You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osinbajo fárígá: Mò ṣetán láti wàákò pẹ́lù àwọn tó ń bàmí lórúkọ jẹ́!
Agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan, Olukayode Ajulo ti sọ wi pe Igbakeji Aarẹ orilẹede Naijiria ko lasẹ labẹ ofin Naijiria lati yọ ofin amuniti (imunity) rẹ kuro nitori o fẹ se ẹjọ.
Ajulo lọ sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori igbesẹ Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo lati ṣe ẹjọ pẹlu ẹsun wi pe awọn kan n ba orukọ oun jẹ.
O ni Osinbajo lasẹ labẹ ofin lati pe eniyan lẹjọ, amọ ẹnikẹni ko laṣẹ labẹ ofin la ti pe e lẹjọ tabi se iwadii rẹ lasiko to ba ṣi wa ni ipo isejọba.
O fikun un wi pe ofin kan naa lo de Osinbajo lati ma lee fun awọn asewadii lanfaani ṣiṣe iwadii rẹ, ki gbogbo aye le mọ wi pe ko wu iwa ibajẹ.
Ti a ko ba gbagbe, laipẹ yii ni Timi Frank ati awọn akẹẹgbẹ rẹ fi ẹsun kan Igbakeji Aarẹ naa wi pe o lu owo ilu ni ponpo lasiko to gba ọgọọrọ biliọnu to to aadọrun kuro ni ẹka to n risi ọrọ abẹle lorilẹede Naijiria, lati fi se idibo gbogboogbo ti ọdun 2019.
Àwọn ọmọ Naijiria fèsì sí Osinbajo tó ṣetán láti wàákò pẹ̀lú Timi Frank
Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti fesi si igbesẹ Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yemi Osinbajo to ni awọn eniyan kan n ba oun lorukọ jẹ, nitori naa oun gbe wọn losi ile ejọ.
Yemi Osinbajo tutọ soke foju gba pẹlu bi o ti ṣe ni awọn eeyan kan n ba orukọ oun jẹ.
Ariwisi ọtọọtọ si ti n tẹle ọrọ igbakeji aarẹ naa nitori bi awọn kan ti ṣe n bẹnu atẹ lu awọn to ni wọn n gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri nipa oun ni awọn miran ni ki igbakeji aarẹ ṣe mẹdọ.
Ninu atẹjade to fi si oju opo rẹ lori ayelujara Twitter ati Facebook,Osinbajo ni oun ṣetan lati ofin aṣemaṣebawi ti ofin faye gba oun silẹ lori ọrọ naa.
Bakanna ni Osinbajo sọ pe oun ti paṣẹ fawọn agbẹjọro oun lati gbe igbesẹ didoju ija kọ awọn to wa nidi ọrọ naa ni ile ẹjọ.
Osinbajo ni ọrọ yi ti wa n fẹ di lemọlemọ ti awọn to n ba ohun lorukọ jẹ naa ko si fẹ jawọ ninu iwa yi.