You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Omoyele Sowore : Àwọn orílẹ̀èdè márùn-ún tí ìjìyà ti wà fún ẹni tó bá bú ààrẹ
Omoyele Sowore ti pari gbogbo eto beeli rẹ lọjọru ṣugbọn awọn alaṣẹ kọ lati tu silẹ.
Eyi ni ohun ti agbẹjọro rẹ Femi Falana sọ fun BBC ni irọlẹ oni ninu ifọrọwanilẹnuwo lori ẹrọ alagbeka.
Lọjọ Iṣẹgun ni ile ẹjọ paṣẹ ki awọn ọtẹlẹmuyẹ tu agbatẹru iwọde Revolution Now ti wọn fi si ahamọ lori ẹsun pe o fẹ fiditẹgbajọba silẹ.
Lara ẹsẹ ti ijọba ni Sowore da ni pe o bu aarẹ orileede Naijiria ni ilodi si ofin Naijiria.
Labẹ ofin ẹni to ba bu aarẹ le lọ si ẹwọn ọdun mẹta tabi ko san owo itanran miliọnu meje Naira.
Amọ ṣa ni Naijiria nikan kọ ni ijiya ti wa fẹnikẹni to ba bu aarẹ.
Ki a to ka awọn orileede naa seti igbọ yin,ka sare sọ fun yin pe iyawo Sowore n lewaju iwọde nibi apero awọn olori orileede to n waye nilu New York.
Oya,ẹ jẹ ki a wo awọn orileede to la ijiya kalẹ fẹni kni to ba bu aarẹ
Netherlands
Losu Kẹrin ọdun 2018, ile aṣofin Netherlands fi ofin lelẹ pe bo nba bu ọba, o le lo to ọdun marun un lẹwọn.
Ofin to de ọrọ yi ti wa lati dun 1881 ti wọn si n pe ni "lese majeste."
Igba ti wn fi ofin yi rinl ni igba ti arakunrin kan lọ si ori Facebook to si ni apaniyan,afipabanilopo ati ole ni Oba Willem-Alexander.
Ẹwọn ọgbọn ọjọ lo fi jura.
Burundi
Ni Burundi o le lo to ọdun marun un lẹwọn ti o ba ṣẹ nkankan to jọ mọ pe o bẹnu atẹ lu aarẹ.
Losu Kẹta ọdun 2019 awọn akẹkọbinrin mẹta kan wọ gau lori pe wọn ya aworan yẹyẹ aarẹ Pierre Nkuruziza .
Ọpẹlọpẹ pe awọn eeyan da si ọrọ naa ni wọn fi tu wọn silẹ lahamọ.
Thailand
Thailand naa ni ofin to jọ mọ "lese majeste" to ni eeyan ko le bu mọlẹbi idile awọn alaṣẹ ilẹ naa ti wn si ti fi iya j ọpọ eeyan lati igba ti awọn ologun ti gba ijọba ldun 2014.
Laarin ewọn ọdun mẹta si mẹẹdogun lẹni to ba bu Ọba le fi gbara
Venezuela
Lọdun 2013,ile ẹjọ giga buwọlu ofin to sọ pe ẹṣẹ ni ki eeyan kọ nkan tabi sọrọ aarẹ laburu.
Eeyan le lo to ọgbọn oṣu lẹwọn to ba tasẹ agẹrẹ si ofin yi.
Rwanda
Ọdun 2018 ni Rwanda fofin lelẹ pe o le lọ ẹwọn ọdun marun un tabi meje to ba bu aarẹ nitori ipo pataki to dimu.