You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Libya Returnees: Àtìpó 161 míì dari dé padà láti Libya layajọ́ ominira Naijiria
Awọn atipo mọkanlelọgọjọ miran tun ti dari de si orile-ede Naijiria lati orile-ede Libya.
Lowurọ kutu ọjọ Iṣegun to ṣe rẹgi pẹlu ayajọ ominira Naijiria ni wọn gunlẹ si papakọ ofurufu ipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi ọgbẹni Ibrahim Farinloye to jẹ agbẹnusọ ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, NEMA lẹka iwọ oorun Guusu Naijiria ti ṣe sọ fun BBC .
O fidiẹ mulẹ pe nkan bi aago mẹfa ku iṣẹju mẹẹdọgbọn ni wọn de nidaji aarọ yii.
O ṣalaye pe ''obinrin mẹ́rìndínlọ́gọ́ta (56) ọkunrin mẹ́tàléláàdọ́rùn ún (93) ati awọn ọmọdekunrin mejila (12) lo wa lara awọn to de naa''
Ninu ọrọ oludari ajọ NEMA nipinlẹ Eko, Idris Muhammed, lo ti ni ajọṣepo laarin NEMA, ajọ awọn arinrinajo lagbaye IOM ati ajọ EU lo mu ki ipadawasile awọ́n atipo yii rọrun.
Mohammed ni awọn ọkunrin mẹta to ni ipenija ilera lawọn ti ko lọ si ile iwosan ni kete ti wọn balẹ.
Lẹnu lọọlọ yi, ijọba Naijiria ti n gbe awọn ọmọ ilẹ naa ti wọn ṣatipo lọ si ilẹ Libya pada wa sile.
Pupọ ninu wọn ni o n kabamọ lilọ si ilẹ naa nibi ti iroyin ti ni awọn kan ti n lo wọn nilo ẹru.