Richard Christoper: Ẹ wo adúrú ǹkan tí Softface ma ń tò pọ̀ láti sín àwọn òṣèré, gbajúgbajà jẹ
Èmi ni mo ni pátá àti kọ́mú tí mo wọ̀ láti sín Regina Daniel jẹ - Softface Ọkùnrin asínnijẹ́.
Richard Christoper jẹ ọdọkunrin ọmọ Naijiria to n ṣe adamọdi aṣọ wiwọ lati sin awọn gbajugbaja eeyan jẹ ninu fọto.
"Ìgbà yẹn ni mo kọkọ 200 laiki laye mi loju opo facebook mi, iyẹ lo wa fun mi ni iwuri latio tẹsiwaju pẹlu eleyii".

Oríṣun àwòrán, @softface_official

Oríṣun àwòrán, @softface_official
O ni oun kan ṣaa ri i pe ẹbun leleyii lati ọdọ Ọlọrun. Nigbakuugba to ba ti ri aworan ti awọn eeyan nla nla ya, a kan mu u a yẹ ẹ wo daadaa a si wo nkan pẹpẹpẹ to le ra lọja lati to pọ mọ ara wọn.
Mo bẹrẹ, mo n ṣe e lojoojumọ,... bi ẹ ba si wo o daadaa, ẹ o ri i pe o jọ ojulowo gẹlẹ bi oni nkan gan ṣe ya fọto tirẹ".

Oríṣun àwòrán, @softface_official

Oríṣun àwòrán, @softface_official
Awọn nkan to jẹ wi pe bi ẹyin ti ẹ ya fọto ba ri lara rẹ, ẹ o le ṣe kẹẹ́ ma rẹrin lo maa n to mọra - Bii ko lẹ ewe ọgẹdẹ pọ fi ṣe aṣọ alawọ ewe, pali fi ṣe alawọ eepẹ, abọ ounjẹ fi ṣe kọmu, ata rodo fi ṣe ododo pupa ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ni ibi to ba iṣẹ yii de, o darukọ awọn eeyan jankan jankan lawujọ to ti ran an lọwọ ti wọn si n tun awọn fọto ti o ba ya pin loju opo ayelujara tiwọn gangan fun iṣẹ ọpọlọ to n ṣe lati pa ni lẹrin yii.

Oríṣun àwòrán, @softface_official