Eniola Badmus: Ẹ má se ọ̀fọ̀ mi, alaàyè ní mí, ń kò kú - Eniola Badmus

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajumọ osere tiata, Eniola Badmus ti kede pe kawọn eeyan ye sọkun oun nitori alaye ni oun, oun ko tii ku rara.

Eniola, to fi fidio soju opo Instagram rẹ wa sọ fawọn ololufẹ rẹ, ẹbi ara ati ọrẹ pe ko ko ko ni ara oun le .

Lalẹ ọjọ Isẹgun ni iroyin kan n ja kiri ori ayelujara pe Eniola Badmus wa lara awọn eeyan tawọn sọja yinbọn mọ ni agbegbe Lekki lati pinwọ iwọde EndSARS to n waye nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ Eniola se fidio naa sita lati fi ọkan awọn ololufẹ rẹ naa balẹ pe ibọn ko ba oun.

Eniola ni " Mo wa laye, bẹẹ ni mo wa laaye, ko ko ko ni ara ọta mi le. Mo si dupẹ lọwọ gbogbo ẹyin tẹ kan si mi .

Ara mi ya, ko si si ohun to se mi, koda n ko jade sita lonii.

N ko jade kuro nile ni ana, n ko si nile iwosan.

O fikun pe oun fi aago ipe oun silẹ nile lasiko ti oun rin lọ fun ere idaraya, nigba ti oun de ni oun ri pe awọn eeyan ọọdunrun ti pe oun.

O ni ẹnu ya oun pupọ, to si n dupẹ pe wọn ku ifẹ oun.