You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus: Ọṣẹ́ wo ni Coronavirus ń ṣe ní àgọ́ ara?
Osu Kejila ọdun to kọja ni coronavirus sẹyọ sugbọn bayi gbogbo aye lo n farakasa ajakalẹ kokoro aifojuri rẹ ati arun to n fa iyẹn Covid-19.
Fun ọpọ eeyan apẹrẹ arun naa diẹ ni o ma n jẹyọ lara wọn sugbọn awọn ẹlọmiran a ma ba lọ.
Bawọ wa ni kokoro yi se n ba ara ja,ki lo de tawọn kan fi n tọwọ rẹ ku,bawọ ni wọn se n tọju rẹ?
Asiko to fi n gberu lara
Asiko yi ni kokoro naa fi n fẹsẹ mulẹ ninu ara.
Awọn kokoro aifojuri a ma sọsẹ nipa wiwọ awọn sẹẹli inu ara ti wọn si ma gba akoso wọn.
Coronavirus, ti orukọ taa mọ si a si ma jẹ Sars-CoV-2,le gba ijọba ara rẹ ti o ba mii si inu lẹyin ti eeyan kan ba wu sita bi ikọ tabi ti o fọwọ kan kokoro naa ti o si mu ọwọ rẹ fi kan oju.
Corona ma kọkọ se akoba fun tọna ọfun yi,ẹdo foro ti a si sọ wọn di ile isẹ to n gbe awọn kokoro aifojuri aimọye ti wọn yoo ma se akoba fun awọn sẹẹli ara mi.
Lasiko ta n wi yi,o le ma se aarẹ ti awọn eeyan mi ko si ni se afihan apẹrẹ arun yi.
Lasiko ti arun naa fi n gberu yi,iyen asiko ti eeyan fi n ko si igba ti apẹrẹ yoo fi han a ma yatọ lara eeyan kan si ẹlọmiran sugbọn o kere tan yoo yọju laarin ọjọ marun.
Asiko Aisan ranpẹ
Nkan ti ọpọ awọn eeyan yoo ri re nipa arun yi.
Covid-19 jẹ aisan ranpẹ to se pe laarin eeyan mẹjọ ninu mẹwa to ba mu,apẹrẹ ti wọn yoo ni ko ni ju ikọ ati ara gbigbona lọ.
Ara riro,ọfun didun ati ori fifọ naa le waye sugbọ́n kii se dandan.
Ara gbigbona to tẹle ati ara wiwuwo ko sẹyin pe awọn ọmọ ogun inu ara eeyan to n ba arun naa koju
Ohun to sẹlẹ ni pe wọn ti ri kokoro aifoju ri yi gẹgẹ bi ẹni gbogun ti ara ti wọ́n a si ma ransẹ si awọn eya ara pe nkankan ti n sẹlẹ.
Eleyi a ma mu ki awọn ọmọ ogun ara to ku naa gbaradi ti eyi a si ma fa ara riro ati ara gbigbona fun ẹni naa.
Ikọ ẹgbẹ ti eeyan yoo ma wu lasikoyi ko ni mu kẹlẹbẹ wa.Idi ni pe inira ti n ba awọn sẹẹli ara ti kokoro aifojuri yi ti nawọ gan.
Awọn ẹlomiran a ma tu kẹlẹbẹ.
Ohun ta fi n tọju aisan yi ni ki eeyan sinmi daada,ki o mu omi daada ko si lo ogun paracetamọl.
Ko ni nilo lati gba itọju ile iwosan akọsẹmọsẹ.
Nkan bi ọsẹ kan ni abala aisan yi ma fi n waye- ti ọpọ a si ma re kọja nitori awọn ọmọ ogun ara wọn ti ba kokoro naa ja.
Amọ awọn ẹlomiran yoo ko arun Covid-19 to lagbara ju bayi lọ.
Ohun ta le sọ nipa arun yi re lasiko yi amọ awọn iwaadi kan n fi han pe arun naa le mu apẹrẹ mi to farapẹ ofinkin bi apẹrẹ ki imu ma yọ ikun.
Ipele to lagbara
Ti arun yi ba tẹsiwaju ko ni sẹyin pe awọn ọmọ ogun ara n sisẹ kọja bo se yẹ lati koju kokoro aifojuri yi .
Awọn kẹmica ti ara n gbejade lati pe akiyesi ara wa si kokoro aifojuri yi a ma fa titobi agọ ara ju bo ti se yẹ lọ.
Ko yẹ ki o pọju,wọn tun wọn si lo yẹ ki o jẹ.Ti titobi agọ ara ba pọju, o le se akoba fagọ ara.
Dokita Nathalie MacDermott lati fasiti King's College London sọ pe ''kokoro aifoju ri yi lo n mu ki aisedeede ma waye nipa bi awọn ọmọ ogun ara se n doju ija kọ ti a si ma fa titobi agọ ara ju bi o ti se yẹ lọ. Bi o ti se n se eleyi,
ko ye wa si ''
Ti o ba seese ki a rin gba ọna ọfun wa si ibi iho kekere to wa ninu ẹdọ foro, o yẹ ki a le ri awọn aaye atẹgun kekeeke meji kan.
Nibi yi ni atẹgun taa n mi sinu,oxygen, ti ma n lọ si inu ẹjẹ ti eleyi ti a si n mi sita,Carbon monoxide si ma n gba jade.
Sugbọn ti eeyan ba ni otutu igba aya ta mọ si pneumonia,omi ni yoo bẹrẹ si ni kun inu aaye atẹgun kekeeke wọn yi ti a si ma fa isoro fẹni naa lati ma mi daada.
Awọn eeyan mi a ma nilo fẹntilatọ lati le fi mi daada.
Ipele arun yi a ma ran to ida mẹrinla ninu ida ọgọrun eeyan ti a ba fi iroyin ta ri gba lati China wo.
Abala arun naa to lewu
Awọn onimọ safojusun pe ida mẹfa ninu ọgọrun ni arun yi yoo sakoba fun ilera wọn gaan.
Lasiko ta n wi yi, ara ẹni naa ti bẹrẹ si ni kọsẹ ti iku ko si nijina si mọ.Wahala to de ba agọ ara bayi ti kọja ohun tipa le ka ti a si ma se akoba fun gbogbo ara.
O le fa ki ẹni naa ma daku ti ẹjẹ rẹ ko ba pọ to ti awọn ẹya ara rẹ naa si le kọ lati ma sisẹ.
Inira pẹlu mimi eleyi ti ko sẹyin titobi ju ẹdọ foro a ma diwọ bi ara ti se n ri atẹgun mimi sinu gba eleyi to nilo lati le fi wa lalaafia.
O le mu ki kidinrin ma le sisẹ fifọ ẹjẹ bo ti se yẹ ti o si tun le mu inira ba awọ eti ifun ẹni naa.
Gẹgẹ bi ohun ti Dokita Bharat Pankhania sọ "kokoro aifojuri yi a ma da wahala silẹ pẹlu titobiju ẹya ara ti eleyi a si mu ki awọn ẹya ara pupọ juwọ isẹ silẹ"
Ti awọn ọmọ ogun inu ẹjẹ ko ba si ribi bori kokoro aifojuri yi,ko si nkan mi ju pe yoo tan kaakiri agọ ara ti yoo si se akoba si fara ẹni naa.
Itọju ta ma n se fun ẹni to ba ti ni arun yi lasiko yi jẹ eleyi ti yoo ka gbogbo ẹya ara ni..
Koda a tun ma kan pe ki wọn se itọju nipa sise iranwọ atẹgun ọxygen fun ara ẹni naa.
Nipase itọju yi, wọn a ma lo ẹdọ foro atọwọda lati se iranwọ mimi fun ẹni naa eleyi ti yoo ma gbe atẹgun wọ ẹdọ foro rẹ ti yoo si tun ma gbe jade pada.
Sugbọn o seese ki aburu ti o de ba ara kọja afarada ti awọn ẹya ara ko si ni lagbara lati sisẹ mọ.
Awọn iku to kọkọ t'ati ọwọ arun yi wa
Awọn Dokita ti sapejuwe bi awọn alaisan kan se pada gbẹmi mi toun ti akitiyan tawọn se.
Ile iwosan Jinyintan Hospital ni Wuhan, China, ni awọn meji kan ti kọkọ ku gẹgẹ bi alaye to wa ninuiwe igbadegba nipa isegun Lancet Medical journal.
Ninu rẹ wọn ni wọn ko foju jọ alaarẹ amọ awọn mejeeji jẹ ẹni to ti n fa siga lọjọ pipẹ ti eleyi si ti mu ki ẹdọ foro wọn ma lagbara to bo ti se yẹ.
Eni akọkọ jẹ ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgọta to ni otutu igba aya to ti jingiri nigba ti wọn gbe de ile iwosan.
Inira ti ba nipa mimi toun ti pe wọn si gbe si abẹ fẹntilatọ lati ran mimi rẹ lọwọ, ẹdọ foro rẹ pada kọsẹ silẹ ni ti o si pada papoda.
Lẹyin ọjọ mejila ti wọn gbe de lo ku si ile iwosan.
Eni keji jẹ ẹni ọdun mọkandinlaadọrin.
Oun naa ni inira pẹlu mimi
Wọn lo ẹrọ to n se iranwọ mimi fun sugbọ pabo lo ja si.
O papoda nigba ti ko ribi mi mọ.
E tẹle James loju opo Twitter.