Belly Mujinga: Bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní UK ṣe parí ẹ̀ṣùn rẹ̀ mú kí àwọn adúláwọ̀ fa ìbínú yọ

Àkọlé fídíò, Belly Mujinga: Bí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní UK ṣe parí ẹ̀ṣùn rẹ̀ mú kí àwọn adúláwọ̀ fa ìbínú yọ

Belly Mujinga jẹ osisẹ kan nileesẹ ọkọ oju irin Reluwe nilẹ UK ti arun Coronavirus gbẹmi rẹ.

Kii se pe tori arun to gbẹmi rẹ lo mu ki ọrọ waye lori iku rẹ bi ko se ọna ti Belly gba ko arun Coronavirus to paa naa.

Ọkunrin alawọ funfun kan to ni arun Coronavirus lo tutọ si Mujinga lara, ti obinrin naa si ko arun yii latipasẹ isẹlẹ naa, eyi to mu ko dero ọrun.

Ileesẹ ọlọpa ilẹ UK se iwadi isẹlẹ naa ti wọn si jabọ pe, ọrọ ko ri bẹẹ eyi ti ko dun mọ awọn adulawọ ninu, ti iwọde si bẹrẹ lori rẹ.

Ọkọ oloogbe, Lusamba Katalay, lasiko to n ba BBC Yoruba salaye pe ibanujẹ ni iku aya oun naa jẹ, paapaa fun iya to bii lọmọ.

Katalay ni oun fẹ ki gbogbo agbaye maa ranti Belly Mujinga bii obinrin takuntakun ati alaanu eniyan, ti kii fi oju pa mẹkunnu rẹ.