Coronavirus in Nigeria: Àwọn ọmọ Nàìjíríà bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ìsìnkú Abba Kyari, wọ́n ní ó tako ìlànà ìjìnàsíraẹni

Àkọlé fídíò, Ètò ìsìnkú Abba Kyari tako ìlànà ìjìnàsíraẹni lórí ààrùn covid-19- Àwọn ọmọ Nàìjíríà yarí

Iku n pa ni, ilẹ n jẹ eeyan. Iku olori awọn oṣiṣẹ aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari lo ti jẹ ki ọpọ ọmọ Naijiria maa sọrọ lori ayelujara bayii.

Bo tilẹ jẹ wi pe ọpọ n daro Kyari, ọgọrọ ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu ọpọ eeyan to pejọ sibi eto isinku rẹ niluu Abuja lọjọ Abamẹta.

Ohun ti wọn n sọ nipe bi ero ti peju sibi isinku Abba Kyari lodi si ilana itakeke sirẹni ti ijọba la kalẹ lati le gbogun ti aarun coronavirus ni Naijiria.

Ibeere meji ni Olúyẹmí Fásípè fi tirẹ ṣe loju opo Twitter rẹ nigba to beere lọwọ ijọba pe ṣe wọn fun awọn ẹbi awọn eeyan mii ti covid-19 ti pa lanfaani lati sin oku eeyan wọn bi ti Abba Kyari?

O tun beere wi pe kilode ti ijọba ṣe n fi eto ilera awọn araalu wewu lori bi wọn ti n gbe oku Abba Kyari ni gbangba.

Ọpọ lo koro oju si ijọba pe awọn lo ni ki ole wa ja, awọn naa lo tun ni ki oloko waa mu un.

Wọn ijọba lo fi ofin konile-o-gbele sita, ijọba naa tun lo faye gba ọpọ eeyan lati lọ sibi isinku Abba Kyari.

Awọn miiran ni titapa si ofin to wa nilẹ gbaa ni bi awọn eeyan ti pejọ sibi eto isinku Abba Kyari l'Abuja nigba ti konile-o-gbele wa lode.

@burina_NG ni tiẹ sọ wi pe o yẹ ki ijọba tọrọ aforiji lọwọ gbajugbaja oṣere, Funke Akindele ti ijọba ipinlẹ Eko fi ọwọ ofin mu lẹyin to ṣe apejẹ ọjọ ibi ọkọ rẹ.