Ọmọ Jerry Rawlings ké gbàjarè pé àwọn gbájúẹ̀ fẹ́ forúkọ bàbá rẹ̀ gbowó ìsìnkú

Ọmọbinrin to dagbaju laarin ọmọ aarẹ orile-ede Ghana to papoda laipẹ ti figbe ta pe awọn gbajuẹ́ n fi orukọ baba oun gbowo isinku loju opo ayelujara.

Zanetor Rawlings fi ọrọ yi sita ninu atẹjade loju opo Facebook rẹ lọjọbọ wi pe awọn opo ayederu ni wọn lo lati gba owo yi jọ.

O ni niṣe ni wọn n sọ awọn to ba ti ba oun kẹdun ti wọn si n ranṣẹ si wọn lati mu owo isinku baba rẹ wa.

Aṣoju ile aṣofin Ghana to n ṣoju ẹkun idibo Klottey Korle ni Zanetor n ṣe.

Lọjọ kejila, oṣu Kọkanla ni Jerry John Rawlings aarẹ Ghana fi aye silẹ lẹni ọdun mẹtalelaadọta.

Ijọba aarẹ Nana Akufo-Ado ti ṣaaju kede ọjọ meje idarọ lorile-ede Ghana gẹgẹ bi wọn ṣe n palẹmọ isinku ti ijọba fẹ se fun.