You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nollywood: Wo àkójọpọ̀ ohun tó wáyé lágbo àwọn òṣèré tíátà lọ́sẹ̀ yìí
Oniruuru awọn isẹlẹ nla nla lo waye ni agbo awọn osere tiata lọsẹ yii ti ko yẹ kẹ padanu rẹ.
Bi awọn isẹlẹ kan se dun mọ ni ninu, ni awọn kan ba ni lkan jẹ, se tibi tire la da ile aye.
Awọn akojọpọ isẹlẹ to waye lagbo tiata lọsẹ yii re ni sisẹ n tẹle.
- Ta bá gba Seriki Fulani padà sí Igangan, a fi ọwọ́ ara wa, pa ara wa ni - Aráàlú
- Wo ọ̀dọ́mọdé olówó, tí àwọn ọkọ̀, fóònù, ọtí wáínì, ẹ̀ṣọ́ ilé rẹ̀ jẹ́ kìkìdá góòlù
- Ẹjọ́ ẹ̀ṣùn àjẹbánu márùn ún to milẹ titi ní Nàìjíríà lọdún 2020
- Buhari fọnmú bí Transparency International ṣe fi Nàíjíríà ṣípò kejì nínú ìwà àjẹbánu
- Ó wù mí kí ń padà sí Igangan, tí wọn bá fún mi láàyè - Seriki Fulani
- Èèyàn 75 di àwátì, 18 jáde láyé bí agbébọn ṣe gbàjọba yíka Nàíjíríà l‘Ọ́jọ́bọ
- Bí Sunday Igboho bá tàpá sófin, kí lẹ ṣe fáwọn ọ̀daràn Fulani tó ń pa èèyàn - Gani Adams
Mr Latin ati Odunlade Adekola gbe asọ Adirẹ lọ silu oyinbo:
Ori lo mọ iṣẹ aṣela laye. Bolaji Amusan ti ọpọ mọ si Mr Latin ati Odunlade Adekola lọ si ilu oyinbo niluu Vienna lorilẹede Austria nibi ayẹyẹ kanifa aṣọ Adire.
Mr Latin lo fi fọto oun ati Adekola nibi ti wọn ti wọ aṣọ Adire nibi ayẹyẹ ọhun niluu Vienna si ori ẹrọ Instagram.
MR Latin tiẹ sọ loju opo Instagram rẹ pe "ẹ o tii ri nkan kan", eyi to tumọ si pe wọn sẹsẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni.
Bobrisky rọ̀jò owó lé olólùfẹ́ lórí torí pé ó ya tattoo rẹ̀ sára:
Ori arabinrin kan lo ma ti sọre bayii lẹyin to ya "tattoo" Okuneye Olanrewaju Idris, ti ọpọ mọ si Bobrisky si ara rẹ.
Bobrisky funra rẹ lo fi fọto obinrin naa, to jẹ ọkan lara awọn ololufẹ rẹ si oju opo Instagram rẹ pẹlu "tattoo" to ya si ẹyin rẹ.
Bobrisky wa ṣeleri lati ṣe ohun mere-mere fun arabinrin naa.
O ṣeleri lati fun obinrin ọhún l'ẹbun miliọnu kan naira, ra foonu to ba fẹ fun un ati pe, oun maa gbe arabinrin naa rinrin ajo afẹ lọ si Dubai.
Dokita fun Kemi Afolabi ni oogun oorun lati fara nisinmi lẹyin ayẹyẹ isile rẹ:
Lẹyin to ṣe ayẹyẹ iṣile tan, oṣere tiata Yoruba, Kemi Afolabi wa ni igbele nibi ti o ti n sinmi.
O ni awọn dokita lo sọ foun pe oun nilo lati sinmi nile tori ilera ara oun.
Kemi ni oun ko mọ pe awọn dokita oun fi oogun orun sinu abẹrẹ ti wọn fún oun.
Muka Ray pàdánù àbúrò:
Iku doro, iku ṣeka, iku ti mu Lofty Eyiwumi Ray to jẹ aburo gbajugbaja oṣere Mukaddam Eyiwumi Ray ti ọpọ mọ sí Muka Ray lọ.
Loju opo Instagram rẹ ni Muka Ray ti sọ nipa iku aburo rẹ obinrin yii.
Ibeere "ki lo de, ki lo ṣẹlẹ" ni Muka Ray n beere pẹlu ẹdun ọkan lori oju opo Instagram rẹ.
Bakan naa lo fi ọrọ bii "sun re o, o daarọ si ori Instagram rẹ eyi to fi dagbere fun aburo rẹ to ṣe aláìsi.