Olagunsoye Oyinlola: A bẹ Obasanjo lásìkò ìbò ààrẹ 2015 ni kó tó gbà láti ti Buhari lẹ́yìn

Gomina ana nipinlẹ Osun, Ọmọọba Olagunsoye Oyinlola ti salaye lẹkunrẹrẹ nipa awọn isẹlẹ to n waye lagbo oselu orilẹede Naijiria.

Oyinlola, lasiko to n ba akọroyin iwe iroyin Punch sọrọ tun mẹnuba bi aarẹ ana, Oloye Olusegun Obasanjo, se pagidina erongba Bola Ahmed Tinubu lati jẹ igbakeji aarẹ Muhammadu Buhari.

O fikun pe ẹbẹ pọ ki Obasanjo to gba lati ti Buhari lẹyin pe ko dije fun ipo aarẹ lọdun 2015 lẹyin to tako isejọba Goodluck Jonathan.

Gomina ologun tẹlẹ nipinlẹ Eko naa fikun pe adehun ti wa saaju ibo 2015 pe laarin Buhari ati Tinubu pe ọkan yoo se aarọ Naijiria, ti ekeji yoo si se igbakeji rẹ, amọ adehun naa ko han si gbogbo ọmọ ẹgbẹ.

Oyinlola ni erongba awọn mejeeji yii lo n da ariyanjiyan silẹ ninu ẹgbẹ oselu APC nitori musulumi lawọn oludije mejeeji naa, eyi to fẹ gba awọn Kristiẹni sẹyin.

O ni ti kii ba se pe Obasanjo yari, ẹgbẹ oselu APC ko ba fa Buhari ati Tinubu kalẹ gẹgẹ bi oludije fun ipo aarẹ ati igbakeji rẹ, ko ba si nira fun wọn lati yẹ aga mọ Jonathan nidi.

Gomina alagbada nipinlẹ Osun naa tẹsiwaju pe, ọpẹlọpẹ Bukola Saraki, Ibikunle Amosun, Bola Tinubu, Kashim, Imam ati oun lo lọ ka Obasanjọ mọle nilu Ota ni deede aago meje aarọ pe ko ti Buhari lẹyin lati dije.

Bakan naa lo ni Obasanjo salaye pe fun awọn lọjọ naa lọhun lori idi to fi tako Buhari lati dije, eyi to wa n fi oju han sita bayi, nitori bo se sọ, bẹẹ naa lo n sẹ bayii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni Obasanjọ sọ pe "Buhari ti mo mọ yoo se daada ninu ọrọ to ba jẹ mọ isẹ ologun, amọ lẹyin eyi, Buhari ko mọ ohunkohun rara mọ, boya ni ẹka ọrọ aje ni tabi tọrọ ilẹ okeere.