You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọbasanjọ: Buhari ń pète láti ka ẹ̀sùn èké si mi lọrùn
Ààrẹ àná orílèèdè Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo, ti ke gbajare pe ìjọba Buhari n pète láti ka ẹsùn sí òun lọrùn.
Obasanjọ ní, ìjọba Buhari fẹ lo ayédèrú ìwé láti ṣe ìṣe aburú yìí.
Nínú atẹjade kàn láti ọwọ olùrànlọwọ rè lórí ọrọ ìròyìn, Kehinde Akinyemi, Obasanjọ ní, ọnà méjì ní wọn fẹ gba fí panpe mu òun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
''Àkọkọ ni pé, wọn fẹ ló àjọ to n gbogun ti iwa jegudu-jera, EFCC, láti bẹrẹ Ìwádìí padà lórí òhun tó ṣẹlẹ lasiko ìjọba mi''
''Ẹlekeji ni pé, wọn fẹ ló awọn ayédèrú ìwé kan láti ṣe àkóbá fún òun gẹgẹ bí wọn ti ṣe ṣe ní àsìkò ìjọba ológun Abacha.''
Kíni àwọn ọmọ Nàìjírìà ń sọ lórí ọ̀rọ̀ tí Obasanjọ lóri ìkànsíraẹni twitter:
Ọrọ yí láwọn kan ti ṣe àpèjúwe rè gẹgẹ bí èsì Obasanjo sí ìgbésẹ ìjọba Buhari, láti fi ọjọ ayajọ òṣèlú tiwá n tiwá da olóògbé Moshood Kasimawo Abiola lọla.