Tottenham sọ ọjọ́ ìsinmi olóyin di ''Black Sunday'' mọ́ Arsenal lọ́wọ́ pẹ̀lú ìgbájú-ìgbámú

Harry Kane

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ti eleyi kii ba ṣe ijamba nla? Ẹ jọwọ kinni ka ti pe eyi naa?

Igbaju igbamu ni kẹri kẹri n ba rode ni ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham fi ṣe fun Arsenal ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn ọjọ Aiku ninu idije Premier League.

Afi bi ala ni ọrọ naa ri nigba tawọn ẹgbẹ agbabọọlu olorogun mejeeji ti wọn fi apa ariwa ilu London ṣe ibujoko kọju ija si ara wọn.

Ki a to wi, ki a to fọ, ẹlẹsẹ ayo, Heung-Min Son ṣi gbada lori Eṣu lẹyin to gba goolu goolu aramọnda kan wọle Arsenal ni bii iṣẹju mẹtala.

Arsenal gbiyanju lati da goolu naa pada, ṣugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju ja si.

Amọ eruku tun sọ lala nigba to ku diẹ ki ipele akọkọ ifẹsẹwọnsẹ naa pari lẹyin ti Harry Kane gbayo mii wọle Arsenal.

Alexandre Lacazette ati Steven Bergwijn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo igbiyanju Arsenal lati gbayo wọle Tottenham ni ipele keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun, pabo lo ja si.

Arsenal ti wa ni ipo kẹẹdogun bayii lori tabili idije Premier League.

Ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ọtọtọ ni wọn ti fidi rẹmi rẹmi bayii bayii ninu mọkanla ti wọn ti gba ni saa bọọlu tuntun yii.

Ẹgbẹ agbabọọlu Tottenham ti Jose Mourinho jẹ akọnimọọgba wọn lo si wa loke tente bayii lori tabili idije EPL.