Balogun Fire: Ibùdó ìtajà tó jóná wà ní 43 Martins street, Lagos Island

Ọwọja ina to waye nile alaja pupọ naa lagbara, to si n jo ranin-ranin.

Pẹlu obitibiti ero to wa ni ọja Balogun, o nira pupọ fun awọn panapana lati de ibi ti ijamba ina naa ti n waye.

Diẹ diẹ, ọwọja ona naa n fẹju si, to si gba gbogbo oke ile naa kan.

Lẹyin o rẹyin, ọkọ panapana raye de ibiti ijamba ina naa ti n waye laarin ero to pọ.