Free Sowore: Ilé ẹjọ́ ti gba béèlì Omoyele Sowore

Ajọ eleto aabo, DSS ti sọ wi pe awọn n duro de iwe irinna ilẹ okeere Omoyele Sowore, ki wọn to le fi silẹ.

Agbẹjọro Sowore, Femi Falana lo sọ wi pe wọn ti n fi baalu gbe iwe irinna ile okeere naa bọ lati ilu Eko si Abuja.

Falana wa fikun wi pe wẹrẹ ti wọn ba ti gba iwe irinna okeere to jẹ bi oniduro fun un de ni Ajọ DSS yoo tusilẹ kuro ni ahamọ wọn ti o wa.

Ilé ẹjọ́ tú Sowore sílẹ̀, wọ́n gba onídùúró rẹ̀!

Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe ile ẹjọ giga l'Abuja ti gba oniduro Omoyele Sowore ti Adajọ si ti ni ki o fi iwe irina rẹ kalẹ.

Idajọ yi waye nibi igbẹjọ to ni i ṣe pẹlu ọrọ naa lọjọ Iṣẹgun Òní lòní ń jẹ́ fún Omoyele Sowore láti fojú bá Ilé ẹjọ́ gíga

Ajọ otẹlẹmuyẹ Naijiria ti saaju beere iyọnda ile ẹjọ lati fi Sowore si ahamọ aadọrun ọjọ ṣugbọn ile ẹjọ ni ki wọn tu Sowore silẹ fagbejọro rẹ Àkójọpọ̀ àwòrán láti ibi igbẹ́jọ́ Omoyele Sowore l'Abuja.

Femi Falana to jẹ agbẹjọro rẹ ni awọn yoo bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu lati seto itusilẹ Sowore.

Losu kẹjọ, ọdun 2019 ni ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ fi Sowore si ahamọ fun pe o fẹ fi iditẹgbaijọba Naijiria.

Wọn ni ki Sowore fi paali iwe irinna rẹ silẹ.

Falana fi idi ẹ mulẹ pe o di dandan ki wọn fi Sowore sile ni kete ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti yọ igbẹjọ wọn kuro.

Adajọ Taiwo Taiwo to gbọ igbẹjọ naa lẹyin isinmi ranpẹ ṣaaju idajọ rẹ ni ki wọn fi Sowole Omoyele sile, ṣugbọn ko ma rinrin ajo kankan titi igbẹjọ naa yoo fi pari.

Agbẹjọrọ Femi Falana ṣalaye pe gbogbo wọn ti n gbe igbesẹ to yẹ bayii ki Omoyele sowore le pada lọ sile lọ ba ẹbi ati ara rẹ lonii laidi ọla.