Akin Alabi: Àwọn èèyàn ṣì mí gbọ́ lórí ohun tí mo sọ ní Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Asofin to n soju ẹkun idibo Ẹgbẹda Ọna Ara nipinlẹ Ọyọ, Hon Akin Alabi ti salaye pe ẹda ọrọ ni oun lo loju opo Twitter oun nigba ti oun kede pe Olori osisẹ lọọfisi aarẹ, taa mọ si Chief of Staff, lagbara ju Igbakeji aarẹ lọ.

Akin Alabi sọ eyi lasiko to n fesi si awuyewuye to jẹyọ lẹyin ti Abba Kyari gba ilu London lọ, lati gbe aba kan fun Aarẹ Buhari pe ko buwọ lu, to si jẹ pe igbakeji Aarẹ wa ni ile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bi awọn ọmọ Naijiria se kẹnu po loju opo Twitter rẹ nipa ikede to gbe sita naa, Akin Alabi salaye pe ọrọ alagbara ti oun lo, eyi to pe ni "Powerful" ni oun fi se ẹda ọrọ nitori o ni ami lori eyi ti oloyinbo n pe ni quote.

O ni eyi tumọ si pe ọrọ naa ti ni itumọ miran yatọ si itumọ ti awọn eeyan mọ lọ, ati pe igbakeji aarẹ ni isẹ ti ofin gbe le lọwọ lati soju aarẹ ti aarẹ ko ba si nibikan amọ eyi ko tumọ si pe igbakeji aarẹ jẹ ọmọ ọdọ abi bọi-bọi fun aarẹ, debi pe yoo maa gbe iwe abadofin kiri.

Alabi ni "To ba di ọrọ nipa ohun to jẹ mọ ileesẹ aarẹ, olori osisẹ lọọfisi aarẹ lo ni ẹnu julọ lẹyin aarẹ, kii si se igbakeji aarẹ rara nitori olori osisẹ lọọfisi aarẹ lo n mọ bi eto gbogbo se n ls nibẹ."

O fikun pe to ba wa wu aarẹ funra rẹ, o le gbe agbara olori osisẹ rẹ fun ẹlomiran lati se, amọ to ba kan ọrọ gbigbe iwe aba kan lọ fun aarẹ lati buwọlu, olori osisẹ lsọfisi aarẹ ni ọrọ yii kan nitori oun lo jẹ bii amugbalẹgbẹ fun aarẹ.

Bakan naa lo salaye pe isẹ gbigbe iwe ofin lọ fun aarẹ kii se ohun ti igbakeji aarẹ lee se, nitori igbakeji aarẹ kii se amugbalẹgbẹ aarẹ rara, o kan lee soju fun aarẹ, amọ ohun to ba jẹ mọ ileesẹ aarẹ , ojuse olori osisẹ nibẹ ni lati see.

Asofin Akin Alabi wa rọ awọn araalu lati mase ti ọwọ oselu bọ ọrọ to wa nilẹ naa tabi maa wa itumọ to lodi si oun ti oun sọ.

Sé lóòtọ́ ni agbára Adárí Òsìsẹ̀, Abba Kyari ju ti igbákejì Ààrẹ Nàìjíríà lọ?

Awuyewuye ti sọ ni oju opo Twitter lori ọrọ ti asojusofin Ile igbimọ asofin apapọ to n soju ẹkun Egbeda/Ona ni ipinlẹ Oyo, Akin Alabi sọ lori pe agbara Adari Osisẹ Aarẹ, Abba Kyari ju ti Igbakeji Aarẹ Naijiria, Yemi Osinbajo lọ.

Akin Alabi sọ eyi lasiko to n fesi si awuyewuye to jẹyọ lẹyin ti Kyari gba ilu London lọ ti o si lọ gbe abadofin fun Aarẹ Buhari lati buwọ lu nigba ti igbakeji Aarẹ wa ni ile.

Alabi fi kun un wi pe kii se isẹ igbakeji Aarẹ lati lọ fun Aarẹ ni abadofin ni ilu London, wi pe isẹ adari osisẹ Aarẹ ni.

Amọ, awọn to bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa ni o yẹ ki Aarẹ Buhari gbe asẹ silẹ fun igbakeji rẹ, ki o to kuro ni orilẹede Naijiria lati lo se isinmi idakọnkọ.

M.K lori Twitter ni igba ti Baba Obasanjo wa lori oye, ti Yarádua wa nibẹ ati Jonathan, adari osisẹ aarẹ ko ni agbara to bẹẹ ti yoo gba isẹ igbakeji aarẹ se nigba ti aarẹ ko ba si ni ile.

Amọ awọn to faramọ nkan ti Alabi ko sọ wi pe agbara ti Abba Kyari ni kii se agbara ti ofin fun un, ṣugbọn eleyii ti ohun lo nitori o sunmọ Aarẹ Buhari pẹkipẹki.