Nkurunziza subu lori papa l'alamojuto meji ba rẹwọn he

Aarẹ Pierre Nkurunziza ni ẹgbẹ agbabọọlu ati ẹgbẹ akọrin to jẹ tirẹ

Awọn alamojuto ere bọọlu meji ni wọn ti r'ẹwọn he lorilẹede Burundi lori ẹsun pe wọn se aarẹ nisekuse lori papa lasiko ti idije n lọ lọwọ.

Idije ọun waye laarin ẹgbẹ agbabọọlu Haleluya FC to jẹ ẹgbẹ agbabọọlu Nkurunziza funra rẹ ati ẹgbẹ agbabọọlu mii to wa lati ilu kan ti wọn pe ni Kiremba.

Wọn ni ẹgbẹ agbabọọlu alatako ko gbọdọ di aarẹ lọwọ, nireti pe aarẹ gbodo gba bọọlu un sinu awọn, sugbọn nise ni a gbọ pe nise ni awọn ati po meji kan lati orilẹede Kongo ti awọn ko mọ bi nnkan se n lọ fi ẹyin aarẹ bẹlẹ.

Lẹyin o rẹyin ni wọn sọ pe, alakoso ẹgbẹ agbabọọlu Kiremba Cyriaque Nkezabahiz ati igbakeji rẹ Michel Mutama ni wọn gbe awọn atipo ọun wa, niwọn ba fi ẹsun igbimọ pọ lọna aitọ kan awọn mejeeji ọun.

Nkurunziza, ẹni ọdun mẹrinlelaadọta la gbọ pe o maa n kopa ninu idije ere bọọlu lẹẹmẹta lọsẹ.