Coronavirus: Àrùn Coronavirus fa'lẹ̀ya láwọn ìletò aláwọ̀dúdú ní Amẹ́ríkà

Akojọpọ iroyin nipa awọn ti arun Coronavirus n ṣe lati ọdọ awọn oṣiṣẹ eto ilera ni Chicago n jẹ ko di mimọ bayii pe ọpọ awọn eeyan to jẹ ọmọ Amẹrika alawọ dudu lọwọ arun naa ti tẹ.

Awọn ọmọ ipinlẹ Chicago to jẹ alawọ dudu lo ko ida aadọrin ninu ọgọrun awọn eeyan ti ọwọ arun naa ti ba ninu bi o tilẹ jẹ pe ida ọgbọn ninu awọn eeyan to n gbe ilu naa lo jẹ alawọ dudu.

Awọn ilu miran ti awọn eeyan alawọ dudu pọ si bii Detroit, Milwaukee, New Orleans ati New York, lo ti di ibuba fun arun naa.

Ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati ọgọrin eeyan lo ti ko arun coronavirus lorilẹede Amẹrika, awọn to si ti ran lọ si ọrun din diẹ ni ẹgbẹrun mọkanla.

Lagbaye o le ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọdunrun eeyan to ti ko arun naa, ẹgbẹrun marundinlọgọrin eeyan lo si ti tipasẹ arun naa ku.

Ki ni apapọ iṣiro ọṣẹ arun coronavirus ni Chicago?

Gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ilu Chicago ṣe sọ, titi di ọjọ karun un oṣu kẹrin, ẹgbẹrun mẹrin ati ọrinlelẹgbẹta eeyan ni arun coronavirus ti mu, okoo le lẹgbẹsan ati mẹrin ni iye awọn eeyan to jẹ alawọ dudu laarin wọn.

Bi a ba gbe eyi sẹgbẹ ojilelẹgbẹrin ati meje alawọ funfun, ọrinlenirinwo o din meji ẹya Hispanic ati mẹrindinlaadọfa ẹya Aṣia to n gbe ni Chicago to ni arun naa

Eeyan mejidinlọgọrun larun coronavirus ti ran lọ si ọrun alakeji ni ilu Chicago, ida mejilelaadọrin wọn lo si jẹ alawọ dudu nibẹ.

Iyatọ gedegbe yii n fara han lawọn agbegbe gbogbo ni ipinlẹ nibi ti awọn eeyan alawọ dudu ti n ko ida mọkanlelogoji ninu iku gbogbo to lọwọ arun coronavirus ninu, ti o si jẹ pe ida mẹrinla awọn eeyan to n gbe ni ipinlẹ Illinois lo jẹ alawọ dudu.

Kọmiṣọna fun eto ilera ni ilu Chicago, Dokita Allison Arwady ṣalaye fun awọn akọroyin pe igbelewọn ẹmi awọn alawọ dudu ni ipinlẹ naa ti ja wa silẹ pẹlu ọdun mẹsan din diẹ ju tawọn to jẹ alawọ funfun lọ.

Olori ilu naa, Mayor Lori Lightfoot ni arun coronavirus "n ṣe ọṣẹ to lagbara laarin awọn alawọ dudu ilu Chicago".

O ni wọn yoo ran awọn wolewole ilu naa lọ sawọn ṣọọbu itaja lati rii pe awọn eeyan n tẹle ilana ijinasiraẹni nigba gbogbo.

Bakan naa lo ni o ṣeeṣe ki wọn gbe eto konileogbele yẹwo lawọn agbegbe ti wọn ba rii pe awọn eeyan ti n ko ori js lati mu ọti niwaju awọn ile itaja, gẹgẹ bi iwe iroyin Chicago Sun-Times ṣe gbee jade.

Bawo ni nnkan ṣe ri lorilẹede Amẹrika lapapọ?

Bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan n sọ pe arun naa ko mọ oju sibẹ akọsilẹ n fihan pe ọwọja rẹ yatọ ni ileto si ileto.

Ni Michigan ida mẹrinla lawọn to jẹ alawọdudu nibẹ, ṣugbọn awọn gan an lo ko ida mẹtalelọgbọn lara awọn ti arun coronavirus ti kan; bẹẹni ida mọkanlelogoji awọn to ti ku lo jẹ alawọ dudu gẹgẹ bi ileeṣẹ eto ilera nibẹ ti ṣe sọ.

Ida mẹtalelogun awọn to nii lo jẹ alalwọ funfun ti ida mejidinlọgbọn awọn to ku ni ipinlẹ Michigan.

Ki lo n faiyatọ to n waye ni ilu Chicago?

Mayor Lightfoot n ṣalaye pe aisan itọ ṣuga, aisan ọkan ati aisan to niiṣe pẹlu eroja eemi pọ laarinawọn ileto awọn alawọ dudu nibẹ.