You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Victor Osimhen Salary: $96m ni wọ́n ra atamátàsé náà láti Lille
Ẹgbẹ agbabọọlu Napoli ti tọwọ bọ iwe adehun lati ra ọmọ Naijiria to n gba bọọlu fun ikọ Lille, Victor Osimhen.
Gẹgẹ bi iroyin ti ileeṣẹ L'Equipe gbe jade, iye owo ti wọn ra agbabọọlu naa lati ilẹ France lọ si iha 'Italian Serie A' le ni miliọnu mọkanlelọgọrin pọun.
Eyii to n tumọ si pe Victor ni agbabọọlu lati ilẹ Afrika ti iye owo ti wọn ra a pọ julọ.
- N kò ri ipa ẹ̀jẹ̀ lára ọmọ mi tó kú sí iléeṣẹ́ ọṣẹ, èjò lọ́wọ́ nínú - Òbí àkẹ́kọ̀ọ́ UI
- Àlàyé rèé lóríi àjọṣepọ̀ tó wà láàrin èmi àti MC Oluomo - Ronke Oshodi Oke
- Ìpalẹ̀mọ́ ọdún Ileya kò rọgbọ ní Maiduguri, ojo ado oloro n rọ leralera
- Mò máa ń fọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ìyá mi, ni ìṣe àwọn obìnrin fi wù mí - Bobrisky
Iye owo ti Napoli san lori Osimhen pọ ju iye owo ti Arsenal san fun Lille lati ra ọmọ orilẹ-ede Ivory Coast, Nicolas Pepe ni nkan bii ọdun kan sẹyin.
Lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Lille ta Pepe ni Osimhen darapọ mọ ikọ ọhun lati ikọ Charleroi, to wa lorilẹ-ede Belgium.
Lẹyin to sọ goolu mejidinlogun ṣawọn fu ikọ Lille ni saa to kọja ni oju ti wa lara rẹ pe o ṣeeṣe ko tẹkọ leti lọ si Napoli laipẹ.
Lẹyin ti idunadura naa pari ni Osimhen sọ loju opo Twitter rẹ pe inu oun dun lati darapọ mọ Napoli, koda o ni niṣe lo dabi pe ki oun ti wa lori papa.