Fuel Scarcity: IPMAN sọ fáwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ láti daṣẹ́ sílẹ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun

Ọwọn gogo epo bẹntiro tun ti n kan ilẹkun gbọngbọn lorilẹede Naijiria tori bi ẹgbẹ awọn alagbajata epo rọbi, IPMAN se n gbero lati gbe awọn ileepo tipa kaakiri Naijiria.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aiku niluu Jos, agbẹnusọ fun ẹgbẹ IPMAN, Yakubu Suleiman ṣalaye pe, ẹgbẹ naa ti sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ lati da iṣẹ silẹ nitori bawọn ọlọpaa ti n dunkoko mọ wọn.

Suleiman ni awọn ọlọpaa tun ṣadede yabo olu ileeṣẹ ẹgbẹ IPMAN lọjọ Ẹti, lori aawọ to n ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ lori ọrọ ipo olori.

O ṣalaye siwaju si pe, idajọ ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọdun 2018 sọ pe Ọgbẹni Chinedu Okoronkwo ni aarẹ ẹgbẹ IPMAN, nigba ti Alhaji Danladi Garba Pasali, si jẹ akọwe agba.

Suleiman ni bi awọn ọlọpaa ṣe n tapa si idajọ ileẹjọ yii ko le bi ọmọ rere fun ẹka epo rọbi ni Naijiria.

Agbẹnusọ ẹgbẹ IPMAN ni afaimọ ki igbesẹ awọn ọlọpaa yii maa jẹ ki ẹka epo rọbi ni Naijiria dẹnu kọlẹ.

Suleiman ṣalaye pe ọwọn gogo epo ni yoo ṣẹlẹ ti ẹgbẹ IPMAN ba le da iṣẹ silẹ lati ọjọ Iṣẹgun kaakiri orilẹede Naijiria.

O ni ẹgbẹ IPMAN ti n ṣepade kaakiri gbogbo ipinlẹ lati sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ wi pe ki wọn da iṣẹ silẹ.

Agbẹnusọ ẹgbẹ IPMAN wa ke si ijọba lati wa nkan ṣe si bi awọn eeyan kan to fi mọ awọn ọlọpaa ṣe n tapa si idajọ ileẹjọ lori ọrọ IPMAN.

O ni ko si igba ti ẹgbẹ naa ko ni gbe awọn ileepo ti pa ti ọga agba ọlọpaa ni Naijiria ko ba wa wọrọkọ fi ṣada lori bawọn ọlọpaa ṣe yabo ile ẹgbẹ IPMAN lori ọrọ ti ileẹjọ ti yanju.