíátà, TAMPAN fọnmú mọ́ Iyabo Ojo àti Nkechi Blessing lọ́wọ́
- Bí ìlànà ìsìnkú TB Joshua yóò ṣe lọ rèé - Mọ̀lẹ́bí kéde
- Yomi Fabiyi fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Iyabo Ojo lẹ́yìn béèlì Baba Ijesha
- Iyabo Ojo gbé fídíò míì síta nípa Olofana àti ìhùwàsí àwọn onítíátà lẹ́yìn béèlì Baba Ijesha
Asiko ti awọn ijọ ẹlẹsin Islam yii, to wa ladugbo Oluode Aranyin nilu Osogbo, si n se adura lọwọ ni wahala ọhun fọnna soju ni deede aago meji abọ ọsan.
Se la gbọ pe awọn egungun yii, to ti kọkọ n paraaro agbegbe ti mọsalasi naa wa, ti wọn n lọ, ti wọn n bọ, ba sadede bẹrẹ si sọ okuta lu awọn to n kirun nibẹ.
Osun Defender, to ba ọkan lara awọn to fara gbọgbẹ nibi isẹlẹ naa sọrọ, jabọ pe awọn egungun ọhun lo de si adugbo naa pẹlu ikọ ọlọpaa ati Amotekun.
Amọ bawọn ikọ agbofinro naa se fi agbegbe ọhun silẹ, ni awọn egungun naa fa ibọn yọ, ti wọn si n yin lakọ-lakọ.
Asiko ti ibọn yii si n dun, la gbọ pe ibọn ba Baba ijọ Mọsalasi naa, Moshood Salawudeen, to si jade laye loju ẹsẹ.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, Imaam Mọsalasi naa, Quyum Yunus ẹni to fidi isẹlẹ naa mulẹ salaye pe, awọn egungun yii lo ni awọn n seto adura fun orilẹede Naijiria tori aabo to mẹhẹ.
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ko tii sọ ohunkohun lori isẹlẹ yii amọ BBC Yoruba yoo tẹsiwaju lati tanna wadi isẹlẹ yii, ta si mu abọ rẹ wa fun yin laipẹ.