Naijiria ló gba ipò kẹwàá nínú orilẹ-ede tó ni ẹ̀gbin ju- Ìwádìí

Iroyin kan ti sọ pe ilu Kano ni ilu to ni ìdọ̀tí inú afẹ́fẹ́ julọ ni gbogbo ilẹ Afirika- Switzerland.

Iwadii naa ni iwọn bi ilu naa ṣe dọti si le ni ida mẹtalelaadọta ninu ọgọrun un.

Gẹgẹ bi iroyin ọhun ṣe sọ, ohun mẹta lo jẹ ki ilu Kano wa ni ipo yii.

Iwadii naa ṣafihan ohun to mu Kano ni idọti inu afẹfẹ ati ayika to pọ yii pe:

Akọkọ ni pe pupọ ninu awọn olugbe ilu naa lo n fi igi, epo kerosin ati eedu da ina.

Ikeji ni bi awọn ojuko idalẹsi ṣe pọ kaakiri ipinlẹ Kano pẹlu idọti gọbọi.

Idi kẹta ni eefin to n wa lati ara ọkọ oju popo, alupupu ati awọn ohun miran.

Iroyin naa wa fi kun un pe ilu Kampala, to wa ni Uganda lo wa ni ipo keji ninu awọn ilu to dọti ju, lẹyin naa ni ilu Port Harcourt ni guusu Naijiria tẹle.

Iwadii ti ileeṣẹ IQ Airvisual to wa lorilẹ-ede Switzerland ṣe lo fi id iroyin naa mulẹ, to si fi orilẹ-ede Naijiria si ipo kẹwaa ninu awọn orilẹ-ede to ni ìdọ̀tí inú afẹ́fẹ́ ju lagbaye.

IQ Airvisual ni iwọn idọti ti orilẹ-ede Naijiria ni le ni ida mẹrinlelogoji ninu ida ọgọrun un, ti orilẹ-ede Uganda ati Ethiopia si n tẹle e lẹyin.

Iroyin naa ni ilẹ Afirika lo ni awọn ilu to n dagba soke julọ lagbaye nitori pe awọn olugbe ibẹ n pọ sii lojoojumọ, eyi lo mu ki idọti ọhun pọ to bẹẹ.

Iroyin ọhun wa fi kun un pe orilẹ-ede Bangladesh lo ni afẹfẹ to buru ju lati mi sinu julọ, nigba ti Pakistan ati India wa ni ipo keji atyi ẹkẹta.