Oyo Tribunal: Olùdámọ̀ràn ìṣèlú fún Makinde ní Adelabu kò ní ẹ̀rí tó dájú láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ to n gbọ́ awuyewuye ibo gomina nipinlẹ Ọyọ ti kede pe gomina Seyi Makinde ló borí ìbò gómìnà to waye losu kẹta ọdun 2019.

Igbimọ̀ naa kede eyi lasiko to n gbe idajọ̀ kalẹ nile ẹjọ giga to wa ni Iyaganku Ibadan, lori ibo lati mọ ẹni to jawe olubori ninu ibo gomina naa.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Suraju Muhammed to ko igbimọ olugbẹjọ to n gbọ ẹhonu ibo naa sodi salaye pe, gbogbo awọn ẹsun ti ẹgbẹ oselu APC ati oludije rẹ gbe wa siwaju igbimọ naa, lo jẹ otubantẹ.

Adajọ Muhammed salaye pe, ẹsun ti Adebayọ Adelabu fi kan ajọ eleto idibo pe, iye ibo ti wọn di pọ ju awọn oludibo to tẹ ika lọ ni ko fidi mulẹ, bẹẹ ni ko si ni ẹri to daju pe iye awọn oludibo ju iye awọn ti ajọ Inec fi orukọ wọn silẹ lọ.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ẹwẹ, nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lẹyin ikede igbimọ olugbẹjọ ẹhonu ibo naa, asaaju agbẹjọro fun Adelabu ni awọn yoo lọ se asaro lori idajọ igbimọ naa lati mọ boya awọn yoo tun pe ẹjọ kotẹmilọrun abi bẹẹ kọ.

Sugbọn lero ti oludamọran agba feto iselu fun gomina Seyi Makinde, eyiun Asofin Babatunde Oduyọye salaye pe, ko si ọrọ fifi tọrọ di kọbọ loju lori agbekalẹ idajọ naa, nitori pe igun olupẹjọ ko ni ẹri to daju lati fi ti awọn ẹsun rẹ lẹyin.

Bẹẹ ba gbagbe, oludije fun ẹgbẹ oselu APC , Adebayọ Adelabu lo morile iwaju igbimọ olugbẹjọ to n gbọ awuyewuye ibo gomina, lati tako esi ibo to gbe alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu PDP, Seyi Makinde wọle bii gomina.

Awọn ero to wa nile ẹjọ

Ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọyọ, lo ti kede saaju lẹyin ibo gomina naa to waye lojọ Kẹsan osu Kẹta ọdun yii pe, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde lo moke ninu ibo naa.

Inec ni ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (515,621) ni Seyi Makinde to gbegba oroke ko, nigbati Adebayọ Adelabu si se ipo keji pẹlu ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun lọna ọdunrun ati aabọ (357,982).

Awọn ero to wa nile ẹjọ

Bakan naa ni ajọ Inec ni Makinde yege ibo ni ijọba ibilẹ mejidinlọgbọn ninu mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ naa, ti Adelabu si moke ni ijọba ibilẹ mọkanla pere.

Ni bayii na, se ni awọn ololufẹ gomina Seyi Makinde ati ẹgbẹ oselu PDP n fo fẹrẹ fayọ nile ẹjọ ati laarin igboro ni kete ti wọn gbọ ibi ti igi ẹjọ naa wo si.