You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sunday Igboho: Láti ọjọ́ Ajé lọ, màá bẹ̀rẹ̀ sí ṣa agbébọn jáde nínú igbó Yorùbá
Gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan nilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho tun ti ke gbajare fun awọn ọdaran darandaran lati fi ilẹ Yoruba silẹ.
Igboho kede pe bi awọn ọdaran to n paniyan naa ba kọ, oun yoo ri daju pe wọn fin wọn jade kuro ni awọn inu igbo ti wọn sa pamọ si.
Sunday Igboho fi ikilọ yii sita lasiko ifọrọwerọ to se ninu fidio kan to se pẹlu agbẹnusọ rẹ, o fikun pe oun kii kan sọrọ lasan, oun yoo sisẹ tọ ọrọ ti oun ba sọ lẹyin.
- Sunday Igboho kan sárá sáwọn ọmọ Yorùbá tó wọ́de lọ́jọ́ Sátidé, ṣùgbọ́n kò sọ ìdí tí kò fi jáde
- '' Ìrọ ní ò, N51.8million kọ́ ní àwọn Naijiria dá fún Sunday Igboho, N4milion ní''
- Ìrù ejò lẹ̀ ń fà pẹ̀lú ìkọlù lemọ́lemọ́ sílé Sunday Igboho - Àgbààgbà Yorùbá
- Ìyàtọ tàbí àfiwé wo ló wà láàrin Sunday Igboho, Nnamdi Kanu àti Asari Dokubo?
- Sunday Igboho, dẹ́kun ariwo fún ìyapa Nàíjíríà - YAF
- Seyi Makinde lo ṣí ilé mi tó jóná pẹ̀lú ‘transformer 500kva’ - Sunday Igboho
Bakan naa ni Igboho salaye pe ko si ọrọ anbojuwẹyin mọ lori idasilẹ orilẹede Yoruba, bẹẹ si ni ko si Jubita kankan to le yẹ igbesẹ naa.
O fikun pe ko si gomina kankan nilẹ Yoruba to le fi ọwọ gbaya pe ki iwọde nipa idasilẹ Yoruba Nation mase waye ni ipinlẹ toun nitori gbogbo ọmọ Yoruba lapapọ lo ni ilẹ wọn.
Gbajumọ ajijagbara naa wa sekilọ fawọn ọdaran to n fi inu igbo se asọ bora lati fi ibẹ silẹ, nitori lati akoko yii lọ, oun ko fẹ gbọ pe wọn ji eeyan kankan gbe nilẹ Yoruba.
"Bawo ni eeyan miliọnu mẹfa yoo se maa dari ọmọ Naijiria yoku ti wọn to ọtalerugba o din mẹwa (250m)? Igbeyawo kii se dandan, a ko le ba yin gbe mọ.
Ọkọ igbala ni idasilẹ orilẹede Yoruba jẹ, mo si fẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba ko wọnu rẹ, ki wọn si mu ijoko sibẹ."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Iyabo Ojo bẹ̀rẹ̀ ìjà rọ̀fọ̀rọ́fọ̀ pẹ̀lú máníjà rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lórí ẹ̀sùn olè jíjà
- Wo ikọ̀ aláàbò tuntun tí yóò gba iṣẹ́ ọlọ́pàá SARS ṣe l'Eko
- N5M ni a pàdánù lásìkò tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo lé wa kùró ní Sabo - Àwọn oníbárà
- Àwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì gbé lọ ní Kebbi
- Àjinigbé pa ọmọ méjì wọ́n ji méjì gbé lọ tí wọ́n jẹ́ ọmọ òbí kan ni Ondo
- Ṣé Princess lè sọ fáráyé iye ìgbà tó ti bọ́ aṣọ sí ìhòhò níwájú Baba Ijẹsha? -Mọlẹbi baba Ijẹsha gbarata
Nigba to n sọrọ lori isẹ ijijagbara fun ominira ilẹ Yoruba, Sunday Igboho ni ko si ọrọ anbojuwẹyin mọ nipa rẹ.
"Bawo la se fẹ pada sẹyin nigba to ku diẹ ka de ibi ta n lọ, awọn ti ko tii dara pọ mọ wa ni ki wọn se bẹẹ lasiko yii nitori ko ni si eto idibo kankan lọdun 2023. Yoruba n ya kuro lara Naijiria."
Sunday Igboho wa rọ awọn ọdọ lati dẹkun sisọ ọrọ abuku sawọn agbaagba nilẹ Yoruba, to fi mọ awọn ọba alaye wa.
"Ẹ jọwọ, ẹ mase maa pe ede ti yoo tabuku awọn agbagba tabi yaju sawọn oriade wa pe wọn ti gba owo. Ẹ ma se bẹẹ.
Koda, ti wọn ba tiẹ ti fun wọn lowo, ara ọrọ ajọni wa ti awọn kan ji ko ni.
Ẹ mase ba awọn agbofinro ja, ẹ jẹ ka se iwọde wa ni alaafia, kẹ si sọ fun aarẹ Buhari pe ti ko ba gbọ ede Yoruba, ẹ sọ fun ni ede Gẹẹsi.
Ẹ wi fun pe awa ko fẹ awọn agbebọn lẹkun wa, isẹ si ti bẹrẹ, lati ọjọ Aje lọ, maa bẹrẹ si ni lọ yika gbogbo igbo nla nla to wa nilẹ Yoruba lati le awọn agbebọn jade.
"Mo fẹ ki gbogbo Fulani to wa nilẹ Yoruba ko aasa wọn. Emi funra mi ni maa tọpinpin boya wọn tẹle asẹ naa, emi kii si sọrọ lai ma sisẹ tọọ. Maa jẹwọ ara mi fun wọn, ti mo ba tun gbọ pe wọn ji ẹnikẹni gbe nilẹ Yoruba."
Sunday Igboho ni oun yoo sọ fun wọn pe iyatọ wa laarin Yoruba ati darandaran nitori gbogbo awọn ohun ija ti wọn n gbe kiri ni oun yoo gba lọwọ wọn ni ẹrọ wọọrọ.
O ni awọn yoo fẹ afẹfẹ si gbogbo awọn inu igbo to wa nilẹ Yoruba nitori ti awọn ko ba tete jẹwọ iru eeyan ti Yoruba jẹ fun awọn agbebọn naa, wọn yoo tun maa wa lati gba ilẹ nigba ti orilẹede Yoruba ba da duro.
Ajijagbara fun ilẹ Yoruba naa tun sẹ pe oun ko gba owo lọwọ ẹnikẹni gẹgẹ bi awọn eeyan kan se n sọ kiri.
Tẹ ba mọ ẹni to ba fun mi ni owo pe ki n pa ijaguru fu idasilẹ Yoruba Nation ti, ẹ jade lati sọrọ bayii. Ko si iru owo to le mu ki n dakẹ lati ja fun ominira Yoruba.
Ẹ ko si le pa mi, ta lẹ pa? Ẹ ju bọnbu si mi abi? Tẹ ba ju bọnbu si mi, maa ran aara si yin. "
Bakan naa ni Sunday Igboho ni ko si ẹnikẹni to le ji oun gbe, tori oun mọ pe awọn eeyan Yoruba nifẹ oun.
"N ko sọnu o, a ti fẹrẹ de ilẹ ileri, gbogbo awọn to n tẹle mi lọ si iwọde, aabo to daju wa fun yin. Ko si ọlọpaa to le mu yin, ẹtọ wa la n beere, ko si sẹni to le dẹru ba wa lori ilẹ baba wa.
O wa rawọ ẹbẹ silẹ Gẹẹsi ati ajọ isọkan orilẹede agbaye lati seranwọ fun ilẹ Yoruba ki afojusun wọn le jọ.