Sri Lanka Election: Adarí ogun Sri Lanka tẹ́lẹ̀rí ṣe tán latí gba'dé

Oríṣun àwòrán, AFP
O ti han wi pe adari ẹka ogun alaabo ni orilẹede Sri Lanka, Rajapaksa ti ṣe tan láti jawe olubori gẹgẹ bi aarẹ orilede naa.
Bi o tilẹ jẹ pe Gotabaya Rajapaksa ti ni oun loun jawe olubori ti ẹni to jẹ alatako rẹ naa ti gba bẹẹ ṣugbọn wọn ko tii gbe esi gangan jade.

Idibo yii ni yoo jẹ igba akọkọ ti yoo waye lẹyin ikọlu nla kan to waye to si mu ẹmi eeyan to le ni igba le ni aadọta lọ ninu oṣu kẹrin ọdun yii.
Oludije marundinlogoji lo du ipo aarẹ orilẹede naa eyi ti yoo jẹ aarẹ kẹta lati ọdun 2009 ti opin ti de si ogun abẹle ọlọdun gbọọrọ to n waye lorilẹede naa.
Ọgbẹni Rajapaksa jẹ odu ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin to si jẹ ọkan lara awọn erin meji to n sare ije ipo aarẹ yii pẹlu minisita kan Sajith Premadasa.
Orukọ aarẹ to wa lori alefa bayii ko si lori iwe orukọ awọn oludije tori o pinnu lati ma dije lẹyin awọn ọrọ to jade si i latari iṣẹlẹ ado oloro to bugbamu lọjọ ọdun ajinde.
Awọn alakatakiti ẹsin Islam doju kọ awọn ile ijọsin atawọn ile itura kaakiri orilẹede naa. Koda ikọlu yii ti mu ki ọrọ aje orilẹede naa wọkun to fi mọ ẹka igbafẹ.

Ki la mọ nipa esi idibo naa
Awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ni ida ọgọrin ninu ọgọrun oludibo lo jade wa dibo.
Ọgbẹni Premadasa ni ida marundinlaadọta o le diẹ (45.3%) nigba ti Ọgbẹni Rajapaksa ni ida mejidinlaadọta o le diẹ (48.2%) Rajapaksa si ni oun yoo bori.
"Mo ni anfani lati gboriyin fun ipinu awọn araalu mo si ki Ọgbẹni Gotabaya Rajapaksa ku oriire idibo yii gẹgẹ bi aarẹ ikeeje Sri Lanka". Ọgbẹni Premadasa sọ gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin AFP ṣe jabọ rẹ.
Ajọ eleto idibo orilẹede naa sọ fun BBC pe esi idibo to tọ yoo jade ni aago mẹrin ti ilu wọn (aago mẹwa abọ lagbaye) lọjọ aje.














