UI: Kélé yóò gbé ọkùnrin tó bá ń rin gb;eregbére lágbègbè ibùgbé obìnrin ní fásitì Ibadan

Laipẹ yii ni iroyin kan pe awọn janduku kan ti ya wọ ibugbe awọn akẹkọ to jẹ obinrin ni fasiti Ibadan.

Nibayii, awọn alaṣẹ fasiti Ibadan ti wa kede ofin isede lọgba faisiti naa laarin agogo mejila oru si agogo marun idaji.

Ofin yii yoo si bẹrẹ loru ọjọru.

Nibi ipade igbimọ abo ileewe naa ni wọn ti gbe igbesẹ yii.

Gẹgẹ bii atẹjade kan ti giwa fasiti naa, Ọjọgbọn Idowu Ọlayinka fi sita ṣalaye wi pe awọn alejo ọkunrin to ba fẹ bẹ awọn akẹkọbinrin ni ibugbe Awolowo hall, Queen Idia hall ati Elizabeth hall ko gbọdọ wọ inu ibugbe awọn obinrin naa ms o. Ita gbangba ni wọn yoo ti maa gbalejo wọn

Bakan naa lo ni ọwọ afunrasi ni wọn yoo fi mu ọkunrin kankan ti o ba n rin gberegbere kaakiri ibugbe awọn obinrin nileewe naa kọja agogo mẹjọ abọ alẹ.