You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iwe Aarẹ Ọbasanjo si Buhari: Awọn eniyan fi erongba wọn han
Sẹ ẹ anti iwẹ ti Aarẹ Ọbasanjo fi sọwa si Aarẹ Goodluck Jonathan nigba to wa lori oye?
Ni bayi ti Baba ti gboye omowe, o ti fi iwe mi sowo si Aare Muhammadu Buhari.Oun to kọ sinu re kọnilominu.
Bi a'n fa iwe ọmọ ẹgbe osẹlu re ya,to fi mọ kiko iwe si awọn to wa lori ipo,ko fẹ si iru ara ti Aarẹ Obasanjo ko ti daa bi o ba kan oselu ni ile Naijiria.
Ko fee si agba ọje oloselu ni ile Naijiria ti enu re to ọrọ bi Aarẹ Obasanjo.
Nigba to wa lọri oye ati igba to kuro naa, Obasanjo a ma dasi oro ilu loorekoore.
O tun ti dasi oro ilu bayi.
Iwe lo ko si Aarẹ Muhammadu Buhari nibi ti o ti parọwa pe ki o lo sinmi nile ko ma wule du ipo Aare lekan si.
Iwe naa waye lẹyin ojo mẹlo kan ti awọn olori egbẹ oselu APC ni ila orun ile yi fi ounte te ipadasipo Aarẹ Buhari lodun 2019.
Ninu atejade pataki oun ti o pe akori re ni ''Ona Abayo: ipe fun itesiwaju Orileede Naijiria"'
Aare Obasanjo toka si awon koko ọrọ kan ninu iwe re.Ninu won ni wipe :
•Aarẹ Buhari ko fi bee mo nipa ẹto ọrọ aje
•Ijoba Buhari ko kobi ara si ọrọ awọn daran daran to'n payan
•Ijoba Buhari feran ko ma di ẹbi ọrọ lu elo miran.
•O pe fun idasile ẹgbe akojopo awon ọmọ ile yi ti wọn setan lati mu ayipada to peye ba ilu.
•O da ẹbi ru awọn Gomina ti wọn korawọnjo lati fi ọunte te ipadasipo Aare Buhari lọjọ ti wọn sin awọn eniyan metalelaadorin nipinle Benue.
Obasanjo ko sẹsẹ ma ko iwe si Awon olori ile yi
Lọdun 2013,Aarẹ Obasanjo ko iwe si Aarẹ Goodluck Jonathan.Iwe alabala mejidinlogun oun ju ti Muhammadu Buhari toje abala iwe metala lo.
Sugbọn oun ti o wa ninu awọn iwe oun ko fe yato sirawon.Pataki julo ni wipe Obasanjo fi awon iwe naa fehonu re han nipa isejoba awon olori mejeji.
Awon agbenuso fun ijoba Buhari ko ti fo esi si iwe naa sugbon awon omo orilẹẹde yi ti bẹrẹ sini fi iriwisi won han lori ẹro Twita.
Se Aarẹ Muhammadu Buhari yoo tele arowa Obasanjo bii?
Iwe ti Aare Obasanjọ kọ si Aarẹ Goodluck Jonathan ko so eeso rere fun. Nigba ti idibo yoo fi waye lọdun 2015, Jonathan fidi rẹmi.
Aarẹ Buhari ko tii sọ boya oun yoo gbegba idibo lọdun 2019 sugbọn pẹlu bi awọn alatilẹhin rẹ ti se n ọrọ bọ, o seese ki o dije.
Bi o ba mu ọrọ Obasanjọ lo, ti o si lọ ọ sinmi nile, eyi yoo jẹ oun tuntun ti Obasanjọ naa nigba to wa lori oye ko le se.