You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Okada Ban: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láwọn yóò rún ọ̀kàdà àti kẹ̀kẹ́ Maruwa t'ọ́wọ́ bá tẹ̀ jégéjégé
Oni ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ keji oṣu keji ọdun 2020 lo pe ọjọ meji ti ijọba ipinlẹ Eko fi ofin de alapupu ti ọpọ mọ si okada ati kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta(kẹkẹ Maruwa) wiwa lawọn ijọba ibilẹ kan jakejado ilu Eko.
Ọpọ awọn ọlọkada atawọn to n wa kẹkẹ Maruwa ti wọn ṣori kunkun lọwọ awọn ọlọpaa tẹ lọjọ Abamẹta ti ofin naa bẹrẹ si ni mulẹ.
Ọga agba ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu to ṣaaju awọn ọlọpaa to n ṣe itọpinpin eto naa kaakiri sọ pe awọn ti ọwọ tẹ yoo foju wina ofin.
- Báyìí ni ìgboro Eko ṣe rí lẹ́yìn tí ìjọba fòfin de Keke àti Okada
- 'Èmi tí mo gé lápá àti ẹsẹ̀ náà ló máa ń wá ọ̀rọ̀ sọ fún èèyàn kí wọ́n má baà sá fún mi'
- Ọ̀rọ̀ di bóò lọ yà á mi l'Abuja lẹ́yìn táwọn kan ní àwọn ti lùgbàdì áárùn Coronavirus
- Atiku banújẹ́ sí ìròyìn pé Amẹ́ríkà dínà mọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà
Ọgbẹni Odumosu ṣalaye pe gbogbo awọn ọkada ati kẹkẹ Maruwa tawọn gba nile iṣẹ ọlọpaa yoo run jegejege.
O ni asiko sissan owo itanran lati gba ọkada pada ti lọ nipinlẹ Eko.
Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ṣalaye pe ofin to ti wa tẹlẹ ni ijọba ṣe agbekalẹ rẹ pada lẹyin ti ijọba ti kọkọ fofin de wiwa ọkada ati kẹkẹ Maruwa lọdun mẹfa sẹyin.
Sanwo-Olu ni yatọ si wi pe iwakuwa awọn ọlọkada pọ, ijamba ọkada ati kẹkẹ Maruwa ti ran ọpọ lọ si ọrun lairotẹlẹ.
- Ọmọ ìjọ 20 kú bí wọ́n ṣe tẹ̀ wọ́n pa níbi ìsọjí ìtagbangba
- Ìdí tí Ààrẹ Trump fi dínà mọ́ Nàìjíríà àtí orílẹ̀èdè márùn ún míì láti má wọ Amẹ́ríkà
- Ọkọ̀ wa wọ'gbó lọ lẹ́yìn táwọn dánàdánà dàbọn bò wá- Toyosi Adesanya
- Àgbékalẹ̀ Amotekun dára torí agbára òògùn àwọn baba wa kò dínkù tàbí parẹ́ - Peter Fatomilola
- Brexit: Ǹkan méje ti yóò yipada àti meje ti kò ni yi pada lẹ́yìn ti ilẹ Gẹ̀ẹ́si ti kuro labẹ EUỌpọ ara ilu Eko ni wọn duro si ibudokọ nibi ti wọn ti n duro de ọkọ lẹyin ti ko si ọkada ati kẹkẹ Maruwa to n ṣiṣẹ mọ lawọn agbegbe kan.
Ọgbẹni Agbator Solomon to fi aworan kan si oju opo rẹ Twitter bu ẹnu ẹtẹ lu igbesẹ ijọba ilu Eko.
O ni o dabi ẹni pe ijọba gba iṣẹ lọwọ awọn eeyan ni lẹyin ti wọn ti kuna lati pese iṣẹ fun wọn.
Bakan naa lọmọ ṣori lagbegbe Sabo Yaba, niṣe lero pọ loju titi biba nibi ti wọn ti n duro de ọkọ fun igba pipẹ.
Ẹwẹ, awọn ọlọkada kan ti wọn wa iṣẹ aje wa silu Eko ti bẹrẹ si ni pada sibi ti wọn ti wa.
Ọkọ tirela lọpọ ninu wọn fi n ko ọkada ti wọn n gun l'Eko pada si ilu wọn lẹyin ti ijọba ile Eko mimu awọn ọlọkada atawọn onikẹkẹ Maruwa nipinlẹ naa.
Ẹru to n ba ọpọ ni bi ilu Eko Eko yoo ṣe ri lọjọ Aje tawọn eeyan yoo pada si ẹnu iṣẹ ṣugbọn lai si ọkada ati kẹkẹ Maruwa ti wọn le wọ mọ.