You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Transparency International: Wo ẹjọ́ àjẹbánu márùn-ún tó ṣeéṣe kó fí Nàìjíríà sí ipò kejì lórí àtẹ ìwà àjẹbánu
Ko jẹ tuntun mọ wi pe ajọ Transparency International to n risi ọrọ iṣedodo ninu ijọba, gbe orukọ Naijiria jade gẹgẹ bi orileede keji lẹkun iwọ oorun ilẹ Afrika, ti iwa ajẹbanu ti gbilẹ julọ.
Iroyin yii jẹ eyi ti ko dun mọ ijọba aarẹ Muhammadu Buhari ninu nitori pe ọkan lara opo pataki iṣejọba rẹ ni lati doju ija kọ iwa ajẹbanu.
Eyi si lo mu agbẹnusọ fun aarẹ, Garba Shehu tutọ soke foju gba gidi pe ko tọ bi wọn ṣe gbe orukọ Naijiria jade ni ipo keji awọn orilẹede alajẹbanu ni iwọ oorun Afirika.
Idi si ree ti BBC Yoruba fi se akojọpọ awọn ẹjọ ajẹbanu to milẹ titi ni Naijiria, ti ijọba ti ṣe lọdun 2020 pẹlu awọn to fẹsun kan pe, wọn lu owo ijọba ni ponpo.
O si seese ko jẹ pe awọn ẹjọ kamilaya nidi iwa ajẹbanu naa, lo mu ki ajọ TI se odiwọn Naijiria bi orilẹede keji to kundun iwọn ajẹbanu ni iwọ oorun Afirika.
Diẹ ninu awọn ẹjọ ajẹbanu to milẹ titi ni ọdun 2020 ree:
Maina ati ẹsun sise owo tole ni biliọnu meji naira basubasu:
Abdulrasheed Maina to jẹ alaga igbimọ atunto ọrọ owo ifẹyinti ni Naijiria, ni wọn fi ẹsun pe o lu biliọnu meji owo awọn osisẹ fẹyinti ni ponpo.
Ẹjọ rẹ yii lọdun 2020 gba orisirisi ọna yọ debi pe, Sẹnẹtọ kan to gba oniduro Maina, iyẹn Senẹtọ Ali Ndume jawọ kuro ninu ẹjọ rẹ nigba to sa mọ ile ẹjọ lọwọ.
- Wo àwọn tó ti dákú bíi Maina níwájú ìjẹ́jọ́
- Ó tó gẹ́! Agbẹjọ́rò Maina yọ ọwọ́ kúrò nínú ìgbẹ́jọ́, Ó lóun kò ṣé mọ̀
- Ilé ẹjọ sún ìgbéjọ Maina síwájú lati fi okodoro àìlera rẹ hàn
- Mo pàṣẹ pé kí ọ̀gá owó ìfẹ̀yìntì tẹ́lẹ̀, Maina sì wà látìmọ́lé- Adájọ́
- Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà wọ́gilé ẹ̀wọ̀n Orji Uzor Kalu, pàṣẹ ìgbẹ́jọ́ tuntun
- Ẹ gbé Etete, Adoke àtàwọn míràn lórí ọ̀rọ̀ epo Malabu - Iléẹjọ́
- EFCC gba ọ̀pọ̀ owó àti dúkìá, ó tún fọwọ́ òfin mú afurasí 865 lọ́dún 2020
Ati Maina ati ọmọ rẹ, Faisal ni ile ẹjọ fiwe sita pe ki awọn agbofinro mu wọn wa siwaju adajọ.
Lẹyin ọpọ atotonu, wọn mu Maina wa lati orileede Niger to sa lọ, to si tun wa pada bẹrẹ si jẹjọ ẹsun ti wọn fi kan an.
Daniel Pondei ati iwadii ajẹbanu ogoji biliọnu naira owo NDDC:
Saaju ki o to daku loju gbogbo ọmọ Naijiria to n wo tẹlifisan, ọpọ eeyan ni ko fẹ ẹ gbọ orukọ Daniel Pondei ri.
Amọ nigba ti wọn bẹrẹ si ni beere bo ti ṣe ṣakoso owo ajọ to n se akoso agbegbe Niger Delta, NDDC, niwaju igbimọ iwadii kan nile aṣoju-ṣofin Naijiria to si ṣadede daku, gbogbo eeyan lo mọ.
Lootọ lo pada ṣalaye pe, oun ni ipenija ilera ni ṣugbọn ọpọ lo ri bo ti ṣe daku gẹgẹ bi ọgbọn ẹwẹ lati mase dahun ibeere ti awọn aṣofin n beere lọwọ rẹ.
Owo to to ogoji biliọnu Naira ni igbimọ naa n ṣe iwadii bi ajọ NDDC ṣe naa laarin ibẹrẹ ọdun 2020.
Titi di igba ta n ṣe akojọ iroyin yii, wọn ko ti ri owo naa yanju
Orji Uzor Kalu n jẹjọ biliọnu meje naira:
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu EFCC ti n ba Sẹnẹtọ Orji Uzor Kalu ṣẹjọ ọjọ ti pẹ, lori pe o ṣe owo ọba to to biliọnu meje naira baṣubasu.
Ẹsun mọkandinlogoji ni wọn fikan an, ti ile ẹjọ si ni ko maa lọ ṣẹwọn ọdun mejila lọdun 2019.
Ẹjọ yii ni wọn fa titi wọ ọdun 2020, ti ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria si pada gbe idajọ lelẹ pe, Uzor Kalu ati awọn mii ti wọn fẹsun kan, ko jẹbi.
EFCC tapa si idajọ naa, ti wọn si ni awọn yoo tubọ bẹrẹ igbẹjọ tuntun lori ọrọ Uzor Kalu.
Amọ ṣa, ba ti ṣe n sọrọ yii, Uzor Kalu jẹ aṣofin agba, to si n ba iṣẹ rẹ lọ nile aṣofin l‘Abuja.
Muhammed Adoke ati ẹjọ ajẹbanu $1.1 billion lori epo Malabu:
Ẹsun onipele meje ni wọn fi kan Minisita feto idajọ ati agbẹjọro agba Naijiria tẹlẹ, Mohammed Adoke.
Ko si sẹyin pe wọn lo gba abẹtẹlẹ, ki wọn ba le buwọlu idunadura ọrọ owo epo rọbi taa mọ si 'Malabu Oil deal.''
Ninu ẹsun ti wọn fi kan, wọn sọ pe o gba abẹtẹlẹ to to ọọdunrun miliọn Naira.
Saaju ni wọn ti bẹrẹ ẹjọ yii, ti adajọ si faaye gba Adoke lati lọ si Dubai fun ayẹwo ara rẹ.
Awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ agbaye, Interpol mu ni Dubai ti wọn si da pada wa si Naijiria ni oṣu Kejila ọdun 2019.
Wọn ko ribi ṣẹjọ yii pupọ lọdun 2020 nitori arun Covid-19 ṣugbọn o wa lara awọn ẹjọ ti Naijiria ṣe, to da lori ajẹbanu to milẹ titi.