You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus: Àjọ NYSC ké ètò ìfinimọ̀ fáwọn àgùnbánirọ̀ kúrú nítorí Coronavirus
Wọn ni ki oju maa ribi, ẹsẹ loogun rẹ.
Eyi lo difa fun ajọ agunbanirọ lorilẹede Naijiria, NYSC ti wọn sọ agadangodo si iloro gbogbo ibudo ifinimọle fawọn agunbanirọ kaakiri orilẹede Naijiria; iyẹn lẹyin ti wọn ti ni ki awọn agunbanirọ naa o maa lọ sibi ti wọn yoo ti ṣe isinruulu lẹyẹ o ṣọka.
- Bí àjálù ìbúgbàmù tó gb'ẹ̀mí ọ̀pọ̀ nìlùú Eko ṣe wáyé nìyí
- Buhari fárígá, ó ní kò s'óṣìṣẹ́ ìjọba tó gbọ́dọ̀ rìnrìnàjò sílẹ̀ òkèèrè lọ́wọ́ yìí
- Nítorí coronavirus, Mikel Obi sá kúrò ní ikọ̀ Trabzonspor
- Bí Fayemi bá tasẹ̀ àgẹ̀rẹ̀, àwọn oníbáwí rẹ̀ wà l'Ekiti-Peter Fatomilọla
- Ṣé lóòtọ́ ni Ọọ̀ni ilé ifẹ̀ ti parí aáwọ̀ lọ́balọ́ba l'Ékìtì?
Ajọ naa kede pe, ohun to fa igbesẹ yii ni arun Coronavirus to ti wa di tọrọ fọnkale yii eleyii to ti mu ki ijọba apapọ paapaa o wọgile idije ere idaraya apapọ orilẹede Naijiria, National Sports festival to yẹ ko waye nipinlẹ Edo lọdun yii.
Atẹjade to fi igbesẹ naa han sita jẹyọ loju opo facebook lowurọ Ọjọru.
Atẹjade naa fi kun un pekawọn agunbanirọ o lọ bẹrẹ isinruulu wọn lawọn ibudo ti wọn pin wọn si ati pe nigba ti nnkan ba ṣẹnuure, wọn yoo pe wọn pada.