Money laundering: Inú ọ̀pọ̀ páálí oúnjẹ́ Nódù ní afurasí kan kó ọ̀pọ̀ ike ATM sí

Ọkunrin kan, Ishaq Abubakar, ni ọwọ ti ba pe o ko ike ti wọn fi n gba owo lẹnu ẹrọ, ATM to din diẹ ni ẹgbẹrun mẹta rin.

Abubakar, to n rinrin ajo lọ si orilẹede Dubai, ti wọn ti fa le ajọ EFCC lọwọ, lo ko awọn ike ATM naa pamọ sinu paali ohun jijẹ Nodu.

Afrurasi ọhun lọwọ awọn osisẹ asọbode tẹ ni papakọ ofurufu Muritala Muhammed nilu Eko, lasiko to fẹ wọ ọkọ ofurufu lọ si Dubai.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lasiko ipade akọroyin ti wọn fi n fa afurasi ọhun le ajọ EFCC lọwọ, igbakeji ọga agba ajọ asọbode, Abdulmumini Bako ni afurasi naa sọ pe ilu Kano ni oun ti wa.

Bako ni ọkunrin kan wa pẹlu afurasi naa to fẹ seranwọ fun lati jẹ kawọn ẹrun naa kọja lọdọ awọn agbofinro laisi ayẹwo, amọ awọn osisẹ asọbode yari pe awọn yoo yẹ gbogbo paali naa wo finni-finni.

O salaye pe o seese ki wọn lo awọn ike ATM shun fun iwa lilu jibiti ati kiko owo tuulu rin, to si leri leka pe gbogbo ẹni to ba lọwọ ninu isẹlẹ yii ni yoo fi imu ko ata ofin.

EFCC gbé agbẹjọ́rò àti àna Atiku lọ iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn gbígbé owó tùùlù rìn

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC gbe Ọgbẹni Abdullahi Babalele tawọn kan sọ pe oun ni ọkọ ọkan lara awọn ọmọbinrin Alhaji Atiku Abubakar lọ ileẹjọ l'Ọjọru.

Ẹsun ti wọn fi kan Ọgbẹni Babalele ni pe wọn gbe owo bi ẹgbẹrun lọna ogoje owo dọla($140,000) rin ṣaaju idibo gbogbogbo ọdun 2019.

Bakan naa, ajọ EFCC ṣafihan Ọgbẹni Uyiekpen Osagie-Giwa to wọn ọpọ gbagbọ pe oun ni agbaẹjọro Atiku lori ẹsun pe o gbe owo bi miliọnu meji dọla ṣaaju idibo gbogbogbo.

Awọn mejeeji lawọn o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Atiku dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP eleyi to ti fidi rẹmi ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti jawe olubori.

Adajọ Nicholas Oweibo sun igbẹjọ siwaju si Ọjọbọ, nigba naa ni yoo dajọ lori beeli ti wọn beere fun.

Adajọ Oweibo ni ki wọn dawọn pada si atimọle ajọ EFCC.