You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lai Mohammed: Ọbasanjọ, bí ìwo bá ṣé réré, Ara kì yóò yà ọ?
Ẹní jẹ fufu lára n fu lọrọ Ọbasanjọ
Èsì ọrọ ree láti ọdọ ìjọba Buhari sí Obasanjo to so pe Buhari n pète láti ka ẹsùn sí òun lọrùn lasiko yii.
Mínísítà fun ètò ìròyìn, Oloye Láì Muhammed, lo fèsì naa pada pe ''aheso ọrọ ni Obasanjo n sọ ati pé ìjọba Buhari ko ráàyè a n diran moni lẹsẹ''
Ọrọ náà jẹyọ nínú atẹjade kàn ti o fí ṣòwò s'awọn akoroyin lọjọ Ẹtì nílu Èkó.
Lai Mohammed so pé àwọn kò ní jẹ kí ''ọrọ ti kò fidimule kánkan yí ìpinnu awọn pada, pàápàá jùlọ lẹyìn ìgbà tí àwọn ṣẹṣẹ kéde ìyípadà ti gbogbo ara ìlú tẹwọgbà.''
O tèsíwájú nínú atẹjade náà :''o ti fojú hàn pé ìgbésẹ tí a gbé láti kéde ìyípadà àṣìṣe ti awọn kan ṣé ló n biwon nínú nipasẹ ètò ìdìbò ti ará ìlú gba pé òhun lo yanranti julọ.''
''Èyí lo mú kí wọn má sare gbogbo ona láti fẹ pajá lọ́bọ fún ara ìlú''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Lai Mohammed ni aseyori ìjọba Buhari lo n ko Obasanjo lominu pàápàá jùlọ pẹlu bi ọ ṣe l'ànfààní ati mú ìyípadà bá ètò ilu ṣugbọn tí o kò láti ṣe òhun tó yẹ.
Ṣáájú ni ọjọ Ẹtì kàn náà ni Ààrẹ àná orílè-èdè Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo, ti figbe ta pé ìjọba Buhari n pète láti ka ẹsùn sí òun lọrùn.
Lẹnu ọjọ mẹta yí, itako ọrọ láàrin Obasanjo àti Buhari ti peleke sí i lẹyìn tí Obasanjo kọ leta sí Buhari lórí bí o tí ṣe n ṣètò ìlú.