Penis Captivus: Nǹkan márùn-ún tí obìnrin àti ọkùnrin tó lẹ̀pọ̀ yóò ṣe láti yọ rèé

Nigba kan, iroyin jade nipa ọkunrin ati obinrin kan ti wọn lẹpọ loju ara, ni ibi ti wọn ti n ba ara wọn lo pọ, idi si ree ti ọpọ ọrọ fi n jade pe ki lo n fa irufẹ eyii.

Bi awọn kan ṣe n pariwo Magun lawọn oloyinbo naa n sọ pe, irọ ni, kii se Magun ni isẹlẹ naa, ko si babara ninu ki nnkan ọkunrin ha soju ara obinrin.

Ọna lati mọ ohun to n fa irufẹ isẹlẹ yii, lo mu ki BBC tọ onisegun oyinbo lọ lati mọ nipa ohun to le fa a, ki oju ara ọkunrin ha si oju ara obinrin, lai le jade ati ọna abayọ.

Awọn oniṣegun oyinbo wa ka ohun marun silẹ gẹgẹ bi ọna abayọ, bi nnkan ọmọkunrin ati ọmọbinrin ba lẹpọ tabi ha sinu ara wọn, lasiko ibalopọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Dokita Ezenwankwo lo fi ilanilọyẹ yii silẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu BBC lori ohun to lee fa wahala yii.

Ohun akọkọ ti awọn ti nnkan yii ba ṣẹlẹ yoo se, ni lati maṣe ko aya soke, amọ ki wọn fi ọkan balẹ, ki wọn si ke si awọn onimọ nipa rẹ fun iranwọ, iyẹn gẹgẹ bi dokita Ezenwankwo ṣe sọ.

Ohun marun tawọn akọ ati abo to lẹpọ lee se lati yọ ara wọn jade:

  • Ẹ maṣe lo epo tabi ororo lati fi ra oju ara yin
  • Ẹ maṣe fi tipatipa yọ nnkan ọkunrin kuro loju ara obinrin nitori eyi le mu ki nnkan ọmọkunrin da si meji
  • Ẹ maṣe lo awọn ohun elo ile to mu, bii abẹ tabi ohunkohun rara, lati fi pin ara yin niya
  • Awọn mejeeji ti ọrọ naa ṣẹlẹ si gbọdọ duro jẹ ẹ loju kan
  • Ki wọn si pe fun iranwọ awọn onimọ iṣegun ni kiakia
  • Ti awọn takọtabo naa ba ni suuru fun bii ọgbọn isẹju, funra nnkan ọkunrin ni yoo rọ, ti yoo si jade funra rẹ lara idi obinrin lai se wahala.

Bí nǹkan ọkùnrin bá há sójú ara obìnrin, kìí ṣe Mágùn, ẹ má páyà

Ni ọpọ igba la ti gbọ iroyin kaakiri nipa bi nnkan awọn ọkunrin kan se ha soju ara awọn obinrin ti wọn n ba sere ifẹ.

Loju ọpọ ọmọ Yoruba, eyi kii se lasan nitori o lọwọ aye ninu ati oogun abẹnu gọngọ, to si nilo ilana ibilẹ lati tu awọn ololufẹ meji naa silẹ.

Nigba miran awọn eeyan maa n fi oju onisekuse ati alagbere wo awọn ololufẹ ti isẹlẹ naa ba sẹlẹ si, ti wọn ko si mọ pe ko si wahala kankan nibẹ.

Nigba miran, wọn yoo gbe iru awọn eeyan bẹẹ lọ sile iwosan tabi agọ ọlọpaa, ti wọn yoo si pe ero le wọn lori, eyi to tabuku ẹtọ ọmọniyan pupọ

Laipẹ yii si ni fidio kan n ja ranin-ranin lori ayelujara nipa ọkunrin kan to n sere ifẹ pẹlu iyawo ile ẹlomiran, ti nnkan ọkunrin rẹ si ha soju ara obinrin naa.

Iroyin naa ni wọn fa awọn mejeeji le ọlọpaa lọwọ nitori pe oogun abẹnu gọngọ lo mu ki awọn mejeeji lẹpọ.

  • Oral Sex: Bóo bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tóo lè kó lójú ara rẹỌ̀nà àbáyọ márùn ún rèé tí obìnrin àti ọkùnrin bá lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀
  • Wo oríṣiríṣi ìgbádun ibálòpọ̀ láwọn orílẹ̀èdè mìíràn
  • Lóòótọ́ ní àṣìṣe wáyé lórí ìṣẹlẹ ìfipábọ́mọdélòpọ̀ nígbà tí mo wà lórí àkóso - Pope Benedict XVI
  • Wo bí o ṣe lè mọ orúkọ àwọn afípabánilòpọ̀ ní Nàìjíríà
  • Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya

Ki lo n fa a, ti nnkan ọkunrin fi n ha soju ara obinrin?:

Sugbọn ninu iwadii awọn onisegun oyinbo, alaye ti wa pe, ko si ohun to buru ninu ki nnkan ọkunrin ha soju ara obinrin.

Wọn ni iti ọgẹdẹ lasan ni, ti ko to ohun ta a yọ ada si.

Gẹgẹ bi Dokita Francis Ezenwankwo se wi, lasiko to n ba BBC sọrọ, bi nnkan ọkunrin ba ha soju ara obinrin, eyi ni oloyinbo n pe ni 'Penis Captivus.'

O ni lasiko ere ifẹ, ẹjẹ lo maa n rọ sinu nnkan ọkunrin, ti yoo fi le gbagidi, ti yoo si maa tobi si to ba wọ oju ara obinrin tan.

Amọ ogiri oju ara obinrin, to kun fun isan, lee ran lati tobi si tabi kere si lasiko ibalopọ.

O si seese ki irufẹ isan to gbe oju ara obinrin ro yii dasẹ silẹ lasiko ti nnkan ọkunrin ba n sisẹ lọwọ nibẹ.

Nigba miran, o ni o seese ki isan oju ara obinrin naa ran ju bo se yẹ lọ, eyi si lee mu ki abawọle oju ara naa kere si.

Lasiko ti eyi ba waye, yoo mu ko nira fun nnkan ọkunrin lati jade kuro loju ara obinrin, paapaa ti nnkan ọmọkunrin naa ba si le gbagidi sibẹ.

Dokita Ezenwankwo ni ko si ohun to jọ Magun tabi oogun abẹnu gọngọ ninu isẹlẹ yii, abuda ara lo n sisẹ tiẹ.

Ki lo yẹ ki ololufẹ meji to ha sinu ara wọn se lati jajabọ?

Isẹlẹ yii kii saba waye lasiko ti takọ-tabo ba n sere ifẹ, amọ to ba waye, ko si ohun ijaya rara nipa rẹ.

Ilana isegun oyinbo fi ye wa pe, ti ololufẹ meji ba ha sinu ara wọn lasiko ere ifẹ, wọn ko nilo lati paya rara, ifarabalẹ nikan ni wọn nilo.

Dokita naa ni kii se aarin awọn ti kii se lọkọlaya ni isẹlẹ yii ti maa n waye nikan, amọ o tun maa n waye laarin tọkọ-taya pẹlu.

Koda o fikun pe, obinrin kan ti pe oun lori aago ri nigba ti oun ati ọkọ rẹ lẹpọ lasiko ere ifẹ ninu ile, ti oun si gba awọn mejeeji nimọran lati farabalẹ, titi ti ara wọn yoo fi walẹ.

Ti ara wọn ba ti balẹ, yoo rọrun fun nnkan ọkunrin lati jade kuro loju ara obinrin to ha si ni wọọrọwọ, laisi isoro kankan.

Kò sóhun tó ń jẹ́ 'Captivus' nílẹ̀ Oodua, mágùn ni mágùn ńjẹ́ - Babaláwo

Ni ọjọ diẹ sẹyin, fidio kan lu ayelujara pa nibi ti ọkunrin ati obinrin kan ti lẹpọ nibi ibalopọ, ti nnkan ibalopọ wọn ko si lee yọ kuro ninu ara wọn.

Awọn onimọ isegun oyinbo ni awọn iṣẹlẹ bẹẹ maa n waye, ṣugbọn kii saba n wọpọ.

Ṣaaju ni dokita Ezenwakwo Francis ṣalaye fun BBC pe, isẹlẹ naa ko lọwọ aye ninu, kii si se Magun, gẹgẹ bi ẹya Yoruba ti maa n pe e.

Amọ o ni isan oju ara obinrin lo n se ohun to wu, ifarabalẹ laarin ololufẹ mejeeji si ni ẹrọ rẹ lẹyin akoko diẹ, o ni bi wọn ba ti fun won loogun orun tabi sun, ara yoo tu wọn.

Iroyin naa mu awuyewuye lọwọ laarin awọn ọmọ Yoruba, bi awọn kan se tako Dokita to ni bi ololufẹ meji ba lẹpọ, kii se magun, lawọn miran fara mọ.

Idi ree ti BBC Yoruba fi tọ awọn onisẹse lọ lati mọ boya wọn nigbagbọ ninu ọrọ dokita yii, bi ko ba si ri bẹẹ, ki lo n fa ki ololufẹ meji lẹpọ lasiko ere ifẹ, ninu igbagbọ awọn baba wa.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba, Babalawo Idowu Olukunle, Akoda Awo ṣalaye pe, ko si ootọ ninu ọrọ ti awọn dokita iṣegun Oyinbo sọ naa.

Babalawo ni Magun ni isẹlẹ ki nnkan akọ ha soju ara abo, agbara ti Eleduwa fun iran Yoruba si ni:

Akoda Awo ṣalaye pe, ti awọn akọ ati abo to ba lẹpọ lasiko ibalopọ, bi awọn agba ko ba ṣe ẹ̀rọ̀ rẹ fun wọn lasiko, afaimọ ki ọkan tabi awọn mejeeji ma jade laye.

O ni lati igba iwaṣẹ ni Magun ti wa, ti awọn agba fi n ṣe iṣọra fun awon iyawo wọn, paapaa julọ, ti wọn ba ti n fura pe iru obinrin bẹẹ n rin awọn irin ti ko tọna.

O fi kun un pe, ẹya gbogbo lo ni agbara ti Eleduwa fun un; lara agbara ti Eleduwa si fun ilẹ Yoruba ni Magun, ma debẹ si lẹrọ rẹ.

Agba awo naa ni ohun to dara ju ni ki awọn eeyan maa duro ti nnkan won, ki wọn maa si ṣe ojukokoro si obinrin olobinrin.

Akoda awo ṣalaye siwaju sii pe, bi ọkunrin ba ni iyawo to si ṣakiyesi pe awọn ọkunrin miran ko jẹ ko sinmi, yoo wa nnkan to ba mọ lati fi ṣọ iyawo rẹ.

Baba Awo Idowu Olukunle ni orisirisi magun pọ pupọ, ko si lopin, ohun ti wọn ba fi se, si ni yoo sọ nipa eewọ rẹ, amọ diẹ lara orisi Magunto mẹnuba ree:

Njẹ o mọ pe oriṣiriṣi Magun lo wa?

Magun onilẹpọ:

Eyi ni irufẹ Magun ti yoo mu ki ọkunrin ati obinrin lẹpọ bi wọn ba ti n ṣe ere ifẹ, ti wọn ko si ni lee ya.

Irufẹ Magun yii lo saba n fara han lori ayelujara lode oni.

Magun ma mu omi:

Iru Magun yii ni yoo ma mu ki ọkunrin to ba lu maa pongbẹ fun omi, ni kete ti o ba ti ba obinrin ti wọn ba le ni magun ni aṣepọ.

N ṣe ni ọkunrin bẹẹ yoo maa pongbẹ omi, koda bi wọn gbe odindi odo fun un pe ko mu, ko ni tan oungbẹ naa.

Omi yii ni yoo si mu, titi ti yoo fi gba ọrun alakeji lọ.

Magun Olokiti:

Bi ọkunrin ba ti lu Magun yii lara obinrin, ọna bi yoo ṣe takiti ni yoo maa wa, bi o ba si ti le e takiti bayii, ọrun laalaa ni.

Magun alakukọ:

Bi eeyan ba ti lee lu iru magun yii lara obinrin, yoo maa gun un tabi ṣe e bii ko kọ bi akukọ ni.

Ni kete ti o ba si ti lee kọ fun igba mẹta, ẹlẹkọ ọrun yoo polowo fun un ni.

Magun Ẹlẹyin:

Bi ọkunrin ba lu Magun yii, yoo maa wa ẹyin kiri ni, to ba si ti rii ni yoo jade laye.

Magun Majẹla:

Ọkunrin to ba ba obinrin ti wọn ba le iru Magun yii si lara, ko gbọdọ jẹ ila, ni kete to ba ti le fi ẹnu kan ila, ọrun laala niyẹn.

Baba awo fi kun un pe ohun ti wọn ba le fi pilẹ Magun bẹẹ, ni yoo maa wu ọkunrin bẹẹ lati jẹ tabi se.

Magun Mafogọta:

Gọta ni yoo ma wu ọkunrin to ba lu Magun yii lati fo, ni kete ti o ba si ti fo o bayii, yoo jade laye ni.

Magun Majẹkengbe:

Bi ọkunrin to ba lu iru Magun yii ba ti jẹ kengbe, ọrun laala.

Magun Majẹ-ibẹpẹ:

Ọkunrin to ba ba obinrin ti wọn ba le iru Magun yii si lara laṣepọ, yoo maa pongbẹ lati jẹ ibẹpẹ ni. Ni kete to ba si n ti fi ẹnu kan an, ọrun laala o.

Akoda awo wa rọ awọn ọkunrin lati jinna si ṣina, ki wọn tọju obinrin wọn nitori ohun to ba wu ọkọ iyawo lo lee fi sọ iyawo rẹ.