Gbèsè tí Buhari ń jẹ bójúmu, isẹ ìdàgbàsókè ló fi ń ṣe - Agbẹnusọ fún ilé aṣòfin àgbà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 14

Ṣenatọ Surajudeen Ajibola Basiru, tí gbogbo ènìyàn mọ si SRJ, tíì se agbẹnusọ fun ilé igbimọ asofin àgbà ilẹ̀ wa ti ṣàlàyé pé, kò seese kí ilé asofin fi òfin de ẹnikẹ́ni, pàápàá àwọn aṣáájú wá, láti lọ gba

itọju lókè òkun.

Agbenuso fún ilé asofin àgbà ní bakan naa ni ọmọ sórí làwọn orile-ede míràn lagbaye, àmọ́ ó wà daba pé, ó yẹ kí ilẹ wa ṣe ìpèsè eto ìlera tó mọyàn lórí ni.

Ajibola ni "Kii se àwọn aṣáájú nìkan ló ń lọ sókè òkun, àwọn onísẹ adani, oniroyin àti àwọn èèyàn tó lowo lati lọ sókè òkun lo ń lọ gba itọju sugbọn a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ tọju ilé na, ká tó lọ síta ni."

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí owoya bilionu lọ́nà ẹgbẹ̀rin àti àbọ̀ náírà tí ìjọba Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ yá, Ajibola ni irọ tó jinna sooto ni èyí.

O ni" ṣáájú ni ile asofin tí buwolu pé kí ìjọba lọ ya owó náà lókè òkun kí àrùn Covid-19 tó dé, àmọ́ nígbà tí àrùn náà dé, ní ìjọba tún padà wá síwájú ilé pé, kí ilé fontẹ lu u pé kí ìjọba lọ yà owó náà ni abẹle dípò

òkè òkun.

Lórí iyansipo rẹ bíi agbenuso fún ilé, Ajibola ni yiyan tí wọn yàn òun, tòun ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sílè asofin àgbà fún ìgbà àkọ́kọ́, lo ṣe àfihàn ìgbẹ́kẹ̀lé tí àwọn asofin náà ni nínú òun ni.

O ni òun ń ṣe iṣẹ́ tí wọn kọ́kọ́ fun òun takuntakun, ní wón tún ṣe fún òun ní isẹ akọni mìíràn, tíì ṣe agbenuso fún ilé.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí ìjọba ṣe de òkun lórí àṣẹ konile ó gbélé, ó ní igbese ìjọba náà lo fihan pe, ijọba tó ń gbọ igbe aráàlú lo wà nita, eyi tó fún wọn láǹfààní láti jáde síta lọ wà jíjẹ àti mímú.

"Àmọ́ mo wà ń rọ àwọn ènìyàn wá láti tẹle asẹ ìjọba tó nii ṣe pelu òfin ìtakété síra ẹni, fifi aṣọ bo imú, ki wọn maa fi ọ̀sẹ̀ fọ ọwọ, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn jìnnà sí ibi tí èrò bá pọ si. "

Nígbà tó ń sọ bóyá ijoba ati àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kẹ́kọ̀ọ́ lórí àrùn Coronavirus, sẹnatọ Ajibola ni a ti kẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀, pàápàá julọ nípa ṣíṣe isẹ ni ile ati ṣíṣe àtúnṣe òfin ajakalẹ àrùn tó wáyé gbẹyin lọ́dún 1926, fifi

ìwé ipejọ lè èèyàn lọwọ láti ipasẹ ifiweransẹ Email pẹ̀lú sise ìpàdé àti eto ìdájọ́ lójú òpó ayélujára bíi Skype, Zoom àti bẹẹ bẹẹ lọ.

"Bí ile asofin àgbà, a yà idà mẹwa ọ̀rọ̀ aje wá ṣílẹ̀ fún idagbasoke eto ìlera, ìdènà ajakalẹ àrùn àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, tá sì tún ń ṣe agbeyẹwo àwọn òfin wá ti ọjọ́ tí lọ lórí wọn."

Ààrẹ Buhari fẹ́ yan òkú oṣù méjì sípò àkóso iléeṣẹ́ ìjọba àpapọ̀

Aarẹ Muhammadu Buhari tun ti yan eeyan kan to ti ku si ipo bayii eleyi to ti n ṣe ọpọlọpọ eeyan ni haahin.

Aarẹ fi orukọ Oloogbe Tobias Chukwuemeka Okwuru gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ igbimọ alakoso fun ajọ ijọba apapọ kan lẹyin oṣu meji to ti jade laye.

Aarẹ Buhari fi iwe kan ṣọwọ si ileegbimọ aṣofin agbalorilẹede Naijiria ni ọjọ Iṣẹgun ninu eyi to kọ orukọ awọn eeyan mẹtadinlogoji to fẹ yan si ipo lai mọ pe Ọgbẹni Okwuru ti jade laye loṣu keji ọdun 2020.

Bi ẹ ko ba gbagbe bi ọdun mẹta sẹyin ni iroyin lu igboro pa pe Aarẹ yan ọpọ awọn eeyan to ti jalaisi sipo akoso loniran-an-ran.

Ninu ọrọ rẹ, ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ fun aarẹ, Lauretta Onocjie ṣalaye penigba ti aarẹ kọ yan Okuru, ko tii ku nigba naa koda, 'o funra rẹ mu iwe ẹri rẹ wa ni imurasilẹ fun ifọrọwanilẹnuwo ti yoo waye ni ileegbimọ aṣofin agba.'

Lockdown in Nigeria: Kí ni Ààrẹ Buhari yóò fi $30bn owoya tó gbà lọ́wọ́ àjọ IMF ṣe?

Ní ọjọ́ Isẹgun nílé asofin àpapọ̀ ilẹ̀ wa fi ontẹ lu ọgbọn biliọnu dọla ($30bn) owo tí ijọba àpapọ̀ ilẹ̀ wá fẹ gba lọdọ àjọ ayanilowo lagbaye IMF.

Láti ìgbà tí ìjọba àpapọ̀ si ti tẹ pẹpẹ owoya náà síwájú àwọn asofin àgbà, làwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí tí ń béèrè pé ṣe ilẹ̀ wá tún nílò owoya kankan lásìkò tí ọrọ aje agbaye ti dagun yìí?

Wọn ní ṣe akọtun ìbéèrè fún owoya yìí, èyí tí yóò mú kí gbèsè tí ilẹ wa jẹ́ láwùjọ agbaye fò fẹrẹ sì biliọnu mẹtadinlọgọrun dọla ($97bn), kò ní ṣe àkóbá ńlá fún igbaye-gbadun àti ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí?

Àmọ́ ṣe ẹni tó béèrè ọrọ, lo fẹ́ ìdí rẹ gbọ, nínú ìwádìí ikọ ìròyìn BBC Yoruba, ìjọba àpapọ̀ ti ṣàlàyé pe, oun fẹ́ gba owó náà lati fi mú kí ọrọ aje Nàìjíríà gbéra lásìkò ajakalẹ àrùn Covid-19 yìí, tí epo rọbi kò ta mọ ni ọjà àgbáyé, ti

ọ̀rọ̀ aje àgbáyé si dẹnu kọlẹ.

Ìjọba ni owo naa ni òun fẹ́ fi ṣe àwọn àkànṣe isẹ tó yà kalẹ ninu eto isuna ọdún 2020.

Ìjọba àpapọ̀ ni àkànṣe isẹ mọkandinlọgọrun tó wà káàkiri àwọn ẹkùn idibo tí ń bẹ lorilẹede èdè yìí, làwọn yóò fi owóya náà gbọ bukata rẹ.

Ìjọba sàlàyé pé, lọ́dún tó kọjá àkànṣe isẹ mẹ́rin péré nínú àwọn àkànṣe iṣẹ́ náà, ni ile asofin àgbà tó kogba wọlé fi àṣẹ si láti gbọ bukata rẹ lọ́dún 2016, nígbà tí àwọn àkànṣe isẹ yoku tí wọn kò buwọlu sì ṣe koko fún idagbasoke

Naijiria.

Lára àwọn àkànṣe isẹ ti ijọba si lo ṣe koko náà, tí wọn fẹ gbọ bùkátà wọn nínú owóya ọhun, lo wa ni ẹka eto ìpèsè ohun amusagbara, iwakusa, eto ọgbin, eto ìlera, ìpèsè omi tó ṣeé mú àti eto ẹ̀kọ́.

Ìjọba wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti nigbagbọ nínú ìjọba, nítorí owoya náà ní wọn yóò lo fún àwọn àkànṣe isẹ tó yẹ fún.

Coronavirus: Ààrẹ ẹgbẹ́ dókítà ní Nàìjíríà covid-19 lè tara òkú Abba Kyari ran àwọn tó péjú síbi ìsìnkú rẹ̀

Ewu n bẹ loko lọngẹ, longẹ gan an ewu! Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita lorilẹede Naijiria(NMA), Dokita Francis Faduyile sọ pe oṣeeṣe kawọn agboku atawọn to wa leti iboji lasiko isinku olori awọn oṣiṣẹ Aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari ko aarun coronavirus lati bẹ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Dokita Faduyile ni bawọn eeyan ti pejọ leti iboji ati bawọn agboku naa ṣe gbe oku Abba Kyari tako ilana ijina sira ẹni ti ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun, NDCD la kalẹ.

Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria fikun ọrọ rẹ pe ko yẹ ki ipejọpọ nibi kibi ju ogun eeyan tabi eeyan mẹẹdọgbọn lọ lasiko ti coronavirus wa lode yii.

''Aisan yii le ti ara oku ti wọn sin bọ si ara awọn eeyan to gbe posi tabi awọn eeyan to wa leti iboji,'' Dokita Faduyile lo woye bẹẹ.

O ni bi awọn eeyan ti sun mọ ara wọn nibi isinku Abba Kyari le ṣakoba fun awọn ọmọ Naijiria.

Dokita Faduyille sọ pe o yẹ ki gbogbo eeyan to wa nibi isinku naa yara wọn sọtọ ninu igbele fun ọjọ mẹrinla ki wọn si ṣe ayẹwo lati mọ boya wọn ko ni aarun naa.

Bakan naa lo bu ẹnu atẹ bi awọn oṣiṣẹ eleto ilera ṣe bọ aṣọ idaabo bo ara ẹni lọwọ aarun nibi isinku naa.

Ẹwẹ, lẹyin ọpọlọpọ ọjọ ti ile ẹjọ di da a lẹbi pe o tapa si ofin konile o gbele nipinlẹ Eko, gbaju-gbaja oṣerebinrin, Funke Akindele-Bello ti sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

Ninu fidio kan to fi sita lọjọ Aiku, Akindele dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun atilẹyin ati aduroti wọn lasiko to fi la 'ewu' kọja.

Lẹyin to dupẹ lo ba awọn eniyan sọrọ pe otitọ ni pe aarun coronavirus wa lode.

Funkẹ sọ pe "asiko ẹkọ kikọ ni ọsẹ bi i melo sẹyin jẹ fun oun, ṣugbọn ko gbọdọ da itẹsiwaju duro."

"Ẹyin ọrẹ mi, lootọ ni aarun coronavirus wa. Gbogbo wa lati si gbọdọ tẹsiwaju lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko ati ijọba apapọ nipa diuro nile, fifọwọ loorekoore ati sise iyagosiraẹni.

Ijina sira ẹni yoo ṣe iranlọwọ lati kapa aarun coronavirus. O ba awọn ti eeyan wọn toi ku sọwọ coroanvirus. O ki awọn eleto ilera.

Àṣìṣe ló ṣẹlẹ̀ níbi ètò ìsìnkú Abba Kyari- FCTA

Awa naa gba pe aṣiṣe lo waye nibi eto isinku ati lẹyin isinku olori oṣiṣẹ fun Aarẹ Buhari, Abba Kyari- FCTA

Ileesẹ ijọba apapọ to n mojuto ọrọ Abujato jẹ olu ilu Naijiria ti sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ nibi eto isinku Abba Kyari ni iboji Gudu nilu Abuja ni ana.

Wọn dupẹ lọwọ awọn ọmọ Naijiria to ya fọnran naa ati awọn to pin in titi ti ọwọ ijọba fi tẹẹ.

Wọn ni iwa bi arakunrin naa ṣe bọ aṣọ idaabobo to wọ lasiko to n gbe oku Abba Kyari sọnu silẹ naa ku diẹ kaato.

Eyi lo si ti jẹ ki ijọba Abuja gbe igbesẹ to yẹ pe:

Ijọba ni wọn rii pe awọn ohun eelo aabo ara ẹni lọwọ ajakalẹ aarun coronavirus naa wa kaakiri iboju oku naa

Ṣugbọn bayii, wọn ti lọ palẹmọ gbogbo ohun to wa nilẹ kaakiri itẹ oku ni Gudu nilu Abuja.

Bakan naa ni ijọba FCTA ti lọ fin kokoro apako ati apa kokoro aifojuri kaakiri itẹ oku to wa ni agbegbe Gudu nilu Abuja lati dẹkun itankalẹ arun coronavirus.

Ni Afikun, wọn ti n ko awọn eeyan ti ọrọ kan bi awọn oṣiṣẹ ni iboji oku naa si igbele fun ọjọ mẹrinla, lẹyin ti wọn yoo ṣe ayẹwo to yẹ fun wọn.

Ni afikun, FCTA tun fi atẹjade sita pe awọn ti da gbogbo awọn ti ọrọ kan mọ, awọn si ti fi ara balẹ wo iṣẹ ti wọn ṣe nibẹ ati ọna abayọ siṣoro to wa bayi

FCTA ṣeleri pe lẹyin isinku Abba Kyari yii, awọn lawọn yoo maa ṣeto oku ẹnikẹni ti coronavirus ba tun pa ni Abuja.

Wọn fi awọn ara Abuja lọkan balẹ pe ko nii si ewuitankalẹ ajakalẹ arun corona ni Abuja ati agbegbe rẹ.

Awuyewuye lórí nǹkan márùn ún tí ó níí ṣe pẹ̀lú Abba Kyari nígbà ayé rẹ̀ rèé

Abba Kyari: Awuyewuye lórí nǹkan márùn ún tí ó níí ṣe pẹ̀lú olórí òṣìṣẹ́ ààrẹ Buhari tó kú rèé

Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń daro ikú Abba Kyari pé ẹni re lọ, ní àwọn míràn ń ju oko ọ̀rọ̀ lu àwọn oloselu lori ikú rẹ.

Olori awọn oṣiṣẹ ni ileeṣẹ Aarẹ lorilẹede Naijiria, Abba Kyari ju awa silẹ, o dagbere faye lalẹ ọjọ Ẹti lẹyin to ba arun COVID-19 wọ iyaaja ṣugbọn ti ko lee bori.

Ọpọ lo n foju wo Abba Kyari nigba aye rẹ gẹgẹ bii ẹni to lagbara julọ ni iṣejọba aarẹ Buhari.

Ni ọdun 2015 ni aarẹ Buhari yan Abba Kyari gẹgẹ bii olori awọn oṣiṣẹ ni ọfiisi aarẹ; ipo yii lo si wa di ọdun ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin, ọdun 2020.

Nigba aye rẹ oniruuru awuyewuye lo wọ tọọ lẹyin:

Ẹsun pe Abba Kyari gba abẹtẹlẹ lọwọ ileeṣẹ ibanisọrọ MTN

Lọdun 2016 lẹyin ti ajọ to n ṣakoso ẹka ibanisọrs lorilẹede Naijiria, NCC paṣẹ ki ileeṣẹ ibanisọrọ MTN o san owo itanran fun bi o ṣe kuna lati ys gbogbo nọmba ibanisọrọ awọn eeyan ti ko ṣeto iforukọsilẹ awọn nọmba ibanisọrọ wọn gẹgẹ bi ofin ṣe laa kalẹ.

Wọn fi ẹsun kan oloogbe Abba Kyari nigba naa pe o gba owo ẹyin to to ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira lọwọ ileeṣẹ naa lati lee din iye owo itanran ti wọn ni ki ileeṣẹ naa san nigba naa.

Ko sẹni to fi idi eyi mulẹ nigba naa nitori Abba Kyari funra rẹ gan ke sawọn oṣiṣẹ agbofinro DSS lati wadii oun.

Ẹsun pe Abba Kyari ni olori awọn igbimọ apaṣẹ wa (Cabal) ni ileeṣẹ aarẹ.

Lati igba ti aarẹ Buhari ti de ori oye ni ariwo pe awọn alagbara kan wa to n paṣẹ ni ijọba rẹ ti bẹrẹ. Awọn alagbara yii ni wọn ni wọn n fi ọla jiyọ ti wọn si ti sọ aarẹ Buhari di aarẹ gbẹwudani. Ọrọ yii di ọrọ ajọsọ kaakiri orilẹede Naijiria paapaa julọ lasiko ti ara aarẹ Buhari ko fi ya to fi lọ gba itọju ni ilu Lọndọn.

Gẹgẹ bi iroyin nigba naa,ko si ẹnikẹni to lee ṣe ohunkohun nigba naa bi awọn igbimọ alagbara yii ko ba fọwọ sii.

Aawọ laarin Abba Kyari ati aya aarẹ, Aisha Buhari

Iyawo aarẹ Buhari, Aisha Buhari ni a lee sọ pe o jẹ eeyan akọkọ lara awọn to sun mọ aarẹ Buhari to kọkọ pariwo sita pe lootọ ni awọn igbimọ alagbara yii wa.

Aisha Buhari pariwo sita nigba naa pe pe awọn eeyan kan n ko aarẹ Buhari ni papa mọra ti wọn si sọ ara wọn di apaṣẹ waa ni ileeṣẹ aarẹ.

Kyari ko iyan ipo igbakeji aarẹ, Oṣinbajo kere.

Bakan naa ni iroyin lọ kaakiri nigba kan naa lorilẹede Naijiria to fẹsun kan Abba Kyari nigba naa pe o n lo anfani bi o ṣe sunmọ aarẹ Muhammadu Buhari lati maa fi jẹ gaba le igbakeji aarẹ, Yẹmi Oṣinbajo lori.

Ọpọ awọn iwe iroyin abẹle lorilẹede Naijiria nigba naa ni wọn royin bi Abba Kyari ṣe n lo agbara aarẹ Buhari lati ti awọn ohun ti Oṣinbajo ba beere fun inawo si ẹgbẹ kan

Awuyewuye pe Abba Kyari n toju bọ ọrọ to nii ṣe pẹlu abo orilẹede Naijiria.

Laipẹ yii ni awọn iwe iroyin abẹle kan gbee pe iwe ijsba kan wa ti adari eto abo lorilẹede Naijiria, Babagana Monguno ti n fi ẹsun kan Abba Kyari pe o ṣe ayọjuran lọna to lewu si ọrọ eto abo orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni Monguna ti fẹsun kan Abba Kyari pe o n paṣẹ fun awọn olori ileeṣẹ alaabo gbogbo lorilẹede Naijiria, eleyi ti aarẹ funrarẹ kii mọ si lọpọ igba.

Ẹ wo àwọn ẹ̀kọ́ tí ikú Abba Kyari kọ olóṣèlú Nàìjíríà - Aráàlú ṣàlàyé

Yoruba ni bàa kú laa dere, èèyàn kò sunwọn ni aaye àmọ́ èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ikú olórí òṣìṣẹ́ nílé isẹ Ààrẹ, Abba Kyari tó dara ilẹ̀.Lójú opo ikan sira ẹni Twitter àti Facebook, onírúurú ọ̀nà ni awọn ọmọ Nàìjíríà ń gba daro olóògbé náà, bí àwọn kan se kárí bọnu pé ẹni re lọ, ní àwọn miran lọ ikú rẹ láti sọ oko ọ̀rọ̀ sáwọn oloselu Nàìjíríà.

Bẹẹ si ni ọ̀pọ̀ àwọn akẹẹgbẹ rẹ nínú oselu, pàápàá àwọn igun alátakò lo ń ṣe ìdárò rẹ fún ipa tó ko fún ìlọsíwájú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Femi Fani-Kayode @realFFK daro pé òun ti pàdánù ọrẹ ogójì ọdún táwọn di jọ lọ sílè ẹ̀kọ́ fasiti Cambridge.

O ṣe àpèjúwe olóògbé náà bíi èèyàn rere àti ẹni apọnle bí ó tilè jẹ́ pé èrò àwọn nínú òṣèlú ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Daddy Freeze @DaddyFRZ lójú òpó tiẹ̀ ni, ẹkọ mẹta ni ikú Abba Kyari kọ àwa ọmọ Nàìjíríà àtàwọn oloselu.

Èkíní ni pé, ikú Kyari fìdí rẹ múlẹ̀ pé, lóòótọ́ ni àrùn Coronavirus wá, to sì ń pá èèyàn.Ẹ̀kọ́ kejì ni pé a nílò abẹrẹ ajẹsara ni kíákíá lórílẹ̀-èdè yìí tí ẹkọ kẹta si n ke si wa pé àwọn ilé ìwòsàn wá nílò àtúnṣe lọgan.

Awọn mii n beere ibeere nla pé bawo la ṣe fẹ mọ pe Abba Kyari ganhan lo ku lasiko yii pé Ta lo le sọ nipato pe Kyari ni wọn n sin pe o ku?

@CallMeBiola sọ ń tiẹ̀ pé, bóyá Abba Kyari lo kú àbí ẹlòmíràn, inú òun kò dùn rárá pé àrùn Covid-19 ń pá ọmọ Nàìjíríà.

Bákan náà ni àwọn miran ń kesi àwọn aláṣẹ Nàìjíríà pé, kí wọn kọ ẹ̀kọ́ ńlá nípa ohun tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ lẹ́yìn ikú Abba Kyari

Wọn ni ki wọn sì máa rò ohun tí aráyé yóò sọ nípa tiwọn náà, tí wọn ba papoda. Awọn bii: @akeula_trendy

Jù gbogbo rẹ lọ, àwọn oloselu Naijiria ni wọn ń kesi julọ lórí ikú olórí òṣìṣẹ́ fún Ààrẹ Buhari, láti fi ikú rẹ ṣe arikọgbọn.

Ọpọ ni bí onirese wọn kò bá fín igba mọ, èyí tí wọn fín silẹ, kò leè parun láéláé ati pe ariṣe larika; arika ni baba iregun, ohunkohun ti oloṣelu kọọkan ba ṣe laraye a royin lọjọ iku rẹ.

Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló sọkùnfà ikú Kyari - Lai Mohammed

Abba Kyari: Lai Mohammed sọ pé aájò kí Nàìjíríà le dára ló sọkùnfà ikú Kyari

Minisita fun eto iroyin ati aṣa ni Naijiria, Lai Mohammed ti sọ pe aajo Naijiria lo pa Abba Kyari.

Aarun Covid-19 ti ṣekúpa olórí àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé ìjọba ní Abuja tó tún jẹ amúgbálẹgbẹ fún Ààrẹ Muhammadu Buhari.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Lai sọ pe eniyan to fi ara ṣiṣẹ fun Naijiria, to si nifẹ orilẹ-ede naa ni Kyari jẹ nigba aye rẹ, tako bi ọpọlọpọ ṣe maa n bu ẹnu atẹ lu u.

Lai ṣapejuwe Kyari gẹgẹ bi ọkan pataki ninu iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari, "nitori pe ko si nkankan ti aarẹ fẹ ẹ ṣe ti ko ni i fi to o l'eti. Oun ni alamọran aarẹ."

Gẹgẹ bi Lai ṣe sọ, ọpọlọpọ eniyan ko mọ nipa oloogbe pe o fi tọkantọkan ṣiṣẹ fun ilu wa lati ri pe iṣẹ agbẹ lọ soke, ni pataki julọ, ọrọ irẹsi gbingbin, ati ajilẹ (fertilizer) wa lara awọn nkan to mu lọkunkun dun."

Lai tẹsiwaju lati sọ pe ọrọ Kyari dabi olootọ ti kii lẹni.

"Germany to lọ to ti kagbako coronavirus, ko lọ fun igbadun ara rẹ. O lọ nitori ilu ni. Ọrọ ina mọna-mọna Naijiria lo ba lọ sibẹ.

"Aarẹ ni iku rẹ maa fi pupọ nitori pe o jẹ ẹnikan ti aarẹ gbarale pupọ fun imọran."

Wọn ti gbe oku olori awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Buhari, Abba Kyari de ilu Abuja fun isinku.

Oluranlọwọ fun Buhari lori ọrọ ayelujara, Bashir Ahmad lo fi ikede naa sita.

Èyí ni àwọn nkan tó yẹ́ kí o mọ̀ nípa Abba Kyari tí coronavirus pa

Abba Kyari ti iku wọlede mu lọ lẹyin ikọlu ajakalẹ arun coronavirus to n gbẹbọ lọwọ gbogbo agbaye yii jẹ odu ti kii ṣe aimọ fun oloko.

Ẹya Kanuri lati ipinlẹ Borno ni olori oṣiṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari, ti aarun Covid-19 pa.

Ni ọdun 1980, o gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ nipa ibagbepọ ẹda, Sociology, ni fasiti Warwick. Bakan naa lo gba oye imọ ijinlẹ akọkọ ninu imọ ofin ni Fasiti ilu Cambridge.

Ọdun 1983 ni wọn gba a wọle si iṣẹ aṣofin ni Naijiria, lẹyin to lọ si ileewe imọ ofin Naijiria, Nigeria Law School.

Yatọ si eyi, Kyari tun kẹkọọ lori idagbasoke amojuto ileeṣẹ, ni ileewe eto okoowo, Harvard Business School lọdun 1992 ati 1994.

O fẹ iyawo kan, o si bi ọmọ mẹrin.

Nigba aye rẹ, Kyari ṣiṣẹ amofin pẹlu gbaju-gbaja oloṣelu, oloogbe Fani-Kayode.

O ṣiṣẹ gẹgẹ bi olootu iroyin nileeṣẹ New Africa Holdings Limited nilu Kaduna.

Laarin ọdun 1990 si 1995, Kyari jẹ oye akọwe fun igbimọ oludari African International Bank Limited.

Bakan naa lo jẹ oludari agba fun ẹka awọn alamojuto ni ile ifowopamọ United Bank for Africa, UBA, ko to di pe o di ọga patapata.

Lọdun 2002, wọn yan-an gẹgẹ bi oludari igbimọ alakoso fun ileeṣẹ aladani Unilever Nigeria, ko tun to o darapọ mọ igbimọ alakoso ileeṣẹ eporọbi Exxon Mobile Nigeria.

Kyari lo ṣaaju awọn aṣoju ẹkun ariwa Naijiria lọdun 1994 nibi apero National Constitutional Conference ki wọn to yan an gẹgẹ bii alaga igbimọ to n mojuto ọrọ eto aabo.

Abba ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn ọmọ igbimọ adari ile ifowopamọ First Bank, Merchant Bank of Commerce ati ile iṣẹ Adojutofo Standard Alliance Insurance ri.

Ọdun 2015 ni wọn yan Kyari gẹgẹ bi Olori awọn oṣiṣẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari.

Kyari jẹ eniyan pataki ninu eto iṣakoso Buhari, debi pe awọn iroyin kan sọ pe oun gan-an ni onílù tó n lu ìlù fún ìròmi Aarẹ Buhari.

Irinajo Abba Kyari lati igba to ti ni aarun Covid-19

Aarun coronavirus ti pa olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi Aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari.

Agbẹnusọ fun aarẹ Buhari, Femi Adesina lo kede iku rẹ lojo opo twitter ni oru ọjọ Abamẹta.

Gẹgẹ bi Adesina ṣe sọ, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin ni Kyari ku.

Ọjọ diẹ ṣaaju ọjọ naa ni Kyari pada si orilẹ-ede Naijiria nibi to ti lọ duna-dura okoowo kan pẹlu ileeṣẹ Siemens AG.

Ilu Abuja ni wọn ti kọkọ n tọju Kyari, ko to o di pe iroyin sọ pe wọn ti gbe e wa si ilu Eko ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kta, lati maa gba itọju fun aarun naa.

Ọpọlọpọ ọmọ Naijria lo si bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, pẹlu alaye pe ilu ti ẹni to ni Covid-19 ba n gbe naa ni ki wọn o ti ma a tọju wọn.

Iroyin sọ pe Abba Kyari ni aisan otutu aya, Pneumonia, ati awọn aisan miran ninu agọ ara rẹ, ko to di pe o ko aarun coronavirus.

Awọn onimọ nipa eto ilera si ti sọ pe awọn to ba ni iru awọn aisan bẹ ẹ lara tẹlẹ ni coronavirus yara lati pa.

Kyari ni olori ijọba to kọkọ ni Covid-19 ni Naijiria.