You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Rashidi Yekini: Ijọba Kwara ti ṣetán látí má ṣèrántí gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù tó ti dolóògbé
Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ni eto ti n lọ lọwọ lati yi orukọ papaa iṣere wọn ni Ilorin si orukọ gbajugbaja agbabọọlu Rashidi Yekini to doloogbe.
Gomina Abdurazaq fi eyi lede lasiko ti o lọ ṣe abẹwo ikini si minisita fun ere idaraya ati idagbasoke awọn ọdọ, Sunday Dare ni ofisi rẹ ni ilu Abuja.
Abdulrazaq ni ijiroro awọn da lori ọna ati mu idagbasoke ba awọn ọdọ lawujọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọwọ́ tẹ ọkùnrin kan ní pápákọ̀ òfurufú l‘Eko tó ń kó ike ATM 2,886 lọ si Dubai
- Ọ̀kẹ àìmọye ẹ̀rọ àyẹ̀wò káàdì olùdìbò jóná mọ́lé l' Ondo
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
- Gbèsè Nàìjíríà ti lé ní 18 tírílíọ́ọ́nù lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Buhari- DMO
- Wo bí iṣẹ́ abẹ wákàtí mẹ́fà, tí wọ́n fi dóòlà ẹ̀mí ìjàpá tí ọkọ̀ tẹ̀, ṣe lọ
- Kò sóhun tó ń jẹ́ ‘Captivus’ nílẹ̀ Oodua, mágùn ni mágùn ńjẹ́ - Babaláwo
- Wo àwọn obìnrin abúlé kan tó dáwó ra ọkọ̀ láti máa gbé aláboyún lọ ilé ìwòsàn
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
O ni ijọba oun yoo fi abadofin ti yoo yi orukọ papa iṣere naa pada si orukọ Yekini, ranṣẹ si Ile Igbimọ Asọfin ni ipinlẹ naa.
Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Minisita naa ni ọpọ igba ni awọn kọ lẹta si ipinlẹ Kwara, lati gbe igbesẹ ti ko ni jẹ ki orukọ gbajugbaja elerebọọlu naa parẹ lailai.
Dare rọ ijọba ipinlẹ Kwara lati tẹsiwaju ninu igbiyanju wọn, lati mu idagbasoke ba awọn ọdọ ni agbegbe wọn.
O ni igbelarugẹ ati ipese iṣẹ fun awọn ọdọ lawujọ ni yoo mu ki iwa ibajẹ dinku lorilẹede Niajiria.
Ọjọ Kẹrin, Oṣu Karun un, ọdun 2012 ni agbabọọlu Naijiria naa papoda ni ilu Ibadan ni ẹni ọdun mejidinlaadọta.
O bẹrẹ ere bọọlu pelu UNTL Kaduna ni ọdun 1981, to si tẹsiwaju lọ darapọ mọ ikọ agbabọọlu Naijiria ati Yuroopu.
Nibẹ lo ti gba bọọlu fun ọdun mẹrin pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Vitoria Setubal ni Portugal, to si tun gba ami ẹyẹ ẹni to gba bọọlu wọ inu awọn julọ ninu idije Primeira Liga ni saa ọdun 1993 si 1994.
Gẹgẹ bi agbabọọlu fun ikọ Naijiria, Yẹkini gba bọọlu wọ inu awọn ni igba mẹtadinlogoji, ti o si ṣoju Niajiria ninu idije gboogi marun pẹlu Idije agbaye meji.
- Àwọn dókítà Nàìjíríà ti fòpin sí ìyanṣẹ́lódì wọn
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
- Gbèsè Nàìjíríà ti lé ní 18 tírílíọ́ọ́nù lábẹ́ ìṣèjọba Ààrẹ Buhari- DMO
- Wo bí iṣẹ́ abẹ wákàtí mẹ́fà, tí wọ́n fi dóòlà ẹ̀mí ìjàpá tí ọkọ̀ tẹ̀, ṣe lọ
- Kò sóhun tó ń jẹ́ ‘Captivus’ nílẹ̀ Oodua, mágùn ni mágùn ńjẹ́ - Babaláwo
- Wo àwọn obìnrin abúlé kan tó dáwó ra ọkọ̀ láti máa gbé aláboyún lọ ilé ìwòsàn
Ni ibẹ ni o ti kọkọ jẹ ẹni akọkọ ti yoo gba bọọlu wọ inu awọn fun Naijiria ninu Idije Agbaye.
Ọdun 1993 ni o gba ami ẹyẹ Agbabọọlu Ilẹ Afrika to lamilaaka julọ.