Oil spillage: Àwọn olùgbé ìjọba ìbílẹ̀ Ilaje ní epo rọ̀bì ń ṣàkóbá fáwọn l'Ondo

Àkọlé fídíò, Epo rọ̀bì ti ṣàkóbá fáwọn olùgbé apá odò l'Ondo

Awọn olugbe ijọba ibilẹ Ilaje nipinlẹ Ondo to ke pe ijọba fun iranwọ, lẹyin ti wọn ni epo n ṣakoba fun wọn ati eto ọrọ aje wọn.

O kere tan, bi ogun awujọ ni asẹsi epo rọbi ti ṣakoba fun ni ijọba ipinlẹ naa nibi to jẹ pe iṣẹ ẹja pipa ni ọpọ eeyan n ṣe nibẹ.

Iṣẹ to n lọ lọwọ ni ibudo epo to wa ni Ororo ni a gbọ wi pe o ṣokunfa asẹsi epo naa ni ijọba ibilẹ Ilajẹ.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe ohu ti gbe igbimọ kan dide lati lọ wo agbegbe naa ki ijọba le mọ ohun to maa ṣe sii.